Làìhónà
Ayọ̀ Pípẹ́ Ìgbé-ayé Ìhìnrere
Oṣù Kejì 2024


“Ayọ̀ Pípẹ́ Ìgbé-ayé Ìhìnrere,” Làìhónà, Oṣù Kejì 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kejì 2024

Ayọ̀ Pípẹ́ Ìgbé-ayé Ìhìnrere

Ayọ̀ pípẹ́ nwá nípa níní ìfaradà nínú ìhìnrere Jésù Krístì àti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ .

Ádámù àti Éfà pẹ̀lú Ọgbà Édẹ́nì ní ẹ̀hìn

Ọgbà Édẹ́nì, láti ọwọ́ Grant Romney Clawson; Fífi Ọgbà Édénì Sílẹ̀, láti ọwọ́ Joseph Brickey

Ọ̀rọ̀ ṣókí ti èrèdí ìgbésí ayé wa ni a lè rí nínú àwọn ẹ̀kọ́ ti-wòlíì Léhì nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀dá lórí ilẹ̀-ayé. Nínú Ọgbà Édénì, Ádámù àti Éfà gbé nínú ipò àìmọ̀kan. Tí wọ́n ìbá ti dúró ninú ipò náà, wọn kì bá ti “[ni] ayọ̀ rárá, nítorí wọn kò mọ òṣì; tí wọn kò ṣe rere, nítorí wọn kò mọ ẹ̀ṣẹ́” (2 Néfì 2:23). Bayi, bí Léhì ti ṣàlàyé , “Ádámù ṣubù kí àwọn ènìyàn lè wà; àwọn ènìyàn sì wà, kí wọ́n ó lè ní ayọ̀” (2 Néfì 2:25; bákannáà wo Mósè 5:10–11).

Bí a ti ndàgbà nínú ayé ìṣubú, à nkọ́ ìyàtọ̀ ní àárín rere àti ibi nípa ohun tí a kọ́ àti nípa ohun tí a ní ìrírí. Àwa “tọ́ ìkorò wò, kí [a] lè mọ̀ láti díyelé rere” (Mósè 6:55). Ayọ̀ nwá bí a ti nkọ ìkorò sílẹ̀ tí a sì nṣìkẹ́ púpọ̀si àtí di ohun rere mú ṣinṣin.

Wíwá Ayọ̀

Nítorí ìfẹ́ pípé Rẹ̀, Baba wa Ọ̀run ntara láti pín ayọ̀ pípé Rẹ̀ pẹ̀lú wa, ní ìsisìyí àti ní àìlópin pẹ̀lú. Èyí ti jẹ́ ìwúrí Rẹ̀ nínú ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú ètò ológo ti ìdùnnú Rẹ̀ àti ìrúbọ Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo láti rà wá padà.

Ọlọ́run kìí gbìyànjú láti fi ayọ̀ tàbí ìdùnnú lé wa lórí dandan, ṣùgbọ́n Ó nkọ́ wa bí á ó ti wa. Bákannáà Ó wí fún wa ibi tí a kò ti lè rí ayọ̀—“ìwà búburú [kìí ṣe kò sì] jẹ́ ìdùnnú rí” (Álmà 41:10). Nípa àwọn òfin Rẹ̀ ni Baba Ọ̀run ti nfi ipa ọ̀nà sí ayọ̀ hàn wá.

Ààrẹ Russell M. Nelson fihàn ní ọ̀nà yí:

“Nihin ni òtítọ́ Ọlọ́lá: nígbàtí ayé bá tẹnumọ pé agbára, ìní, òkìkí, àti ìgbádùn ti ara nmú ìdùnnú wá, wọn kò ní! Wọn kò lè ni! Ohun tí wọ́n nmú jáde kìí ṣe ohunkankan ṣùgbọ́n ìrọ́pò kòròfo fún “ipò ìbùkún àti ìdùnnú àwọn [tí wọ́n] npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́’ [Mòsíàh 2:41].

“Òtítọ́ ni pé ó jẹ́ ikaarẹ̀ púpọ̀ síi láti wá ìdùnnú níbití ẹ kò ti lè rí i láé! Bákannáà, nígbàtí ẹ bá ru ẹrù ara yín fún Jésù Krístì àti tí ẹ sì ṣe iṣẹ́ ti ẹ̀mí tí ẹ nílò láti ṣẹ́gun ayé, Òun, àti Òun nìkan, ni ó ní agbára láti gbé yín sókè ju ayé yí lọ.”1

Bayi, ayọ̀ pípẹ́ ni à nrí nínú pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, àwọn òfin Ọlọ́run ni a sì nrí nínú ìhìnrere Jésù Krístì. Ṣùgbọ́n àṣàyàn wa ni. Bí a bá kùnà nínú àìlera wa fún ìgbà kan láti pa àwọn òfin mọ́, a ṣì lè yí padà, kọ ìkorò, kí a sì lépa rere lẹ́ẹ̀kansi. Ìfẹ́ Ọlọ́run kìí ṣe gáfárà fún ẹ̀ṣẹ̀—èyí yíò jẹ́ àánú tí ó nja ìdáláre lólè—ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, Jésù Krístì fúnni ní ìràpadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀:

“Amuleki … wípé … Olúwa nbọ̀ dájúdájú láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, ṣùgbọ́n kò lè wá láti rà wọ́n padà nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n láti rà wọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

“À sì ti fi agbára fún un láti ọ̀dọ̀ Baba láti rà wọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìrònúpìwàdà; nítorínã ni ó ṣe rán àwọn ángẹ́lì rẹ̀ láti kéde ìròhìn ayọ̀ nípa ti àwọn ipò ìrònúpìwàdà, èyítí ó mú ènìyàn wá sínú agbára Olùràpadà nã, sí ti ìgbàlà ọkàn wọn” (Hẹ́lámánì 5:10–11;

Jésù wí pé:

“Tí ẹ bá pa òfin mi mọ̀, ẹ ó gbé nínú ìfẹ́ mi; àní bí mo ti ṣe pà òfin Bàbá mi mọ́, tí mò ngbé nínú ìfẹ́ rẹ̀.

“Àwọn ohun wọ̀nyí ni mo wí fún yín, kí ayọ̀ mi lè dúró nínú yín, àti kí ayọ̀ yín lè kún” (Johanu 15:10–11).

Èyí ni ohun tí Léhì ní ìmọ̀lára nínú àlá rẹ̀ bí ó ti tọ́ èso igi ìyè wò—èyí tí ó ṣojú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó wípé, “Bí mo sì ti jẹ́ nínú èso rẹ̀ ó fi ayọ̀ nlá tí ó rékọjá kún ọkàn mi” (1 Néfì 8:12; bákannáà wo 11:21–23).

Léhì bákannáà fi ọ̀nà kejì hàn tí a fi lè mú ayọ̀ wá sínú ayé wa nígbàtí ó wípé, “Nítorínáà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ìfẹ́ wípé kí ìdílé mi kí ó jẹ́ nínú [èso náà] pẹ̀lú” (1 Néfì 8:12).

ọwọ́ kan tí ó nna èsò sí ọwọ́ míràn, pẹ̀lú igi lẹ́hìn

Igi Ìyè, láti ọwọ́ Kazuto Uota

Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Rí Ayọ̀

Bíiti àwọn ènìyàn Ọba Benjamin, a “nkún fún ayọ̀” nígbàtí a bá gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a sì ní ìrírí “ìbàlẹ̀ ọkàn” (Mosiah 4:3). À nní ìmọ̀lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi nígbàtí a bá wo ìta tí a sì wá láti ran ọmọ ẹbí àti àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gba irú ayọ̀ àti àláfíà kannáà.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́mọkùnrin Álmà, Álmà wá ìdùnnú nínú ohun gbogbo tí ó tako ìhìnrere Jésù Krístì. Lẹ́hìn tí ángẹ́lì ti ba wí, wá láti ọ̀nà jíjìn kúrò nínú “ìkorò” sí “rere” nípa ìrònúpìwàdà “dé ẹnu ikú” (Mosiah 27:28) àti ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà. Àwọn ọdún lẹhìnnáà, Álmà fi ayọ̀-nlá kéde sí ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì pé:

“Àti, a!, irú ayọ̀ wo, àti pé irú ìmọ́lẹ̀ wo ni èmi rí; bẹ̃ni, ọkan mi kún fún ayọ̀ èyítí ó pọ̀ púpọ̀ bí ìrora èyítí mo ní ṣãjú! …

“Bẹ̃ni, láti ìgbà nã lọ àti títí di ìsisìyí pẹ̀lú, èmi ti ṣiṣẹ́ láìsinmi, kí èmi kí ó lè mú àwọn ọkàn wá sí ìronúpìwàdà; kí èmi kí ó lè mú wọn tọ́ wò nínú ọ̀pọ̀ ayọ̀ nínú èyítí èmi ti tọ́ wò. …

“Bẹ̃ni, àti nísisìyí kíyèsĩ, A! ọmọ mi, Olúwa ti fún mi ní ọ̀pọ̀ ayọ̀ nlá nínú èrè iṣẹ́ mi;

“Nítorítí ọ̀rọ̀ [ìhìnrere Jésù Krístì] èyí tí òun ti fi fún mi, kíyèsi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ti bí nípa Ọlọ́run, tí wọ́n sì ti tọ́ wò gẹ́gẹ́bí èmi ti tọ́ wò” (Àlmà 36:20, 24–26).

Ní ọ̀nà míràn, Álmà jẹri pé:

“Èyí sì ni ògo mi, pé bóyá èmi lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti mú ọkàn àwọn ẹ̀mí díẹ̀ wá sí ìrònúpìwàdà; èyí sì ni ayọ̀ mi.

“Sì kíyèsĩ, nígbàtí mo bá rí púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin mi pé nwọ́n ti ronúpìwàdà nítoótọ́, tí nwọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, ìgbàyĩ ni ọkàn mi kún fún ayọ̀” (Álmà 29:9–10).

Álmà lọ láti kéde ayọ̀ alágbára tí ó ní ìmọ̀lára nígbàtí àwọn ẹlòmíràn ní àṣeyọrí ní mímú àwọn ọkàn wá sọ́dọ̀ Krístì:

“Ṣùgbọ́n èmi kò yọ̀ nínú àṣeyọrí mi nìkan, ṣùgbọ́n ayọ̀ mi kún síi nítorí àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi [àwọn ọmọ Mosiah], tí nwọ́n ti lọ sí ilẹ̀ Néfì.

“Kíyèsĩ, nwọ́n ti ṣiṣẹ́ púpọ̀, nwọ́n sì ti mú èso púpọ̀ jáde wá; báwo sì ni èrè wọn yíò ti pọ̀ tó!

Nísisìyí, nígbàtí mo bá ro ti àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, a mu ọkan mi fo lọ, ani bi i pe a pin niya kuro ní ara mi, bi o ti ri, bẹ́ẹ̀ si ni ayọ mí tobi to” (Álmà 29:14–16).

A lè rí irú ayọ̀ kannáà bí a ti nfẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú “ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Krístì” (Moroni 7:47; bákannáà wo ẹsẹ 48), ẹ pín òtítọ́ ìmúpadàbọ̀sípò pẹ̀lú wọn, kí ẹ sì wọ́n láti kó wọn jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn májẹ̀mú.

Olùgbàlà ní Gẹ́tsémánì

Ah Bàbá Mi, láti ọwọ́ Simon Dewey

Ayọ̀ Ní Àárín Ìpọ́njú

A kò níláti bẹ̀rù pé àwọn àdánwò àti ìpènijà tí à nkojú láìlèyẹ̀ nínú ayé ikú yíò dẹ́kun tàbí pa ayọ̀ wa run. Álmà ni ọ̀kan lára àwọn tí iṣẹ́-ìsìn àìmọtaraẹni fún àwọn ẹlòmíràn paá lára gidigidi. Ó jìyà ìtìmọ́lé, ebi àti ohungbẹ fún ìgbà pípẹ́, lílù, ewu sí ẹ̀mí rẹ̀, àti ẹ̀sín àti ìkọ̀sílẹ̀ léraléra. Àti pé síbẹ̀, gbogbo rẹ ni “a gbé mi nínú ayọ̀ Krístì” (Álmà 31:38). Àní bóyá Ìjìyà Álmà tilẹ̀ mú kí ayọ̀ tí ó tẹ̀le tóbí jùlọ.

Àarẹ Nelson rán wa létí pé ayọ̀ ṣe ojúṣe kan nínú ìjìyà Olùgbàlà—“nítorí ayọ̀ ti a gbé kalẹ̀ níwájú [Rẹ̀] Ó farada Agbélèbú” (Hébérù 12:2).

“Ronú nípa èyíinì! Ní èrò fún Un láti farada ìrírí olóró jùlọ tí a faradà rí nílẹ̀ ayé, Olùgbàlà wa dojúkọ ayọ̀!

“Kíni ayọ̀ tí a ti gbé kalẹ̀ níwájú Rẹ̀? Dájúdájú ó pẹ̀lú ayọ̀ ìwẹ̀nùmọ́, ìwòsàn, àti fífúnwalokun; ayọ̀ sísan gbèsè fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn tí yíò ronúpìwàdà; ayọ̀ mímu ṣeéṣe fún yín àti èmi láti padà sílé—ní mímọ́ àti yíyẹ—láti gbé pẹ̀lú àwọn Òbí Ọ̀run àti ẹbí wa.

“Bí a bá dojúkọ ayọ̀ tí yíò wá sọ́dọ̀ wa, tàbí sí ọ̀dọ̀ àwọn tí a fẹ́ràn, kíni a lè faradà tí ó dàbí ohun tí ó lágbára, ronilára, bànilẹ́rù, tí kò dára, tàbí tí kò ṣeéṣe lọ́wọ́lọ́wọ́?”2

Ayọ̀ pípẹ́ nwá nípa níní ìfaradà nínú ìhìnrere Jésù Krístì àti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákannáà. Ayọ̀ pípẹ́ nwá bí a ti ngbé nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, gbọ́ran sí àwọn òfin rẹ̀ tí a sì ngba ore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà. Ní ipa ọ̀nà ìhìnrere, ayọ̀ wà nínú irìn-àjò bákannáà bí ayọ̀ ní ìgbẹ̀hìn. Ìhìnrere ti Jésu Krístì ni ipa ọ̀nà ayọ̀ ojojúmọ́.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Rí Ìsinmi,” LàìhónàOṣù kọkànlá 2022, 97.

  2. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Ìtúsílẹ̀ Ẹ̀mí,” Liahona, Oṣù Kọkànlá 2016, 83.