2013
Jọ̀wọ́ Wo Ọkàn Mi Sàn
March 2013


Ọ̀dọ́

Jọ̀wọ́ Wo Ọkàn Mi Sàn

Ní àjọ̀dún ikú arákùnrin mi, mo ṣe àyẹ̀wò lórí àkókò mi láti ìgbà tí ó ti kú. Mo rántí kìí ṣe ìrora pátápáta tí mo ní nìkan ṣùgbọ́n bákannáà àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run fún mi.

Un kò ní òye láí bí àwọn ènìyàn ṣe lè sọ wípé ikú àyànfẹ́ kan lè mú àwọn ìbùkún wá. Kò yé mi bí mo ṣe lè ní ayọ̀ àti ìmoore fún ohun tí ó dùn mí jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Òru kan wà, bíótilẹ̀jẹ́pé, tí ìwojú mi yípada pátápátá.

Mo jí ní àárín òru pẹ̀lú ọkàn wíwúwo tí un kò ní rí. Ìrora náà ndí èmímí mi. Mo wólẹ̀ lórí eékún mi mo sì sun ẹkún àdúrà sí Bàbá Ọ̀run mi. Ní gbogbo ayé mi a ti kọ́ mi nípa Ètùtù náà àti agbára ìwòsàn ìyanu Jésù Krístì. Nísisìyí à á ndán ìgbàgbọ́ mi wò. Njẹ́ mo gbàgbọ́ gan? Mo bi Bàbá mi ní Ọ̀run kí ó wo ọkàn mi sàn. Ìrora náà ti pọ̀jù fún mi nìkan láti yanjú.

Nígbà náà ìmọ̀-inú àláfíà, ìtùnú, àti ìfẹ́ kan gba gbogbo ara mi kan. Mo ní ìmọ̀-inú bí ẹnipé Ọlọ́run lọ́ apá Rẹ̀ yí mi ká sìí dáàbò mi láti ọwọ́ ìrora kíkan tí mo ti ní. Mo ṣì ndárò arákùnrin mi, ṣùgbọ́n mo wá lè ríran pẹ̀lú àwọn ojú míràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan ló wà fún mi láti kọ́ láti ìrírí yìí.

Mo mọ̀ wípé ìfẹ́ àti àláfíà Olúwa wà ní àrọ́wọ́tó. A kàn ní láti jẹ́ alábápín.

Tẹ̀