Làìhónà
Ẹ̀wù ti Oyè-àlùfáà Mímọ́
Oṣù Kẹsan 2024


“Ẹ̀wù ti Oyè-àlùfáà Mímọ́,” Làìhónà, Oṣù Kẹsan 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kesan 2024

Ẹ̀wù ti Oyè-àlùfáà Mímọ́

Bí ara ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, a ti fún wa ní ìránniléti àfojúrí mímọ́ kan nípa àwọn májẹ̀mú wa—àmì Olùgbàlà Fúnrarẹ.

Ádámù àti Éfà nrìn papọ̀

Àlàyé láti inú Adámù àti Éfà, láti ọwọ́ Douglas M. Fryer

Láìka ìmúrasílẹ̀ tí a fún wọ́n láìṣiyèméjì sí àti àwọn àtúnṣe-ìdánilójú tí wọ́n ngbìyànjú láti rántí, ó gbọ́dọ̀ ti jẹ́ ìyàlẹ́nu ìgbọ̀ntìtì sí Ádámù àti Éfà láti fi Ọgbà Édẹ́nì wọn bíi párádísè sílẹ̀ tí wọ́n sì gbésẹ̀ sínú ayé ìṣubú.

Pẹ̀lú ìfura ọ̀wọ̀, wọ́n mọ ohun tí ó túmọ̀ sí láti ṣe ìpààrọ̀ ìgbé ayé ìsìnmi, òmìnira fún ayé àtakò àti ìlàágùn, àwọn ẹ̀gún àti ìbànújẹ́—nígbẹ̀hìn ohun kan tí à pè ní ikú á tẹ̀le. Wọn lè má mọ ohun tí gbogbo èyí túmọ̀ sí ní ìbẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n láìpẹ́ wọ́n kẹkọ pé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan le mú ìrora titun wá. Nítòótọ́, èyítí ó ronilára jùlọ nínú gbogbo rẹ̀ ni ìdámọ̀ pé wọn yíò kojú gbogbo èyí ní ìyapa kúrò ní ọ̀dọ̀ Baba wọn ní Ọ̀run——“ní lílé jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀,” ni Mósè yíò ṣe àkọsílẹ̀ lẹ́hìnwá.

Fífúnni ní ìyapa àti ìdánìkanwà yí nínú ayé tútù, ṣíṣókùnkùn, ó ti gbúdọ̀ jẹ̀ títuni-nínú tó fún Ádámù àti Éfà láti rántí ohun kan: pé àwọn ìlérí ti jẹ́ ṣíṣe—ohun mímọ́ àti ti ayérayé kan tí à pè ní àwọn májẹ̀mú. Wọ́n tì ṣe ìlérí pé àwọn yíò gbọ́ràn sí Baba ní gbogbo ayé wọn, Òun sì ti ṣe ìlérí láti pèsè Olùgbàlà kan, ẹni tí yíò dín ìrora àti ìbànújẹ́ wọn kù, ṣe ètùtù fún àwọn àṣìṣe wọn, àti tí yío mú wọn padà wá láìléwu sí iwájú Rẹ̀.

Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ẹni kíkú wọ̀nyí ó ṣe rántí ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí? Báwo ni wọn ó ṣe dúró nínú ìfura ipò ewu wọn—ìfura gbogbo ìgbà, lọ́san àti ní òru?!

Ìránnilétí kan nípa àwọn Májẹ̀mú Wọn

Fún irú ìránnilétí kan bẹ́ẹ̀ Ó fún wọn ní “àwọn ẹ̀wù awọ.” Èyí ti jẹ́ ẹ̀bùn kan tó ó sì ti bọ́ sí àkokò tó. Lẹ́hìn jíjẹ nínú èso kíkà léèwọ̀ náà, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ lọ́gán ni Ádámù àti Éfà fura pé àwọn wà ní ìhòhò. Lakọkọ, wọ́n gbìyànjú láti bo ìhòhò wọn pẹ̀lú àwọn ewé ọ̀pọ̀tọ́. Lẹ́hìnnáà, ní bíbẹ̀rù pé èyíinì kò tó, wọ́n gbìyànjú láti sápamọ́ kúrò lọ́dọ̀ Olúwa. (Irú ìṣe agọ́ kan bẹ́ẹ̀ jẹ́ híhàn pé ikú nwọlé bọ̀ wá!) Láti àkokò náà sí ìsisìyí, olùfẹ́ni Baba kan ti pe àwọn ọmọ Rẹ̀ láti wá, jáde láti ibi ìsápamọ́, sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Àti bíi ti àwọn ẹ̀wù awọ ìgbànáà àti onírurú àwọn ohun èlò ìwọṣọ láti ìgbà náà, Òun nínú àánú Rẹ̀ kò tíì fi wá sílẹ̀ ní ìhòhò ṣùgbọ́n ó ti wọ aṣọ fún àwọn olùgbọ́ran nínú “ẹ̀wù òdodo,” ìránnilétí àwọn ìlérí àti májẹ̀mú wa. Àwọn “ẹ̀wù ìgbàlà” wọ̀nyí ṣe àfihàn àmì ẹ̀bùn títóbi jùlọ ninu gbogbo rẹ̀, Ètùtù Jésù Krístì.

Ẹ̀wù Náà Jẹ́ Àmì kan ti Olùgbàlà

Ó dára, gbogbo ríronú yí nípa Ádámù àti Éfà àti àwọn májẹ̀mú àti ìwọṣọ jẹ́, nítòótọ́, ohun tó ju ìdárayá ọpọlọ kan lásán lọ. Kò le láti fi ojú inú wo bí Ádámù àti Éfà ti ní ìmọ̀lára, nítorí àwa náà nkojú àwọn ìdàmú nínú ayé ìṣubú yí. Àwà náà ti jẹ́ yíyapa kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì nmú ara wa jìnnà síwájú síi ní gbogbo ìgbà tí a bá ní ìrékọjá. Bíiti Ádámù àti Éfà, a ti fún wa ní Olùgbàlà kannáà, Jésù Krístì ti Násárẹ́tì, Álphà àti Ómégà, Ọmọ Ọlọ́run alàyè. Bíiti Ádámù àti Éfà, a ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Àti, bí ara ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, a ti fún wa ní ìránniléti àfojúrí mímọ̀ kan nípa àwọn májẹ̀mú wọnnì—àmì kan ti Olùgbàlà Fúnrarẹ. Ní àkokò ìríjú wa à pè é ní ẹ̀wù ti oyè-àlùfáà mímọ́.

àwòrán Jésù Krístì

Àlàyé láti inú Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì, láti ọwọ́ Harry Anderson

À nwọ ẹ̀wù yí lábẹ́ àṣọ ìta wa. Eyikeyi àwọn ojúṣe tí mo ní, eyikeyi àwọn ipa tí mo bá kó nínú ayé, eyikeyi àwọn ojúṣe tí ìgbé ojojúmọ́ nílò, lábẹ́ gbogbo rẹ̀ ni àwọn májẹ̀mú mi wà—nígbà gbogbo àti títíláé. Lábẹ́ gbogbo rẹ̀ ni àwọn ìlérí mímọ́ wọnnì wà èyí tí mo rọ̀mọ́ pẹ̀lú ìtara. Ẹ̀wù náà kìí ṣe àgbéká tàbí àfihàn níwájú aráyé, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn májẹ̀mú mi. Ṣùgbọ́n mo máa npa mèjèjì mọ́ súnmọ́ mi—ní sísúnmọ́ bí mo ti lè ṣe tó. Wọ́n jẹ́ ti araẹni tó lágbára àti mímọ́ tó lọ́lá julọ.

Ní rírántí àwọn májẹ̀mú wọnnì, àwọn ìlérí ọ̀nà-méjì wọnnì, à nwọ ẹ̀wù náà ní gbogbo ayé wa. Ìṣe yí nhàn nínú ìfẹ́-inú wa fún Olùgbàlà láti jẹ́ ipa nínú ayé wa léraléra. Àwọn àyànfẹ́ àmì míràn jẹ́ ti àkokò. A nṣe ìrìbọmi nígbàkan nínú ayé wa. A nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀. À nlọ sí tẹ́mpìlì bí àwọn ipò bá ti gbà. Ṣùgbọ́n ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́ náà yàtọ̀: àmì yí ni à nbu-ọlá fún ní gbogbo ọ̀sán àti òru.

Àti pé bẹ́ẹ̀ni àwọn májẹ̀mú ṣe wà—kìí ṣe gbígbé sẹgbẹ nítorí ìrọ̀rùn tàbí àìnáání kíì sì ṣe títúnṣe láti bá àwọn ẹ̀yà àti ọ̀ṣọ́ àwùjọ̀ mu. Nínú ìgbésí ayé ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì kan, àwọn ọ̀nà ayé gbúdọ̀ di títúnṣe láti wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú wa, kìí ṣe ní ọ̀nà míràn yípo.

Nígbàtí a bá wọ ẹ̀wù náà, bí Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti kọ́ni, à ngbé àmì mímọ́ Jésù Krístì wọ̀. Tí èyí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kínìdí tí a ó fi wá àwáwí láti mú àmì náà kúrò? Kínìdí tí a ó fi mú ara wa kúrò nínú ìlérí agbára, ààbò, àti àánú tí ẹ̀wù náà nrọ́pò? Ní ìlòdì sí, ìgbàkugbà tí a bá ní láti bọ́ ẹ̀wù náà sílẹ̀ ránpẹ́, a níláti nítara láti wọ̀ ọ́ padà, ní àìpẹ́ bí ó bá ti ṣeéṣe tó, nítorí a rántí méjèjì àwọn ìlérí àti ewu tí ó nfún àwọn májẹ̀mú wa ní ìtumọ̀. Ní òpin gbogbo rẹ̀, a rántí àgbélèbú àti ibojì ṣíṣófo ti Krístì.

Àwọn kan lè wípé, “Mo ní àwọn ọ̀nà míràn láti rántí Jésù.” Èmi ó sì fèsì, ìyẹn náà dára. Bí ó ti pọ̀ sí ní ó dára sí. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ronú àwọn ọ̀nà púpọ̀ bí a ti lè ṣe tó láti pa àwọn ìfarajìn wa mọ́ láti “rántí rẹ̀ nígbàgbogbo.” Ṣùgbọ́n ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, yíò jẹ́ irọ́ láti mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìpatì ìrántí tí Olúwa Fúnrarẹ̀ fún àwọn tó ní ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, ẹ̀wù ti oyè-àlùfáà mímọ́.

Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ túmọ̀ sí ohun gbogbo fún mi. Gbogbo àwọn ìrètí ayérayé àti ìlépa mi, gbogbo ohun tí ó ṣọ̀wọ́n sí mi, dá lórí Rẹ̀. Òun ni “àpáta ìgbàlà mi,” àyè ọ̀nà mi sí Baba mi Ọ̀run, ọ̀nà mi kanṣoṣo padà sí ohun tí mo ní nígbàkan rí tí mo sì fẹ́ ní lẹ́ẹ̀kansi, lẹgbẹ pẹ̀lú púpọ̀ gan síi. Ẹ̀bùn Rẹ̀ fún wa ni inúrere jùlọ tí mo ti gbà rí, inúrere jùlọ tí a fúnni rí—tí a rà bí ó ti wà pẹ̀lú ìjìyà àìlópin, tí a nà sí iye àìlópin, tí a fúnni pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin. Àwọn ẹ̀gún àti òṣùṣú, ìrora àti àròkàn, ìbànújẹ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ ayé ìṣubú yí gbogbo “ni ó di gbígbémì nínú Krístì.”

Nítorínáà mo ti wọ ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́—ní gbogbo ọ̀sán àti òru bí ó ti tọ́ láti ìgbà tí mo ti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ní ọgọ́ta ó lé mẹ̀rin ọdún sẹ́hìn, ní ọjọ́ orí ọdún mọ́kàndínlógún—nítorí mo nifẹ Rẹ̀ àti nítorípé mo nílò àwọn ìlérí tí ó rọ́pò.

Àwọn Ìbèèrè nípa Wíwọ Ẹ̀wù náà?

Àwọn kan lára yín lè máa ka àtẹ̀kọ yí ní ìrètí pé èmi yíò dáhùn ìbèèrè pàtàkì kan nípa ẹ̀wù náà. Ẹ lè ní ìrètí fún “Bayi ni Olúwa wí kan”—àní tàbí “Bayi ni àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ wí kan”—lórí ọ̀ràn tí ó súnmọ́ ọkàn yín. Ìbèèrè yín lè wá láti inú ipò araẹni kan tí ó bá iṣẹ́, ìdárayá, ìmọ́tótó, àyíká, ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, àwọn ibi ètò ìtọ́jú ara, àní tàbí ipò ìlera kan.

Àwọn ìdáhùn kan sí irú àwọn ìbèèrè wọ̀nyí ni a lè rí ní temples.ChurchofJesusChrist.org àti ní ìpín 38.5 ti Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò. Àwọn ọmọ ẹbí tí a gbẹ́kẹ̀lé àti àwọn olùdarí ni a lè kàn sí nípa ọ̀ràn araẹni kan. Bákannáà, ìdarí híhàn kedere gidi wà, tí a fúnni nínú àwọn ìlànà ìgbaniwọlé, àti pé Baba yín ní Ọ̀run wà títí láé àti láéláé, ẹnití ó mọ̀ yín tí ó sì fẹ́ràn yín tí ó sì ní òye ohun gbogbo nípa àwọn ipò yín. Inú Rẹ̀ yíò dùn tí ẹ bá le bì I ní àwọn ìbèèrè wọ̀nyí fún ara yín.

ilé agogo ti Tẹ́mpìlì St. George Utah

Àwòrán ilé agogo ti Tẹ́mpìlì St. George Utah

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe ṣì gbọ́. Bí ẹ ti nnawọ́ jáde fún ìtọ́nisọ́nà ti ọ̀run, Ẹ̀mí kò mí sí yín láti ṣe dínkù ju títẹ̀lé ìkọ́ni tí a gbà nínú tẹ́mpìlì àti ìmọ̀ràn bíi-ti-wòlíì tí a pín nípasẹ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní nínú ọ̀rọ̀ wọn àìpẹ́. Olùfẹ́ni Baba kan kò ní ràn yín lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n inú ṣe dínkù ju bí ẹ ti lè ṣe láti wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n Rẹ̀ ti ìfọkànsìn àti ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí yíò bùkún yín nísisìyí àti títíláé. Ṣùgbọ́n njẹ́ Òun ní òye àwọn ìbèèrè yín, àti pé njẹ́ Òun ó ràn yín lọ́wọ́ láti gba àwọn ìbùkún ti bíbu-ọ̀wọ̀ fún ẹ̀wù náà àti pípa àwọn májẹ̀mú yín mọ́? Bẹ́ẹ̀ni! Bákannáà njẹ́ ẹ níláti gbàmọ̀ràn pẹ̀lú àwọn akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ egbògi àti ètò ìlera nígbàtí a bá nílò? Bẹ́ẹ̀ni! Njẹ́ ẹ nílati ṣe àìkàsí ọgbọ́n ìwọ́pọ̀ tàbí wò kọjá àmì náà bí? Mo gbàdúrà pé ẹ kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.

Èmi kò lè dáhùn gbogbo ìbèèrè tí ẹ ní. Èmi kò tilẹ̀ lè dáhùn gbogbo ìbèèrè tí mo ní. Ṣùgbọ́n bíi Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì kan, mo lè ṣe ìlérí fún yín ní ti ìrànlọ́wọ́ olùfẹ́ni Ọlọ́run kan, ẹnití ó nwá gbogbo àṣeyege àti ìbùkún yín, ní àwọn ọ̀nà tí ẹ kò lè wọ̀n tàbí rí tẹ́lẹ̀ nísisìyí, bí ẹ ti npa àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti dá mọ́ pẹ̀lú Rẹ̀.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Mósè 5:4.

  2. Mósè 4:27.

  3. Wo Mósè 4:13–14.

  4. Wo Isaiah 61:10; 2 Nefi 9:14; bákannáà wo Ìfihàn 19:8; 2 Nefi 4:33; Mọ́mọ́nì 9:5; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:76.

  5. Ó hàn gbangbà pé, ẹ̀wù tí à nwọ̀ ní òní kò bárajọ sí àwọn ẹ̀wù awọ tí a fifún Ádámù àti Éfà. Ẹ̀wù náà ti yípadà ní onírurú àwọn ọ̀nà bí àwọn ọdún ti nkọjá lọ, nínú ohun èlò àti àwòrán pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àwọn ohun tí ó ṣe kókó lotitọ—ìwàẹ̀dá mímọ́ ti ẹ̀wù náà, àwọn májẹ̀mú tí ó nṣojú—kò yípadà.

  6. Orúkọ kíkún yìí ti ẹ̀wù náà, bíi ti orúkọ kíkún ti Ìjọ, jẹ́ ìkọ́ni. Oyè-àlùfáà jẹ́ agbára Ọlọ́run, àti pé wíwọ ẹ̀wù náà jẹ́ ìránnilétí kan nípa agbára ti-ọ̀run tí ó wà fún wa nígbàtí a bá dá tí a sì pa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́.

  7. Mórónì 4:3; 5:2.

  8. 2 Nefi 4:30.

  9. Álmà 16:8; wo bákanáà Álmà 31:38.