Làìhónà
Iṣẹ́ Nlá Olúwa àti Ànfàní Nlá Wa
Oṣù Keje 2024


“Iṣẹ́ Nlá Olúwa àti Ànfàní Nlá Wa,” Làìhónà, July 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kéje 2024

Iṣẹ́ Nlá Olúwa àti Ànfàní Nlá Wa

Nígbàtí a bá fẹ́ràn, pín, tí a sì pè, à nṣiṣẹ́ pẹ̀lú Olúwa láti ran ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀mí iyebíye lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀.

àwọn obìnrin méjì bí wọn ti nrìn lọ sí ìsàlẹ̀ òpópónà

Gbogbo wòlíì nínú iṣẹ́ ìríjú nlá, ìgbẹ̀hìn yí ti kọ́ àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti pín ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì. Ní ìgbà ayé mi, onírurú àpẹrẹ ni ó wá sí ọkàn:

Ààrẹ David O. McKay (1873–1970), wòlíì ìgbà ọ̀dọ́ mi, kéde pé, “Gbogbo ọmọ ìjọ jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere.”

Ààrẹ Spencer W. Kimball (1895–1985) kọ́ nípa, “Ọjọ́ fún gbígbé ìhìnrere sí àwọn ibi àti ènìyàn púpọ̀ síi ni ìhín àti nísisìyí,” a sì “gbúdọ̀ tẹ̀síwájú” ní pípín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn míràn.

Ààrẹ Gordon B. Hinckley (1910–2008) wípé: “Títóbi ni iṣẹ́ wa, púpọ̀jù sì ni ojúṣe wa ní ṣíṣe ìrànwọ́ láti wá àwọn wọnnì láti kọ́. Olúwa ti fi àṣẹ lé wa lórí láti kọ́ ìhìnrere sí gbogbo ẹ̀dá. Èyí yíò gba àwọn ìtiraka [wa] dídára jùlọ gan.”

Àti pé Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé: “iṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ ara pàtàkì ìkójọpọ̀ nlá ti Ísráẹ́lì. Ìkójọpọ̀ náá ni iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé ní òni. Kò sí ohun kankan tí a lè fi wé ní títóbi. Kò sí ohun kankan tí a lè fi wé ní pàtàkì. Àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere Olúwa—àwọn ọmọẹ̀hìn—wà nínú iṣẹ́ ìpènijà títóbi-jùlọ, èrò títóbí-jùlọ, iṣẹ́ títóbí-jùlọ lórí ilẹ̀ ayé ní òní.”

Mò wá láti mọ èyí fúnrami bí ọ̀dọ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere ní Míṣọ̀n British. Àní ó sì dá mi lójú síi ní òní. Gẹ́gẹ́bí Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì, mo jẹ́ ẹ̀rí àwọn ànfàní wa níbi gbogbo láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì nípa fífi ìfẹ́ wa hàn, pípín ìgbàgbọ́ wa, àti pípè wọn láti darapọ̀ mọ́ wa láti ní ìrírí ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì.

Iṣẹ́ Náà Nlọ̀ Síwájú

Mo ní ànfàní láti wà lórí ìyannisíṣẹ́ ní ẹ̀ká Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Ìhìnrere ti Ìjọ nígbàtí a fi àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ Wàásù Ìhìnrere Mi hàn ní 2004, àti lẹ́ẹ̀kansi nígbàtí a fi àtẹ̀jáde kejì sílẹ̀ ní 2023. Mo gbàgbọ́ pé Wàásù Ìhìnrere Mi ti bùkún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ní ọ̀nà tó jinlẹ̀.

Wàásù Ìhìnrere Mi pẹ̀lú ohun gbogbo tí a ti kọ́ láti 2004, ìdarí ìmísí láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, àti àwọn ìyípadà tí a ṣe fún pípín ìhìnrere ní ọjọ́ ìgbàlódé. Díẹ̀ lára àwọn ìyípadà wọ̀nyí ti yọrísí àṣeyege púpọ̀.

A ti ri pé pípín ìhìnrere ní àwọn ọ̀nà ìrọ̀rùn, jẹ́jẹ́, àti àdánidá nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ti “ìfẹ́, pín, pè” nbùkún ìjọba lọ́pọ̀lọpọ̀. Jésù Krístì pín ìhìnrere ní ọ̀nà yí nígbàtí Ó gbé ní ayé. Ó pín ayé Rẹ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀ Ó sì pe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (wo Matteu 11:28). Láti nifẹ, pín, àti láti pè bí Òun ti ṣe jẹ́ ìbùkún pàtàkì àti ojúṣe fún gbogbo ọmọ Ìjọ.

Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ìfẹ́

Nínú Ọgbà Gethsemane àti lórí àgbélébú, Jésù Krístì gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lé orí Ararẹ̀ Ó sì jìyà gbogbo àwọn ìkorò àti “ìrora àti ìpọ́njú àti àdánwò onírurú gbogbo” (Alma 7:11). Èyí “mú kí [Òun], … tí ó tóbi ju ohun gbogbo lọ, láti gbọ̀nrìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ihò ara” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:18). Nípasẹ̀ Ètùtù àti Àjínde Rẹ̀, Jésù Krístì ti mú ìgbàlà àti ìgbèga ṣeéṣe fún gbogbo ènìyàn.

Yíyí sí Olùgbàlà àti jíjíròrò gbogbo ohun tí Ó ti ṣe fún wa ndá ọkàn tó kún pẹ̀lú ìfẹ́ sílẹ̀ nínú wa fún Un. Nígbànáà Ó nyí ọkàn wa síwájú àwọn ẹlòmíràn ó sì npàṣẹ fún wa láti nifẹ wọn (wo John 13:34–35) àti láti pín ìhìnrere Rẹ̀ pẹ̀lú wọn (see Matteu 28:19; Mark 16:15). Bí àwọn wọnnì ní àyíká wa bá lè ní ìmọ̀lára pé a ní ìfẹ́ wọn tòótọ́ tí a si nṣe ìtọ́jú fún wọn, wọn yíò lè ṣí ọkàn wọn sí àwọn ọ̀rọ̀ wa, gẹ́gẹ́bí Ọba Lámónì ti ṣí ọkàn rẹ̀ láti gba ìhìnrere nítorí ìfẹ́ àti iṣẹ́ ìsìn Ámmónì (wo Alma 17–19).

Nígbàtí a bá pín ìhìnrere, ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́. Bí a ti nnawọ́ sí àwọn ẹlòmíràn nínú ìfẹ́—tí à nrántí pé wọ́n jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin wa àti àwọn olùfẹ́ ọmọ Baba wa Ọ̀run—àwọn ànfàní yíò ṣí sílẹ̀ fún wa láti pín ohun tí a mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́.

Ẹ Fi Taratara Ṣiṣẹ́ kí ẹ sì Ṣe Àbápín

Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó farajì sí pípín ìhìnrere ju Ààrẹ M. Russell Ballard (1928–2023). Nínú ọ̀rọ̀ ìgbẹ̀hìn ìpàdé àpapọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ẹ̀rí pé, “ọ̀kan lára àwọn nkan ológo àti yíyanilẹ́nu jùlọ ti ẹnikẹ́ni nínú ayé yi le mọ̀—pé Baba wa Ọrun àti Olúwa Jésù Krístì ti fi Ara Wọn hàn ní ọjọ́ ìkẹhìn yí àti pé a ti gbé Jósẹ́fù dìde láti mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àìlópin ti Jésù Krístì padàbọ̀sípò.”

Ní gbogbo ayé rẹ̀, àti ní àwọn kan gbogbo ayé jùlọ, Ààrẹ Ballard fi taratara ṣiṣẹ́ ní pípín ọ̀rọ̀ iyebiye yí pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ó gbà wá níyànjú láti ṣe ohun kannáà. Ó kọ́ni pé kí a pín ìhìnrere “nípa jíjẹ́ aladugbo rere àti nípa títọ́jú kí a sì fi ìfẹ́ hàn.” Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, à “nfi ìhìnrere hàn nínú ayé ti arawa, a sì … nfi àwọn ìbùkún tí ìhìnrere ní láti fúnni hàn sí [àwọn ẹlòmíràn].” Bákannáà à “njẹ́ ẹ̀rí nípa ohun tí [a] mọ̀ tí a sì gbàgbọ́ àti ohun tí [a] ní ìmọ̀lára rẹ̀.” Ààrẹ Ballard kọ́ni pé, “Ẹ̀rí mímọ́ kan … ni a lè gbe nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ọkàn àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ṣísílẹ̀ láti gbà á.”

Pípín ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ni ìfẹ́ títóbi jùlọ ti ọkàn Ààrẹ Ballard. A lè fi taratara ṣiṣẹ́—bí ó ti ṣe—ní pípín ìhìnrere nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe papọ̀. A kò mọ ẹnití ó lè máa wá ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere ní àárín wa rárá ṣùgbọ́n tí kò mọ ibi tí ó ti lè ri (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 123:12).

ọkùnrin méjì nrin lókè àwọn àtẹ̀gùn

Ẹ Nawọ́ Àwọn Ìfipè Atọkànwá

Ní ríran àwọn ẹlómíràn lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì, a pè wọ́n láti wá ní ìrírí ayọ̀ tí Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀ nmúwa. A lè ṣe èyí nípa pípè wọ́n láti wá sí ibi ṣíṣe kan, láti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tàbí láti pàdé àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere. Bákannáà a le nawọ́ ìfipè àtọkànwá sí wọn láti wá sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú wa.

À nlọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ láti “jọ́sìn Ọlọ́run àti láti ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa láti rántí Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀.” Èyí ni àkokò ànfàní fún àwọn ènìyàn láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí, súnmọ́ Olùgbàlà síi, àti láti fún ìgbàgbọ́ wọn nínú Rẹ̀ lókun.

Bí a ti nwo àwọn ọ̀nà láti ní ìfẹ́, pín, àti láti pè, àwọn ìṣètò àti ìtiraka wa níláti pẹ̀lú ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa. Bí wọn yíò bá tẹ́wọ́gba ìfipè wa kí wọ́n sì lọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa, ó ṣeéṣe púpọ̀ kí wọ́n lè tẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà sí ìrìbọmi àti ìyípadà. Mo gbàgbọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi pé àṣeyege nlá yíò wá bí a ti npe àwọn ẹlòmíràn láti wá sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dá àwọn ìbùkún tí wọ́n lè gbà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ mọ̀.

Olúwa Yíò Tọ́ Wa Sọ́nà

A kò lè mọ ohun tí àwọn àṣeyege àti ìpènijà wa yíò mú wá bí a ti nní ìfẹ́, pín, tí a sì npè. Àwọn ọmọ Mòsíà “lọ láti ìlú dé ìlú, àti láti ilé ìjọsìn kan sí òmíràn, … ní àárín àwọn ará Lámánì, Láti wàásù àti láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làárín wọn; bayi ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àṣeyọrí púpọ̀púpọ̀.” Nìpasẹ̀ ìtiraka wọn, “ẹgbẹgbẹ̀rún ni a mú wá sí ìmọ̀ Olúwa,” ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì “yípadà tí wọn … [kò sì] ṣubú kúrò lọ́nà ná mọ́” (Álmà 23:4–6).

Nígbàtí èyí kò ní jẹ́ ìrírí wa nígbàgbogbo, Olúwa ti ṣe ìlérí pé Oùn yíò ṣiṣẹ́ lẹgbẹ wa nítorí gbogbo ẹ̀mí ni ó jẹ́ iyebíye sí I. Bí a ti nfi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Olúwa tí à sì nṣiṣẹ́ ìsìn Rẹ̀, Òun yíò tọ́ wasọ́nà ní bí a ti lè pín ìhìnrere Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nípa níní ìfẹ́ wọn, pípín ìgbé ayé wa àti ẹ̀rí pẹ̀lú wọn, àti pípè wọ́n láti darapọ̀ mọ́ wa ní títẹ̀lé E.

“Bí ayọ̀ [wa] ó ti pọ̀ tó” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18:15) nígbà tí a bá lo àwọn ànfàní ní àyíká wa láti ran Olúwa Jésù Krístì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ títóbí ti mímú àwọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: David O. McKay (2003), xxii.

  2. Àwọn Ìkọ́ni Ààrẹ Ìjọ: Spencer W. Kimball (2006), 222–23.

  3. Gordon B. Hinckley, “Wá Ọ̀dọ́-àgùtàn, Bọ́ àwọn Àgùtàn,” Liahona, July 1999, 121. Ọ̀rọ̀ yí ni a fúnni ní Ọjọ́ Kọkànlélógún Oṣù Kejì, 1999, nígbà ìtàkiri àgbéká ojú ọ̀run láti Àgọ́ Salt Lake.

  4. Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” Lìàhónà, Oṣù Kẹwa 2022, 11.

  5. M. Russell Ballard, “Ìyìn Fún Ọkùnrin Náà,” Liahona, Nov. 2023, 74.

  6. M. Russell Ballard, “Ojúṣe Pàtàkì Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere Ọmọ Ìjọ,” Liahona, May 2003, 40.

  7. M. Russell Ballard, “Rántí Ohun Tó Ṣe Kókó Jùlọ,” Liahona, May 2023, 107.

  8. Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà Kan Sí Pípín Ìhìnrere Jésù Krístì (2023), 88.

  9. Wo Wàásù Ìhìnrere Mi, 172.