Làìhónà
Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ọ̀rọ̀ Olùgbàlà síi Yín
Oṣù Kẹta 2024


“Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ọ̀rọ̀ Olùgbàlà síi Yín,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2024

Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ọ̀rọ̀ Olùgbàlà síi Yín

Atọ́nà yí nràn yín lọ́wọ́ láti so àwọn àṣàyàn yín pọ mọ́ Jésù Krístì àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

Jésù Krístì

Mo Dúró ní Ẹnu-Ọ̀nà mo sì Nkan Lẹ̀kùn, láti ọwọ́ J. Kirk Richards

Ròó pé ò ngbé ní Gálílì àtijọ́, ní ẹgbẹ́rún ọdún méjì sẹ́hìn. Ẹ̀yin àti àwọn ọ̀rẹ́ yín ni a ti pè sí ìfọkansìn àwọn ọ̀dọ́ ní sínágọ́gù ìbílẹ̀, tí ó nfi olùsọ̀rọ̀ àlejò pàtàkì kan hàn: Jésù ti Násárẹ́tì. Àti pé ní àkókò kan pàtó nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Jésù pe àwọn ọ̀dọ́ inú ọ̀pọ̀ èrò láti bi Òun ní àwọn ìbèèrè.

Irú àwọn ìbèèrè wo ni ẹ rò pé ẹ lè gbọ́?

Mo lérò pé àwọn ìbèèrè kan yíò fi àṣà àti ipo àkokò náà hàn. Ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ lotitọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn yíò dún bí ọ̀pọ̀ àwọn ìbèèrè tí a ní loni.

Fún àpẹrẹ, nínú Májẹ̀mú Titun, àwọn ènìyàn bi Olùgbàlà ní àwọn ìbèèrè bí ìwọ̀nyí.

  • Kíni mo nílò láti ṣe láti jèrè ìyè ayérayé?1

  • Ṣe mo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣe mo jẹ́ ara kan pẹ̀lú yín?2

  • Bí arákùnrin mi bá ṣẹ̀ ní ìlòdì sí mi, ìgbà melo ni mo níláti dáríjì í?3

  • Kíni yíò ṣẹlẹ̀ sí ayé yí ní ọjọ́ iwájú? Njẹ́ èmi ó wà láìléwu?4

  • Ṣé Ẹ lè wo olólùfẹ́ mi sàn?5

  • Kíni òtítọ́?6

  • Báwo ni èmi ó ṣe mọ̀ bí mo bá nlọ ní ọ̀nà tí ó tọ́?7

Ṣé gbogbo wa kìí ní ìyàlẹ́nu ohun kannáà láti ìgbà sí ìgbà? Ní àwọn sẹ́ntíúrì, àwọn ìbèèrè náà kò tíì yípadà púpọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àánú Olùgbàlà sí àwọn tí wọ́n nbèèrè wọn. Ó mọ bí ayé ṣe lè jẹ́ dídàmú àti dídàrú sí. Ó mọ̀ bí ó ti rọrùn tó láti sọ ọ̀nà wa nù. Ó mọ̀ pé a ndàmú nígbàmíràn nípa ọjọ́ ọ̀la. Ó sì wí fún ẹ̀yin àti èmi, gẹ́gẹ́ bí Òun ti sọ fún àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn pe:

  • “Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú.”8

  • “Èmi ni ọ̀nà [àti] òtítọ́.”9

  • “Ẹ Tẹ̀lé mi.”10

Nígbatí ẹ bá ní awọn yíyàn pataki lati ṣe, Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò ni yíyàn tí ó dárajulọ. Nígbatí ẹ bá ní awọn ibéere, Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò ni awọn idáhun tí ó dárajulọ.

Èyí ni ìdí tí mo fi féràn Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Yíyàn. Ó ntọ́ wa sí Jésù Krístì kí a lè gba okun Rẹ̀. Mo nmú ẹ̀dà kan pamọ́ sí àpò mi nígbà gbogbo. Bí mo ṣe npàdé àwọn ènìyàn káàkiri ayé tí wọ́n fẹ́ láti mọ ìdí tí àwà, bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì, fi nṣe ohun tí à nṣe, èmi npín atọ́nà yí pẹ̀lú wọn.

Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ nkọ́ni ní àwọn òtítọ́ ayérayé Nípa Olùgbàlà àti Ọ̀nà Rẹ̀. Ó npè yín láti ṣe àwọn yíyàn tí ó dálé orí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí. Ó sì npín àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí tí Ó nà sí àwọn wọnnì tí wọ́n ntẹ̀le E. Ẹ jọ̀wọ̀ ẹ kà, ẹ jíròrò, kí ẹ sì pín atọ́nà yí!

Ẹ Pè É Wọlé

Jésù Krístì nfẹ́ láti jẹ́ ara ìgbé ayé yín—wíwà lójojúmọ̀, léraléra, ní àwọn ìgbà rere àti búburú. Òun kò kàn dúró lásán ní òpin ipa-ọ̀nà, ní dídúró fún yín láti dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Òun ó rìn pẹ̀lú yín ní gbogbo ìgbésẹ̀ ojú ọ̀nà náà. Òun ni Ọ̀nà náà!

Ṣùgbọ́n Òun kò ní fi ipá fi ọ̀nà Rẹ̀ sínú ayé yín. Ẹ̀ npè É wọlé, nípasẹ̀ àwọn yíyàn yín. Èyí ni ìdí tí àtọ́nà fún ṣíṣe àwọn yíyàn, bíi ti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, fi ṣe iyebíye tóbẹ́ẹ̀. Gbogbo ìgbà tí ẹ bá ṣe yíyàn òdodo tí ó dá lé àwọn òtítọ́ ayérayé Olùgbàlà, ẹ nfihàn pé ẹ nfẹ́ Ẹ nínú ayé yín. Àwọn yíyàn wọ̀nyí nṣí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run, okun Rẹ̀ sì nwá ní dídà sínú ayé yín.11

Ṣe Ìsopọ̀ Alágbára kan

Ẹ lè rántí pé Olùgbàlà ṣe àfiwé àwọn tí wọ́n gbọ́ tí wọ́n sì ṣe àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí ọlọgbọ́n ọkùnrin tí ó “kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta.” Ó ṣàlàyé:

“Òjò rọ̀, ìkun omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, ó sì bìlu ilé nã; kò sì wó, nítorí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.”12

Ilé kan kò lè dúró nínú ìjì kan nítorí ilé náà lágbára. Bákànnáà kò kàn lè dúró nítorí àpáta náà lágbára. Ilé náà ndúró nínú ìjì nítorí ó lè dọindọin mọ́ àpátà alágbára náà. Ó jẹ́ pé okun ìsopọ̀ sí àpáta náà ni ó ṣe kókó.

Ní àfijọ, bí a ṣe ngbé ilé ayé wa ga, ó ṣe pàtàkì láti ṣe àwọn yíyàn rere. Ó sì ṣe pàtàkì láti ní òye òtítọ́ ayérayé Olùgbàlà. Ṣùgbọ́n okun tí a ó nílò láti kojú àwọn ìjì ayé nwá nígbàtí a bá so àwọn yíyàn wa pọ̀ pẹ̀lú Jésù Krístì àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Èyí ni ohun tí Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ nrànwá lọ́wọ́ láti ṣe.

Fún àpẹrẹ, àwọn ọ̀rẹ́ yín lè mọ̀ pé ẹ ngbìyànjú láti máṣe lo èdè pípanilára tàbí bíbíni-nínú. Wọ́n lè ríi yín tí ẹ̀ nnawọ́ jáde sí ọmọdé kan ní ilé-ìwé tí púpọ̀jù àwọn ènìyàn npati tàbí àní fìyàjẹ. Ṣùgbọ́n ṣe wọ́n mọ̀ pé ẹ̀ nṣe àwọn yíyàn wọ̀nyí nítorí pé Jésù Krístì kọ́ni pé “gbogbo ènìyàn jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin yín—pẹ̀lú … àwọn ènìyàn tí wọ́n yàtọ̀ síi yín”?13

Àwọn ọ̀rẹ́ yín lè mọ̀ pé ẹ̀ nlọ sílé ìjọsìn lọ́jọjọ́ Ìsinmi. Wọ́n lè kíyèsi nígbàtí ẹ bá yí orin kan kúrò tàbí kọ ìpè láti wo eré-ìtàgé kan. Ṣùgbọ́n ṣe wọ́n mọ̀ pé ẹ nṣe àwọn yíyàn yí nítorí ẹ ní “ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú aláyọ̀ kan pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì,” àti pé bí ara ìfọkànsìn náà láti tẹ̀lé Olùgbàlà, ẹ ní ìmoore “láti ní Ẹ̀mí Mímọ́ bí ojúgba yín léraléra”?14

Àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ẹ kìí mutí tàbí mu sìgá tàbí lo àwọn egbòogi olóró míràn. Ṣùgbọ́n ṣe wọ́n mọ̀ pé ẹ̀ nṣe àwọn yíyàn wọ̀nyí nítorí Jésù Krístì kọ́ni pé “ara yín jẹ́ mímọ́,” “ẹ̀bùn ìyanu láti ọ̀dọ̀ Baba yín Ọ̀run,” tí a dá ní àwòrán ara Rẹ̀?15

Àwọn ọ̀rẹ́ yín lè mọ̀ pé ẹ kò ní rẹ́nijẹ tàbí parọ́ àti pé ẹ mú ẹ̀kọ́ kíkọ́ ní ọ̀kúnkúndùn. Ṣùgbọ́n ṣe wọ́n mọ̀ pé èyí jẹ́ nítorípé Jésù Krístì kọ́ni pé “òtítọ́ yíò sọ yín di òmìnira”?16

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ṣe àwọn ọ̀rẹ́ yín mọ̀ pé ẹ̀ nṣe àwọn yíyàn tí kò lókìkì nígbàmíràn wọ̀nyí láti dúró ní tòótọ́ sí àwọn òṣùwọ̀n ti Krístì nítorí ẹ mọ̀ pé “Jésù Krístì ni okun yín”?17

Òun Ni Okun Yín

Mo fún yín ní ẹ̀rí dídájú mi pé Jésù Krístì ni Ọ̀nà sí ọjọ́ ọ̀la dídán àti ológo—ọjọ́ ọ̀la yín. Òun bákannáà sì ni Ọ̀nà sí dídán àti ológo ti ìsisìyí. Ẹ rìn ní ọ̀nà Rẹ̀, Òun ó sì rìn pẹ̀lú yín. Ẹ lè ṣe èyí!

Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, Jésù Krístì ni okun yín. Ẹ tẹra mọ́ rírìn pẹ̀lú Rẹ̀, Òun ó sì ràn yín lọ́wọ́ láti fò “pẹ̀lú ìyẹ́ bí àwọn idì”18 sí ìhà ayọ̀ ayérayé tí Òun ti pèsè sílẹ̀ fún yín.