Àwọn Ìwé Mímọ́
Mọ́mọ́nì 4


Orí 4

Ogun àti ìparun tẹ̀síwájú—Àwọn ènìyàn búburú nfìyàjẹ àwọn ènìyàn búburú—Ìwa búburú èyítí ó burú jùlọ gbilẹ̀ jù ti àtẹ̀hìnwá ní gbogbo Ísráẹ́lì—Nwọ́n fi àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé rúbọ sí àwọn òrìṣà—Àwọn ara Lámánì bẹ̀rẹ̀sí gbá àwọn ará Nífáì kúrò níwájú wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 363 sí 375 nínú ọjọ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̃dúnrún ọdún àti ìkẹta tí àwọn ara Nífáì sì gòkè lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn láti kọlũ àwọn ará Lámánì, kúrò nínú ilẹ Ibi-Ahoro.

2 O sì ṣe tí wọn tún lé àwọn egbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì padà sí ilẹ̀ Ibi-Ahoro. Àti bí wọn sì ti wà nínú ipò ãrẹ̀ lọ́wọ́ ogun tí wọn njà, àkọ̀tun ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ara Lámánì tún kọ lù wọ́n; wọ́n sì jà ogun gbígbóná, tóbẹ̃ tí àwọn ara Lámánì gbà ìlú-nlá Ibi-Ahoro, tí wọn sì pa púpọ̀ nínú àwọn ara Nífáì, tí wọn sì kó púpọ̀ lẹ́rú.

3 Àwọn tí ó kù sì sá, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn olùgbé inú ìlú-nlá Tíákúmì. Nísisìyí ìlú-nlá Tíákúmì wà ní àwọn ãlà ní ẹ̀bá bèbè òkun; ó sì tún súnmọ́ ìlú-nlá Ibi-Ahoro.

4 Àti nítorípé àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Nífáì kọjá lọ í kọlu àwọn ará Lámánì ní àwọn ara Lamanì ṣe bẹ̀rẹ̀sí pa wọ́n; nítorítí bí kò bá rí bẹ̃, àwọn ará Lámánì kì bá tí ní agbára lórí wọn.

5 Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, ìdájọ́ Ọlọ́run yíò wà lórí ènìyàn búburú; nípasẹ̀ ènìyàn búburú sì ni a ó fì ìyà jẹ ènìyàn búburú; nítorípé àwọn ènìyàn búburú ní í máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè sí ìtàjẹ̀sílẹ̀.

6 O sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ṣe ìmúrasílẹ̀ láti kọlũ ìlu-nla Tíákúmì.

7 O sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̃dúnrún ọdún àti ìkẹrin àwọn ara Lamanì sì kọlu ìlú-nlá Tíákúmi, láti lè gbà ìlú-nlá Tíákúmì pẹ̀lú.

8 O sì ṣe tí àwọn ara Nífáì lù wọ́n tí wọn sì lé wọn padà sẹ́hìn. Nígbàtí àwọn ará Nífáì sì ríi pe àwọn ti lé àwọn ara Lámánì padà wọn tún nyangàn nínú agbára ara wọn; wọ́n sì jáde lọ nínú ipá tí ara wọn, wọn sì tún gbà ìlú-nlá Ibi-Ahoro.

9 Àti nísisìyí gbogbo ohun wọ̀nyí ní wọn tí ṣe, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni wọ́n sì ti pa ni apá méjẽjì, àti àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lamanì.

10 O sì ṣe tí ọ̀tà lé lọ̃dúnrún ọdún àti mẹfà ti kọjá lọ, àwọn ara Lámánì sì tún padà wá kọlũ àwọn ara Nífáì nínú ogun; sibẹ̀ àwọn ara Nífáì kò ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà ibi èyítí wọn ti hù, ṣùgbọ́n wọ́n tẹramọ́ iwa búburú wọn títí.

11 Ó sì ṣòro fún ahọ́n láti ṣe àpèjúwe, tàbí fún ènìyàn láti kọ ní pípé nípa bí ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìparun èyítí ó wà lãrín àwọn ènìyàn nã ti banilẹ́rù tó, àti nínú àwọn ara Nífáì àti nínú àwọn ara Lamanì, gbogbo ọkàn ni ó sì sé le, tí wọn sì nyọ̀ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ títí.

12 Kò sì sí irú ìwà búburú tí ó tó bayĩ rí ní ãrín gbogbo ìran Léhì, tàbí ní ãrín gbogbo ìdílé Ísraẹlì papã, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí irú èyítí ó wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ.

13 O sì ṣe tí àwọn ara Lamanì gbà ìlú-nlá Ibi-Ahoro nã, èyí sì rí bẹ nítorípé iye wọn tayọ iye àwọn ara Nífáì.

14 Nwọn sì kọjá lọ pẹ̀lú láti kọlũ ìlú-nlá Tíákúmì, wọn sì lé àwọn tí ngbé inú ìlú nã jáde kúrò nínú rẹ̀, wọn sì kó ẹrú púpọ̀ àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, wọ́n sì pa wọ́n fún ìrúbọ sí àwọn òrìṣà wọn.

15 O sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̃dúnrún ọdún o le méje, àwọn ara Nífáì bínú nítorípé àwọn ara Lámánì ti fi àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn rúbọ, wọn sí lọ í kọlũ àwọn ara Lámánì pẹ̀lú ìbínú tí ó pọ̀ púpọ̀, tó bẹ̃ tí wọn tún lù àwọn ara Lamanì, tí wọ́n sì lé wọn kúrò lórí awọn ilẹ̀ wọn.

16 Àwọn ara Lamanì kò sì tun padà láti kọlũ àwọn ara Nífáì títí di ọ̀rìn lé lọ̃dúnrún ọdún ó dín márún.

17 Nínú ọdún yĩ sì ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti kọlũ àwọn ara Nífáì pẹ̀lú gbogbo agbára wọn; a kò sì lè kà wọ́n nítorípé iye wọn pọ̀ jùlọ.

18 Láti àkókò yĩ lọ sì ni àwọn ara Nífáì kò lè gbà agbára lórí àwọn ara Lamanì, ṣùgbọ́n tí àwọn ará Lamanì bẹ̀rẹ̀sí pa wọ́n run àní gẹ́gẹ́bí ìrì níwájú oòrùn.

19 O sì ṣe tí àwọn ara Lamanì sì sọ̀kalẹ̀ wa láti kọlũ ìlú-nlá Ibi-Ahoro; wọn sì ja ogun gbígbóná nínú ilẹ̀ Ibi-Ahoro, nínú èyítí wọ́n lù àwọn ara Nífáì.

20 Wọ́n sì tún sá kúrò níwájú wọn, wọ́n sì dé ìlú-nlá Bóásì; níbẹ̀ ní wọ́n sì dojúkọ àwọn ara Lamanì pẹ̀lú ìgboyà títóbi, tóbẹ̃ tí àwọn ara Lamanì kò lù wọ́n títí wọ́n tún padà wá ní ìgbà kéjì.

21 Nígbàtí wọn sì tún padà wa ní ìgbà kéjì, wọ́n lé àwọn ara Nífáì wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa; wọn sì tun fi àwọn obìnrin wọn àti àwọn ọmọ wọn rubọ sí àwọn orìṣà.

22 O sì ṣe tí àwọn ara Nífáì tún sá kúrò níwájú wọn, tí wọn kó gbogbo àwọn olùgbé inú ìlú nã pẹ̀lú wọn, àti nínú àwọn ilu àti àwọn ìletò.

23 Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, nítorítí mo wòye pé àwọn ara Lámánì ti fẹ́rẹ̀ gbà gbogbo ilẹ nã tan, nitorinã ni emi lọ sí orí òkè Ṣímù, tí mo sì gbé gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ èyíti Ámmárọ́nì tí gbé pamọ́ sí Olúwa.

Tẹ̀