“Árọ́nì Kọ́ Ọba,” Fríẹ́ndì , Oṣù Kéje 2024, 26–27.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kéje 2024
Árọ́nì Kọ́ Ọba
Árọ́nì ni ọ̀kan lára àwọn ọmọ Mòsíà. Ó jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere kan. Ó kọ́ ọba àwọn Lámánì lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
Árọ́nì bèèrè lọ́wọ́ ọba bí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ọba wípé òun ó gbàgbọ́ bí Árọ́nì bá wí fún òun pé Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́. Ó ni kí Árọ́nì wí fún òun nípa Ọlọ́run síi.
Árọ́nì ka àwọn ìwé mímọ́ sí ọba. Ó kọ́ni nípa ìṣẹ̀dá ilẹ̀-ayé. Ó kọ́ni nípa ètò Ọlọ́run. Ó wí fún ọba nípa Jésù Krístì.
Lẹ́hìnwá, ọba gbàdúrà. Ó bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run bí ohun tí Árọ́nì wí bá jẹ́ òtítọ́. Ọba gbà ìdáhùn pé òtítọ́ ni!
Ọba gbà ohun tí Arọ́nì kọ́ gbọ́. Gbogbo àwọn ènìyàn nínú agbogb-ilé rẹ̀ gbàgbọ́ bákannáà. Wọ́n ṣe ìrìbọmi wọ́n sì yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kéje 2024. Yoruba. 19348 779