Orí 8
Àwọn ará Lámánì lépa àwọn ará Nífáì wọ́n sì pa wọ́n run—Ìwé ti Mọ́mọ́nì yíò jáde wá nípa agbára Ọlọ́run—A fi àwọn tí ó nmí ẽmí ìbínú àti ohùn asọ̀ sí iṣẹ́ Olúwa bú—Akọsílẹ̀ àwọn ara Nífáì yíò jáde wa ní ọjọ́ ìwà búburú, ìfàsẹ́hìn, àti ìṣubú-kúrò nínú òtítọ́. Ní ìwọ̀n ọdun 400 sí 421 nínú ọjọ Olúwa wa.
1 Ẹ kíyèsĩ emí, Mórónì, parí àkọsílẹ̀ tí baba mi, Mọ́mọ́nì kọ. Ẹ kíyèsĩ, ohun diẹ̀ ni èmi ní láti kọ, tí ó jẹ́ àwọn ohun tí baba mi ti pa láṣẹ fún mi.
2 Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn ogun nla àti èyítí ó pọ tí á jà ní Kùmórà, ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì tí wọn ti sálọ sinu ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gũsù ní àwọn ara Lámánì dọdẹ, titi wọn fi pa gbogbo wọn run.
3 Àti bàbá mi ni wọ́n pa pẹ̀lú, àní èmí nìkan ni o sì kù láti kọ nípà ìtàn ìparun àwọn ènìyàn mi, èyítí ó baninínújẹ́. Ṣugbọn kíyèsĩ, wọ́n ti lọ, emí sì ṣe èyítí baba mi pa láṣẹ fún mi. Bí wọn ó bá sì pa mi, èmi kò mọ̀.
4 Nitorinã èmi yíò kọ, emí yíò sì gbé àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́ sínú ilẹ̀; ibití èmi sì nlọ kò ja mọ́ nkan.
5 Ẹ kíyèsĩ, baba mi ti ṣe àkọsílẹ̀ yĩ, o sì ti kọ ohun ti ó wà fun. Ẹ sì kíyèsĩ, emí yíò kọ ọ́ pẹ̀lú bí èmí bá rí àyè lórí àwọn àwo nã, ṣùgbọ́n èmi kò rí; emí kò sì ní irin àìpò tútù rárá, nítorítí ó kù èmi nìkan. A ti pa Bàbá mi nínú ogun, àti gbogbo àwọn ìbátan mí, èmi kò sì ní ọ̀rẹ́ tàbí ibití èmi lè lọ; èmi kò sì mọ̀ bí Olúwa yíò ti gbà kí èmi ó wa lãyè pẹ́ to.
6 Ẹ kíyèsĩ, irinwó ọdún tí kọjá lọ láti ìgbà wíwá Olúwa àti Olùgbàlà wa.
7 Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ara Lámánì ti dọdẹ àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì, láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, àti láti ibìkan dé ibìkan, àní títí wọn fi pa gbogbo wọn; ìsubú wọn sì pọ̀; bẹ̃ni, títóbi àti ìyanilẹ́nu sì ni ìparun àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì.
8 Ẹ sì kíyèsĩ, ọwọ Olúwa ni ó ṣe é. Ẹ sì kíyèsĩ pẹ̀lú, àwọn ara Lámánì nbá ara wọn jagun; gbogbo orí ilẹ̀ nã ní ó sì kún fun ipanìyàn àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ títí; kò sì sí ẹnití ó mọ́ àkókò tí ogun nã dópin.
9 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, èmi kò ṣọrọ̀ mọ́ nípa wọn, nítorítí kò sí ẹnikẹ́ni mọ́ àfi àwọn ará Lámánì àti àwọn ọlọ́ṣà tí ó wà lórí ilẹ̀ nã.
10 Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ̀ Ọlọ́run otitọ bíkòṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù, tí wọn duro nínú ilẹ̀ nã títí ìwà búburú àwọn ènìyàn nã fi pọ̀ tóbẹ̃ tí Olúwa kò jẹ́ ki wọn ó wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn nã; bí wọn bá sì wa lórí ilẹ̀ nã ẹnikẹ́ni kò mọ̀.
11 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Bábà mi àti emí ti rí wọn, wọn sì ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí wa.
12 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà àkọsílẹ̀ yĩ, tí kò sì dá a lẹ́bi nitori àwọn àìpé tí ó wà nínú rẹ̀, ẹni nã ni yíò mọ̀ àwọn ohun tí ó ta àwọn wọ̀nyí yọ. Ẹ kíyèsĩ, emí ni Mórónì; bí ó bá sì ṣeéṣe ní, emí yíò sọ ohun gbogbo di mímọ̀ fún yín.
13 Ẹ kíyèsĩ mo fi opin sí sísọ nípa àwọn ènìyàn yĩ. Emí ní ọmọ Mọ́mọ́nì, bàbá mi sì jẹ́ ìran Nífáì.
14 Emí sì ni ẹni nã tí ó gbé àkọsílẹ̀ yĩ pamọ́ sí Olúwa; àwọn àwo rẹ̀ kò ní iye lórí, nitori àṣẹ Olúwa. Nítorítí o sọ ọ́ nítõtọ́ pé ẹnikẹni kò gbọ́dọ̀ ní wọ́n láti ní èrè; ṣùgbọ́n àwọn àkọsílẹ̀ inú rẹ̀ jẹ iyebíye; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ di mímọ̀, òun ni ẹnití Olúwa yíò bùkún.
15 Nítorítí kò sí ẹniti ó lè ní agbara láti sọ ọ́ di mímọ̀ bíkòṣe kí Ọlọ́run fi í fún un; nítorítí Olọ́run fẹ kí a ṣeé pẹ̀lú ìfọkànsìn àti ògo rẹ̀ nìkán, tabi ní ìlépa àlãfíà àwọn ẹni ìgbànì ti Olúwa bá da májẹ̀mú, ti wọn sì ti di ìfọnká.
16 Alabùkún sì ni fún ẹni nã tí yíò sọ ohun yĩ di mímọ̀; nítorítí a ó mũ jáde láti inú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ, gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; bẹ̃ni, a ó múu jáde láti inu ilẹ̀, yíò sì tan jáde láti inú òkùnkùn, yíò sì wá sí ìmọ̀ àwọn ènìyàn nã; a ó sì ṣe é nípa agbara Ọlọ́run.
17 Bí àbùkù bà sì wà nínú àkọsílẹ̀ nã, àṣìṣe tí ènìyan ni. Ṣugbọn ẹ kíyèsĩ, àwa kò mọ̀ àbùkù kankan; bíótilẹ̀ríbẹ̃ Ọlọ́run ni ó mọ̀ ohun gbogbo; nitorinã, ẹniti o bá dã lẹbi, jẹ ki o ṣọ́ra kí ó máṣe bọ́ sínú iparun iná ọ̀run àpãdì.
18 Ẹniti ó bá sì wipe: Fi í hàn mí, bíkòjẹ́ bẹ̃ a ó lù ọ́—jẹ́ kí o sọ́ra kí o máṣe pàṣẹ èyiti Olúwa tí dánilẹ́kun rẹ̀.
19 Nítorí ẹ kíyèsĩ, ẹniti ó bá kánjú ṣe ìdájọ́ ni a ó tún kánjú ṣe ìdájọ fún; nítorí gẹgẹbi iṣẹ́ rẹ̀ ni èrè rẹ̀ yíò rí; nitorinã, ẹniti ó bá lù ènìyàn ni Olúwa yíò tún lù.
20 Ẹ kíyèsí ohun tí ìwé mímọ́ sọ—ẹnikẹni kò gbọ́dọ̀ lù ènìyàn, bẹ̃ni kò gbọ́dọ̀ dánilẹ́jọ́; nitori temi ni idájọ́, ni Olúwa wí, temi sì ni ẹ̀san pẹ̀lú, èmi yíò sì gbẹ̀san.
21 Ẹniti ó bá sì mí èmí ìbínú àti ìjà sí iṣẹ́ Olúwa, àti sí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa tí í ṣe ìdílé Ísráẹ́lì, tí yíò sì wípé: Àwa yíò pa iṣẹ́ Olúwa run, Olúwa kò sì ní rántí májẹ̀mú rẹ̀ èyítí ó ti dá pẹ̀lú ìdílé Ísráẹ́lì—ẹni nã ni ó wà nínú ewu tí a ó ké e lulẹ̀, tí a ó sì sọ ọ́ sínú iná;
22 Nítorítí èrò ayérayé Olúwa yíò tẹ̀ síwájú, títí gbogbo ìlérí rẹ̀ yíò fi di mímúṣẹ.
23 Ẹ ṣe ìwádi nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah. Ẹ kíyèsĩ, èmi kò lè kọ wọn. Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, pé àwọn ènìyàn mímọ́ nnì tí wọ́n ti kọjá lọ ṣãjú mi, tí wọn ti ní ilẹ̀ yĩ ní ìní, yíò kígbe, bẹ̃ni, àní láti inú erùpẹ̀ wá ni wọn yíò kígbe pè Olúwa; bí Olúwa sì ti wà lãyè oun yíò rántí májẹ̀mú èyítí ó ti dá pẹ̀lú wọn.
24 Ó sì mọ àdúrà wọn, pé fún ànfàní àwọn arákùnrin wọn ni. Ó sì mọ ìgbàgbọ́ wọn, nítorípé ní orúkọ rẹ̀ ní wọ́n lè ṣí àwọn òkè nlá ní ìdí; àti ni orúkọ rẹ̀ ní wọ́n lè mú kí ayé kí ó mì; àti nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní wọn mú kí àwọn tũbú wó lulẹ̀; bẹ̃ni, àní àwọn iná ìléru kò lè pa wọ́n lára, tàbí àwọn ẹranko búburú tàbí àwọn ejò olóró, nítorí agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀.
25 Kí ẹ sì kíyèsĩ, adura wọn wà fún ànfàní ẹnití Olúwa yíò jẹ́ kí ó mú àwọn ohun wọ̀nyí jáde wá.
26 Kí ẹnikẹni ó má sì sọ pé wọn kò ní wá, nítorí dájúdájú wọn yíò wá, nítorípé Olúwa ti wíi; nítorítí wọn yíò jáde wá láti inú erùpẹ̀, nipa ọwọ́ Olúwa, kò sì sí ẹniti ó lè dá a dúró; yíò sì wá ní ọjọ́ nã nígbàtí wọn yíò wípé iṣẹ́ ìyanu kò sí mọ́; yíò sì wá àní bí ẹnití nsọ̀rọ̀ láti inú ipò-òkú.
27 Yíò sì wá ní ọjọ́ nã nígbàtí ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ yíò kígbe pe Olúwa, nitori àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àti àwọn iṣẹ ìkọ̀kọ̀.
28 Bẹ̃ni, yíò wá ní ojọ́ nã nígbàtí àwọn ènìyàn yíò sẹ́ agbara Ọlọ́run ti àwọn ìjọ onígbàgbọ́ yíò di àìmọ́, tí wọn yíò sì gbé ara wọn sókè nínú ìgbéraga ọkan wọn; bẹ̃ni, àní ni ọjọ́ nã nígbàtí àwọn oludari àwọn ijọ onígbàgbọ́ àti àwọn olùkọ́ni yíò gbe ara wọn sókè nínú ìgbéraga ọkàn wọn, àní títí wọ́n fi jẹ́ ohun ìlara sí àwọn tí ó wà nínú àwọn ìjọ onígbàgbọ́ wọn.
29 Bẹ̃ni, yíò wá ní ọjọ́ nã nígbàtí a ó mã gbọ́ nípa àwọn ìsẹ̀lẹ̀ iná, àti èfũfùlíle, àti ìkùukùu ẽfin láti inú àwọn ìlẹ̀ òkẽrè wá.
30 A ó sì tún gbọ́ pẹ̀lú nípa àwọn ogun, ìdágìrì ogun, àti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ní onírúurú ibi.
31 Bẹ̃ni, yíò wá ní ọjọ́ nã nígbàtí àwọn ìbàjẹ́ èyítí ó pọ̀ yíò wà lórí ilẹ̀ ayé; ìpànìyàn yíò wà, àti olè jíjà, àti irọ́ pípa, àti ẹ̀tan, àti ìwà àgbèrè, àti onírúurú ìwà ìríra; nígbàtí púpọ̀ ènìyàn yíò wipe: Ṣe tibí, tabi ṣe tọ̀hún, àti pe kò já mọ́ ohun kan, nítorípé Olúwa yíò gbe irú àwọn ẹni bẹ̃ dúró ní ọjọ ìkẹhìn. Ṣugbọ́n ègbé ni fún irú àwọn ẹni bẹ̃, nítorípé wọn wà nínú ìkorò òrõro àti ìdè àìṣedẽdé.
32 Bẹ̃ni, yíò ṣe ní ọjọ́ nã nígbàtí a ó kọ́ àwọn ìjọ onígbàgbọ́ tí wọn yíò mã wípé: Wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti fún owó rẹ, a ó dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.
33 A! ẹ̀yin oníwà búburú àti alárèkérekè àti ọlọ́rùnlíle ènìyàn, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi kọ ijọ onigbagbọ́ jọ fún ara yin láti jẹ èrè? Kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin yí ọ̀rọ̀ mímọ́ ti Ọlọ́run padà, kí ẹ̀yin ó lè mú ègbé wá sí órí ọkàn yin? Ẹ kíyèsĩ, ẹ wò inú àwọn ìfihàn Ọlọ́run; nítorí ẹ́ kíyèsĩ, àkókò dé tán ní ojọ nã nígbàtí gbogbo àwọn ohun wọnyĩ gbọdọ̀ di mímúṣẹ.
34 Ẹ kíyèsĩ, Olúwa ti fi àwọn ohun nla tí ó yanilẹ́nu hàn mí nípa eyĩnì tí ó gbọ́dọ̀ dé ní àìpẹ́, ní ọjọ nã nígbàtí àwọn ohun wọnyĩ yíò jáde wa ní ãrín yín.
35 Ẹ kíyèsĩ, mo nbá yín sọ̀rọ̀ bí ẹnipé ẹ̀yin wà níhìn yĩ, síbẹ̀ ẹ̀yin kò sì níhìn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Jésù Krístì ti fi yín hàn sí mi, èmi sì mọ́ àwọn ìṣe yín.
36 Emí sì mọ̀ pé ẹ̀yin nrìn nínú ìgbéraga ọkàn yín; àti pe kò sì sí nínú yin, afi díẹ̀ tí kò gbé ara wọn sókè nínú ìgbéraga ọkàn wọn, sí wíwọ̀ ẹ̀wù olówó iyebíye, ṣí ṣíṣe ìlara, àti ìjà, àti àrankàn, àti inúnibíni, àti onírúurú ìwà àìṣedẽdé; tí àwọn ijọ onígbàgbọ́ yin, bẹ̃ni, àní gbogbo wọn, ní ó ti díbàjẹ́ nítorí ìgbéraga ọkàn yín.
37 Nítorí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin fẹ́ràn owó, àti ohun ìní yín, àti àwọn ẹ̀wù olowo iyebíye yín, àti ṣíṣe àwọn ijọ yín lọ̀ṣọ́, jù bí ẹ̀yin ti fẹ́ràn àwọn òtòsi àti àwọn aláìní, àwọn aláìsàn àti àwọn ti á pọn lójú.
38 A! ẹyin oníbàjẹ́, ẹyin àgàbàgebè, ẹyin olùkọ́ni, tí ẹ ntà ara yín fun èyítí yíò díbàjẹ, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin ṣe bá ìjọ mímọ́ Ọlọ́run jẹ́? Kíni ojú ṣe ntì yín láti gbà orúkọ Krístì sínú yin? Ẹyin kò ṣe rò ó pé iye tí ó wà lórí ayọ̀ àìnípẹ̀kun jù ti òṣì tí kì í kú—nítorí ìyìn ti inú ayé yi?
39 Kíni ìdì rẹ̀ ti ẹ̀yin nṣe ara yín lọ́ṣọ pẹ̀lú èyítí kò ní ẹ̀mí, tí ẹyin sì njẹ́ kí ẹnití ebi npa, àti aláìní, àti ẹniti ó wà làìláṣọ lárá, àti alaisàn àti ẹniti a pọ́n lójú kí ó kọjá ní ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ kò sì nãní wọn?
40 Bẹ̃ni, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹyín nkó àwọn ohun irira yín ìkọ̀kọ̀ jọ fún èrè jíjẹ, tí ẹ sì nmú kí àwọn opó ṣọ̀fọ̀ níwájú Olúwa, àti pẹ̀lu kí àwọn ọmọ alainibaba ṣọ̀fọ̀ níwájú Olúwa, àti kí ẹ̀jẹ̀ àwọn bàbá wọn àti àwọn ọkọ wọn kígbe pe Olúwa láti inú ilẹ̀ wa, fún ìgbẹ̀san lórí yin?
41 Ẹ kíyèsĩ, idà ìgbẹ̀san nrọ̀dẹ̀dẹ̀ lórí yín; àti pé àkókò nã fẹ́rẹ̀ dé tí oun yíò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ lórí yín, nítorítí oun kì yíò jẹ́ kí wọn ó ké mọ.