Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2013
Mímú Ṣiṣẹ́
Fi àdúrà ṣàṣàrò lórí ohun yìí àti, bí ó bá bójú mu, ṣe àjọsọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arábìnrin tí ò ó mbẹ̀ wò. Lo àwọn ìbéèrè náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìfúnlókun àwọn arábìnrin rẹ àti láti mú Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ jẹ́ ipá tí ó láapọn nínú ayé rẹ. Fún ìmọ̀ síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Wòlíì wa, Ààre Thomas S. Monson, ti gbà wá níyànjú kí a “na wọ́ láti gba àwọn tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ wa sílẹ̀ àti gbé wọn sókè sí ọ̀nà gíga náà àti sí ọ̀nà dídára náà. … Ìṣẹ́ Olúwa ni, àti nígbà tí a bá wà lórí jíjíṣẹ́ Olúwa, … a ní ẹ̀tọ́ sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa.”1
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn LaVene Call àti ẹnìkejì abẹniwò kíkọ́ni rẹ̀ ṣe àbẹ̀wọ̀ obìnrin kan tí ó nṣòjòjò. Wọ́n kan ilẹ̀kùn wọ́n sì rí ọ̀dọ́ ìyábìnrin kan nínú aṣọ balùwẹ̀ rẹ̀. Ó rí bí aláàárẹ̀, ṣùgbọ́n láìpẹ́ wọ́n ṣàkíyèsi wípé wàhálà rẹ̀ ni otí líle. Àwọn abẹniwò kíkọ́ni náà jókó wọ́n sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ ìyábìnrin tí ó tiraka náà.
Lẹ́hìn tí wọ́n lọ̀, wọ́n wípé, “Ọmọ Ọlọ́run ni ón ṣe. A ní ojúṣe láti ràn án lọ́wọ́.” Nítorínáà wọ́n ṣe àbẹ̀wò rẹ̀ déédé. Ní olúkúlùkù ìgbà, wọ́n lè rí àti ní ìmọ̀-inú àyípadà fún rere kan. Wọ́n ní kí arábìnrin náà kí ó wá sí Ẹgbé Aranilọ́wọ́. Bí ó tilẹ̀ lọ́ra, ní ìparí ó nlọ déédé. Lẹ́hìn ìgbàníyànjú, òun àti ọkọ rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wá sí ìjọ. Ọkọ ní ìmọ̀-inú ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ó wípé, “Màá ṣe ohun tí bíṣọ́pù gbànímọ̀ràn.” Nísisìyí wọn ṣáapọn nínú Ìjọ wọ́n sì ti ṣe èdìdí nínú tẹ́mpìlí.2
Láti Àwọn ìwé Mímọ́
Láti Ìtàn Wa
Ríran àwọn tí ó ti ṣáko lọ láti padà sí ìhìnrere ti Jésù Krístì ti maá njẹ́ lára jíjẹ́ Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn àti ọmọ Ẹ̀gbẹ́ Aranilọ́wọ́. Ààrẹ Brigham Young (1801–77) wípé, “Ẹ jẹ́ kí a káánú lórí ara wa, … àti jé kí àwọn tí ó ríran darí afójú títí dìgbà tí wọ́n bá lè rí ọ̀nà fún ara wọn.”3
Eliza R. Snow, ààrẹ gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ kejì, fi ìmoore jẹ́wọ́ àwọn ipá àwọn arabìnrin ní Ogden, utah, USA, láti fún ara wọn lókun. “Mo mọ̀ dájúdájú pé a ti ṣe ìtọrẹ nlá [nípa iṣẹ́ sísìn] tí kìí dé [àkọsílẹ̀] àwọn ìwé láí,” ó wí Ṣùgbọ́n ṣíṣe ìdámọ̀ wípé a ṣe àkọsílẹ̀ ti ọ̀run kan fún iṣẹ́ àwọn arabìnrin bí wọ́n ṣe én nawọ́ sí àwọn tí àwọn ọkàn wọn ti tutù, ó wípé: “Ààrẹ Joseph Smith wípé a ṣe ìkójọ ẹgbẹ́ yí láti gba ọkàn là. … A ṣe ìtọ́jú ìwé míràn fún ìgbàgbọ́, àánú, iṣẹ́ rere yín, àti àwọn ọ̀rọ̀. … A kò sọ nkankan nù.”4
© Ọdún 2013 nípasẹ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/12. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/12. Àyípadà èdè ti Visiting Teaching Message, March 2013. Yoruba. 10663 779