“Jákọ́bù àti Néfì Rí Jésù,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2024, 26–27.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2024
Jákọ́bù àti Néfì Rí Jésù
Jákọ́bù jẹ́ arákùnrin kékeré ti Néfì. A bí i lẹ́hìn tí ẹbí wọn kúrò ní Jérúsálẹ́mù. Jákọ́bù wá sí ilẹ̀ ìlérí bí ọmọdé.
Jákọ́bù àti Néfì Rí Jésù. Wọ́n ṣe àbápín àwọn ẹ̀rí wọn pẹ̀lú ẹbí wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Jésù.
Wọ́n ṣe àbápín àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Ìsàíàh pẹ̀lú. Ìsàíàh bákannáà tí rí Jésù ó sì kọ nípa Rẹ̀ nínú àwọn ìwé-mímọ́. Jákọ́bù àti Néfì lo àwọn ọ̀rọ̀ Ìsàíàh láti inú àwọn ìwé-mímọ́ láti kọ́ àwn ẹbí wọn nípa Jésù.
Wọ́n kọ́ni wípé Jésù yíò wá sí ilẹ̀-ayé. Òun yíò kú yíò sì yè lẹ́ẹ̀kansi. Wọ́n ṣe àbápín ẹ̀rí Jésù Krístì kí àwọn ẹbí wọn lè wo iwájú fún bíbọ̀ Rẹ̀.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2024. Yoruba. 19287 779