Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2013
Àláfíà, Dúró Jẹ́
Ní ọjọ́ kan ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, lẹ́hìn tí mo yanjú àwọn nkan ní ibiṣẹ́ mi, mo ní ìmọ̀-inú ìmísí alágbára kan láti ṣe àbẹ̀wò ògbó opó kan tí ó jẹ́ aláìsàn ní ilé ìtọ́jú àwọn àgbàgbà kan ní Salt Lake City. Mo wa ọkọ̀ lọ síbẹ̀ tààrà.
Nígbà tí mo lọ sí iyàrá ẹ̀, mo ríi lófo. Mo bi onítọ́jú kan nípa ibi tí ó wà a sì darí mi sí agbègbè rọ̀gbọ̀kú kan. Níbẹ̀ ni mo rí opó aládùn yí tí ó nṣe àbẹ̀wò pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́ míràn. A ní àjasọpọ̀ ẹlẹ́wà kan papọ̀.
Bí a ṣe én sọ̀rọ̀, ọkùnrin kan wá sí ẹnu ọ̀nà iyàrá náà láti gba agolo ohun mímu aláìlọ́tí líle láti ìdí ẹ̀rọ ìtajà. Ó wò mí fírí ó sì wípé, “Kílódé, ìwọ ni Tom Monson.”
“Bẹ́ẹ̀ni,” mo fèsì. “Àní o sì rí bíi Hemingway kan.”
Ó jẹ́wọ́ pé òhun ní Stephen Hemingway, ọmọkùnrin Alfred Eugene Hemingway, tí ó ti sìn bíi olùdámọ̀ràn mi nígbà tí mo jẹ́ bíṣọ́pù ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn àti ẹni tí mo pè ní Gene. Stephen sọ fún mi wípé bàbá un wà níbẹ̀ ní ilé ìrọrùn kannáà ó sì súnmọ́ ikú. Gene tí ń npe orúkọ mi, àwọn ìdílé tí fẹ́ kàn sí mi ṣùgbọ́n wọn kò rí nọ́mbà ìpeni bá sọ̀rọ̀ kankan fún mi.
Mo yònda ara mi lọ́gan mo sì gòkè pẹ̀lú Stephen lọ sí iyàrá ti olùdámọ̀ràn mi tẹ́lẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ rẹ̀ míràn náà péjọ bákannáà, tí ìyàwó rẹ̀ sì ti kọjá lọ bíi ọdún méló kan ṣáájú. Àwọn ará ìdílé náà ka pípàdé Stephen mi ní agbègbè rọ̀gbọ̀kú kan sí ìfèsì nípa Bàbá Ọ̀run wa sí ìfẹ́ nlá wọn wípé kí in rí bàbá wọn kí ó tó kú àti kí un sì dáhùn ìpè rẹ̀. Èmi náà ní ìmọ̀-inú wípé èyí ni ipò náà, nítorí tí Stephen ò bá wọnú iyàrá yẹn nínú èyí tí mò ón ṣe àbẹ̀wò ní gbọ̀gán àkókò tí ó ṣe, È mi ò ni mọ̀ wípé Gene tilẹ̀ wà nínú ilé ìrọrùn yẹn.
A fún un ní ìbùkún kan. Ẹ̀mí àláfíà kan borí. A ní àbẹ̀wò ẹlẹ́wà kan, lẹ́hìn èyí tí mo kúrò.
Ní òwúrọ̀ tí ó tẹ̀le ìpè lórí aago kan fihàn wípé Gene ti kọjá lọ — bíi ogún ìṣẹ́jú lẹ́hìn tí ó gba ìbùkún kan láti ọwọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ àti èmi.
Mo sọ àdúrà ìdákẹ́jẹ́ ọpẹ́ kan sí Bàbá Ọ̀run fún ìpá ìdarí Rẹ̀, tí ó tọ́ bíbẹ́wò mi sí ilé ìtọ́jú náà tí ó sì darí mi sí ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n Alfred Eugene Hemingway.
Mo fẹ́ láti ronú wípé àwọn èrò Gene Hemingway ní àṣálẹ́ yẹn — bí a ṣe én yá nínú ìtànná ti Ẹ̀mí, ṣe alábápín nínú àdúrà ìrẹ̀lẹ̀, sí sọ ìbùkún ti oyè àlùfáà kan — ṣe àtúnsọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú orin ẹ̀mí “Master, the Tempest Is Raging”:
Dúró, Áà Olùràpadà Ìbùkùn!
Má ṣe fimí sílẹ̀ mọ́,
Àtí pẹ̀lú ayọ̀ un ó gúnlẹ̀ sí èbúté ọkọ̀ alábùkún
Sì simi lórí etí òkun tí ó kún fún àláfíà pípé.
Mo yì fẹ́ràn orin ẹ̀mí yẹn mo sì jẹ́rí sí ìtùnú tí ó pèsè.
Bó yẹ́ ìbínú ti ìjì-omi òkun
Tàbí àwọn iwin tàbí ènìyàn tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́
Kò sí àwọn omi tí ó lè gbé ọkọ̀-omi tí a sùn sí
Olúwa ti òkun àti ayé àti àwọn ọ̀run.
Gbogbo wọn yíó ní dídùn gbọ́ràn sí àṣẹ rẹ̀:
Àláfíà, dúró jẹ́.1
Nínú àwọn ẹkún àti àwọn àdánwò, nínú àwọn ìjayà àti àwọn ìkorò, nínú ẹ̀dùn ọkàn àti dídáwà ti sísọ àwọn àyànfẹ́ sọnú, ìdánilójú wà wípé ayé wà títí ayérayé. Olúwa àti Olùgbàlà wa ni ẹ̀rí alàyè wípé èyí jẹ́ bẹ́ẹ̀.2 Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ mímó ti tó: “Ẹ dúró jẹ́, kí ẹ sì mọ̀ wípé èmi ni Ọlọ́run” Orin Dáfídì 46:10 Mo jẹ́rí sí òtítọ́ yìí
© Ọdún 2013 nípasẹ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/12. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/12. Àyípadà èdè ti First Presidency Message, March 2013. Yoruba. 10663 779