2013
Wá Sọ́dọ̀ Mi
May 2013


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kárún Ọdún 2013

“Wá Sọ́dọ̀ Mi”

Nípasẹ àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti àpẹrẹ Rẹ̀, Krístì ti fi bí a ṣe lè súnmọ́ Òhun hàn wá.

Mo ní ìmoore láti wà pẹ̀lú yin nínú ìpàdé àpapọ̀ ti Ìjọ ti Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. A gba orúkọ Rẹ̀ lé ara wa nígbà tí a bá wọ ìjọba Rẹ̀. Òhun ni Ọlọ́run, Ẹlẹ́dá, àti pípé. A jẹ́ alára ìdíbàjẹ́ ti ikú àti ẹ̀ṣẹ̀ nípá lórí. Síbẹ̀ nínú ìfẹ́ Rẹ̀ fún àwa àti ìdílé wa, Ó pè wá láti súnmọ́ Òhun. Níbí ni àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀: “Sún mọ́ mi àti Èmi yíó sì sún mọ́ Ọ; wá mi lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ àti ìwọ yíó sì rí me; bèrè, àti ìwọ yíó rí gbà; kàn, àti pé a ó ṣí fún ọ.”1

Ní àkókò Easter yíí a ní ìrántí nípa ìdí tí a fi fẹ́ràn Rẹ̀ àti ti àwọn ìlérí tí ó ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ olóótọ́ láti di àwọn ọ̀rẹ́ àyànfẹ́ Rẹ̀. Olùgbàlà ṣe ìlérí yẹn àti pé Ó sọ fún wa bí, nínú iṣẹ́-ìsìn wa sí I, Òhun ṣe wá sí wa. Àpẹrẹ kan wà nínu ìfihàn sí Oliver Cowdery bí ó ti ń sin Olúwa pẹ̀lú Wòlíì Joseph Smith nínú àyípadà èdè ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì: “Kíyèsíi, ìwọ ni Oliver, àti pé mo ti sọ fún ọ nítorí àwọn ìfẹ́-inú rẹ; nítorínáà ṣe ìtọ́jú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bíi ìtura nínú ọkàn rẹ. Jẹ́ olóótọ́ àti alápọn ní pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, àti pé Èmí yíó rọ̀gbà yí ọ ká nínú àwọn apa ìfẹ́ mi.”2

Mo ní ìrírí ti ayọ̀ ti wíwá sún mọ́ Olùgbàlà áti ti wíwá Rẹ̀ sún mọ́ mi ní ìgbàkúgbà nípa àwọn ìṣe ìrọrùn ti ìgbọràn sí àwọn àṣẹ.

O ti ní ìru àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀. Ó ti lè jẹ́ nígbà tí o yàn láti péjọ fún ìpàdé oúnjẹ Olúwa kan. Ó jẹ́ fún mi ní Ọjọ́ Ìsinmi kan nígba tí èyí kéré gan. Ní àwọn ọjọ́ yẹn a gba oúnjẹ Olúwa nínú ìpàdé ìrọ̀lẹ́ kan. Ìrantí ti ọjọ́ kan tí ó ju ọdún márùndínláádọ́rin, nígbà tí mo pa àṣẹ láti kó àwọn ìdílé jọ pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ mọ́, yì í n fà mí sún mọ́ Olùgbàlà.

Ìta ṣókùnkùn ó sì tutù. Mo rántí níní ìmọ̀-inú ti ìmọ́lẹ̀ àti lílọ́ nínú ìlé ìsìn ní ìrọ̀lẹ́ yẹn pẹ̀lú àwọn òbí mi. A ṣalábápín nínú oúnjẹ Olúwa, tí a pín nípa àwọn tí ó di Oyè Àlúfáà ti Áárọ́nù mú, ní dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run wa láti máa rántí Ọmọ Rẹ̀ nígbà gbogbo àti pa àwọn àṣẹ Rẹ̀ mọ́.

Ní ìparí ìpàdé náà, a kọ orin ẹ̀mí “Abide with Me, ’Tis Eventide,” pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ nínú rẹ̀ “A Olùgbàlà, dúró lálẹ́ yí pẹ̀lú mi.”3

Mo ní ìmọ̀-inú ti ìfẹ́ àti sísúnmọ́ ti Olùgbàlà lálẹ́ yẹn. Àti pé mo ní ìmọ̀-inú ti ìtùnnú ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Mo fẹ́ láti tún tàn lẹ́ẹ́kan si àwọn ìmọ̀-inú ti ìfẹ́ àti sísúnmọ́ Olùgbàlà tí mo ní nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa yẹn nígbà ọ̀dọ́ mi. Ní láìpẹ́ yìí mo pa àṣẹ míràn mọ́. Mo ṣàwárí nínú àwọn ìwé mímọ́. Nínú wọn, mo mọ̀ pé mo tún lè padà láti jẹ́ kí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ki ní ìmọ̀-inú tí àwọn ọmọ ẹ̀hìn méjì ti Olúwa Àjíìnde ti ní nígbà tí Ó gba ìpè láti wá sínú ilé wọn àti láti wà pẹ̀lú wọn.

Mo kà nípa ọjọ́ kẹta lẹ́hìn Ìkànmọ́-àgbélèbú àti ìsìnkú Rẹ̀. Àwọn arábìrin olóótọ́ àti àwọn míràn ri tí a ti yí òkúta kúrò nínú túbú wọ́n sì rí wípé ara Rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́. Wọ́n jáde wá nítorí ìfẹ́ Fun láti kun ara Rẹ̀ ní òróró.

Àwọn àngẹ́lì méjì dúró ní tòsí wọ́n sì bèrè ìdí tí wọ́n fi ń bẹ̀rù, wípé:

“È é ṣe tí ẹ̀nyín fi ń wá alààyè láárín àwọn òkú?

“Kò sí níhín, ṣùgbọ́n ó jíìnde: rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Gálílì,

“Wípé, A kò lè ṣaláìmá fi Ọmọ-ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, àti pé a ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, àti pé ní ijọ́ kẹ́ta yíó tún dìde.”4

Ìhìnrere ti Márkù ṣe àfikún ìtọ́sọ́nà náà láti ọwọ́ ìkan nínú àwọn ángẹ́lì náà: “Ṣùgbọ́n ẹ lọ, sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn rè àti Pétérù wípé ó ṣáájú yín lọ sí Gálílì: níbẹ̀ ní ẹ̀nyin yíó gbé ríi, gẹ́gẹ́bí ó ti wí fún un yín.”5

Àwọn Àpóstélì àti àwọn ọmọ ẹ̀hìn péjọ pọ̀ ní Jérúsálẹ́mù. Gẹ́gẹ́bí àwa náà ṣe lè wà, ẹ̀rù ń bà wọ́n àti pé wọ́n ní ìyanu bí wọ́n ṣe é nsọ̀rọ̀ papọ̀ nípa oun tí ìkú àti àwọn ìròhìn nípa jí jíìnde Rẹ̀ jẹ́ fún wọn.

Mẹ́jì nínú àwọn ọmọ ẹ̀hin náà rìn lọ́sán yẹn láti Jérúsálẹ́mù lórí ọ̀nà sí Ẹ́mmáúsì. Krístì tí a jíìnde yọ ní ọ̀nà náà ó sì rìn pẹ̀lú wọn. Olúwa ti wá sọ́dọ̀ wọn.

Ìwé ti Lúkù gbà wá láyè láti rìn pẹ̀lú wọn:

“Ó sì ṣe, wípé, nígbàtí wọ́n jùmọ̀ sọ̀rọ papọ̀ àti sọ àsoyé, Jésù fún ara rẹ̀ súnmọ́ tòsí, àti pé ó lọ pẹ̀lú wọn.

“Ṣùgbọ́n a dì wọ́n lójú kí wọ́n má ba da mọ́.

“Àti pé ó sì bi wọ́n pé, Ìrú àjọsọ papọ̀ wo ní èyí tí ẹ̀ ẹ́ nní ẹnìkan sí ìkejì, bí ẹ tí nrìn, àti tí ẹ banújẹ́?

“Ọ̀kan nínú wọn, tí orúkọ re njẹ́ Klẹ́ópà, ní ìdáhùn wí fún un, Njẹ́ àlejo níkan ní ìwọ ní Jérúsálẹ́mù, àti tí ìwọ ò sì mọ ohun tí ó ṣe níbẹ̀ ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí?”6

Wọ́n sọ Fun nípa ìbànújẹ́ wọn wípé Jésù ti kú nígbà tí wọ́n gbẹ́kẹ̀le pé yí Ó jẹ́ Olùràpadà Ìsráẹ́lì.

Ìnífẹ́sí láti ti wà nínú ohùn Olúwa Àjíìnde bí ó ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀hìn méjì oníròbìnújẹ́ àti tí nkẹ́dùn:

“Nígbànáà ó wí fún wọn, ẹ̀nyin tí òye kò yé, àti tí ó yigbì ní ọkàn láti gba gbogbo èyítí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:

“Kò há à yẹ kí Krístì kí ó jìyà nkan wọ̀nyí, àti kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀?

“Àti bẹ̀rẹ̀ láti Mósè àti gbogbo àwọn wòlíì, ó sàsoyé àwọn nkan nípa rẹ̀ nínú gbogbo ìwé mímọ́ fún wọn.7

Nígbànáà àkókò kan dé tí ó ti mú ọkàn mi lọ́ wọ́ọ́rọ́ láti ìgbà tí mo ti jẹ́ ọmọkùnrin kékeré:

“Àti pé wọ́n súnmọ́ sí ìletò, níbi tí wọ́n nlọ, àti ó sì ṣe bí ẹnipé yíó lọ́ sí ìwajú.

“Ṣùgbọ́n wọ́n rọ̀ ọ́, wípé, Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, àti pé ọjọ́ sì kọjá tán. “Àti pé ó sì wọlé lọ láti bá wọn dúró.”8

Olùgbàlà gbà, ní alẹ́ yẹn, ìpè láti wọ ilé àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ nítòsí ìletò Ẹ́mmáúsì.

Ó jókó ti oúnjẹ pẹ̀lú wọn. Ó mú búrẹ́dì, súre sí i, bù ú, àti pé ó fifún wọn. A ṣí ojú wọn tó jẹ́ pé wọ́n dáa mọ̀. Nígbànáà Ó di òfo mọ́ wọn lójú. Luku ṣe àkọsílẹ̀ fún wa àwọn ìmọ̀-inú ti àwọn ọmọ ẹ̀hìn alábùkún nì: “Àti pé wọ́n sì wí fún ara wọn, ọkàn wa kò há à gbiná nínú wa, nígbàtí ó mbá wa sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà, àti nígbàtí ó ntúmọ̀ àwọn ìwé mímọ́ fún wa?”9

Ní wákàtí kan náà, àwọn ọmọ ẹ̀hìn méjì náà sáré tete padà sí Jerúsálẹ́hù láti sọ fún àwọn Àpóstélì mọ́kànlá ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ní àkókò yẹn gan, Olùgbàlà tún yọ sí wọn.

Ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bàbá Rẹ̀ àti láti já àwọn ìdè ikú.

“Àti ó wí fún wọn pé, Bẹ́ẹ̀ni a ti kọ̀wé rẹ̀, àti pé kí Krístì kí ó jìyà, àti kí ó sì jíìnde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú:

“Àti kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ láárín orílẹ̀ ède gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù.

“Àti ẹ̀nyìn ni ẹlẹ́rí nkan wọ́nyí.”10

Àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà jẹ́ òtítọ́ bákanná fún wa bí wọ́n ṣe wà fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ nígbà yẹn. A jẹ́ ẹ̀lẹ́rí àwọnnkan wọ̀nyí. Àti ojúṣe ológo tí a gbà nígbàtí a ṣe ìrìbọmi wọ́ inú Ìjọ ti Jésù Jrístì tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn di kedere fún wa nípasẹ wòlíì Alma ní ọgọgọ́rún ọdún sẹ́hìn ní àwọn ọmi Mọ́mọ́nì:

“Ó sì ṣe, tí ó wí fún nwọn pé: kíyèsí i, àwọn wọ̀nyí ni omi Mọ́mọ́nì (nítorípé báyí ní à npè nwọn) àti nísisìyí, bí ẹ̀yin ti ṣe ní ìfẹ́ láti wá sínú agbo Ọlọ́run, kí a sì pè nyín ní ènìyàn rẹ̀, tí ẹ sì ṣetán láti fi ara da ìnira ara nyín, kí wọ́n lè fúyẹ́;

“Bẹ́ẹ̀ni, tí ẹ̀yin sì ṣetán láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀; bẹ́ẹ̀ni, àti láti tu àwọn tí ó fẹ́ ìtùnú nínú, àti láti dúró gẹ́gẹ́bí àwọn ẹlẹ́rí Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti níbi gbogbo tí ẹ̀yin lè wà, àní títí dé ojú ikú, kí a lè rà yín padà nípasẹ Ọlọ́run, kí a sì kà yín mọ́ ara àwọn tí ọ́ ní àjíìnde èkíní, kí ẹ̀yin kí ó lẹ̀ ní iyè àìnípẹ̀kun—

“Nísisiyí mo wí fún nyín, tí èyí bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn nyín, kíni ẹ̀yin ní tí ó jẹ́ ìdènà sí kí a rì nyín bọmi ní orúkọ Olúwa, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí níwájú rẹ̀ wípé ẹ̀yin ti bá a dá májẹ̀mú, pé ẹ̀yin yíò máà sìn in, ẹ̀yin yíò sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí Òun kí ó lè da Ẹ̀mí rẹ̀ lé nyín lórí lọ́pọ̀lọpọ̀?

“Àti nísisìyí, nígbàtí àwọn ènìyàn náà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nwọ́n pàtéwọ́ fún ayọ̀, nwọ́n sì kígbe sókè: Ẹ̀yí ni ìfẹ́ ọkàn wa.”11

A wà lábẹ́ májẹ̀mú lọ́nà méjì láti gbé àwọn aláìní sóké àti láti jẹ́ àwọn ẹlẹ́rí ti Olùgbàlà níwọ̀n igbà tí a wà láyé.

À á lè ṣe é láì kùnà níkan tí a bá ní ìmọ̀-inú ìfẹ́ fún Olùgbàlà àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa. Bí a bá ṣe ṣòótọ́ sí àwọn ìlérí ti a ti ṣe, a ó ní ìmọ̀-inú ti ìfẹ́ wa fún Un. Èyí yíó pọ̀ si nítorí a ó ní ìmọ̀-inú ti agbára Rẹ̀ àti sísúnmọ́ Rẹ̀ sí wa nínú ìṣẹ́-ìsìn wa sí I.

Ààrẹ Thomas S. Monson ti rán wa létí lóòrèkóòrè ti ìlérí ti Olúwa sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn olóótọ́ Rẹ̀: “Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà yín, níbẹ̀ ní Èmí yíó wà bákannáà, nítorí Èmí yíó lọ ṣíwájú ojú yín. “Èmi yíó wà ní ọwọ́ ọ̀tún yín àti ní ọwọ́ òsì, àti Ẹ̀mí mi yíó wà nínú àwọn ọkàn yín, àti àwọn ángẹ́lì mi rọ̀gbà yí i yín ká, láti gbé e yín sókè.”12

Ọ̀nà míràn kan wà tí èmi àti ìrẹ ti ní ìmọ̀-inú sísúnmọ́ Rẹ̀ sí wa. Bí a ṣe é fún Un ní ìsìn tọkàntọkàn, Yíó súnmọ́ àwọn tí a fẹ́ràn nínú ìdílé wa. Ní gbogbo ìgbà tí a ti pè mí nínú ìsìn Olúwa láti ṣí tàbí láti fi ìdílé mi sílẹ̀, mo ti wá ri pé Olúwa nbùkún ìyàwó àti àwọn ọmọ mi. Ó pèsè àwọn ìrànṣẹ́ Olólùfẹ́ ti Rẹ̀ àti àwọn ànfàní láti fa ìdílé mi súnmó Òhun.

Ẹ ti ní ìmọ̀-inú irú ìbùkùn bẹ́ ẹ̀ nínú ayé yín. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín ni ó ní àwọn àyànfé tí wọ́n nṣáko kúrò lọ́na iyè àìnípẹ̀kun. Ẹ má nronú ohun tí ẹ lè tún ṣe láti mú wọn padà. Ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé Olúwa láti súnmọ́ wọn bí ẹ ṣe nsìn Í nínú ìgbàgbọ́.

Ẹ rántí ìlérí Olúwa sí Joseph Smith àti Sidney Rigdon nígbà tí wọ́n kò sí lọ́dọ̀ àwọn ìdílé wọn torí ìṣẹ́ Rẹ̀: “Ẹ̀ yin ọ̀rẹ́ mi Sidney àti Josefu, àwọn ìdílé yín wà ní dáradára, wọ́n wà ní ọwọ́ mi, àti pé Èmi yíó ṣe pẹ̀lú wọn bí ó ṣe tọ́ sí mi; nítorí nínú mi ni gbogbo agbára wà.”13

Bí i Alma àti Ọba Mòsíà, àwọn òbí olóótọ́ kan ti sin Olúwa pẹ́ àti ní dáradára síbẹ̀ wọ́n ní àwọn ọmọ tí wọ́n ti ṣáko bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn òbí wọn ti rúbọ fún Olúwa. Wọ́n ti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láì yege, àní pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àyànfẹ́ àti olóótọ́.

Almá àti àwọn ènìyàn mímọ́ ìgbà rẹ̀ gbàdúrà fún ọmọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ Ọba Mòsíà. Ángẹ́lì kan wá. Àdúrà yín àti àdúrà àwọn tí ó sa ìgbàgbọ́ wọn yíó mú àwọn ìránṣẹ́ Olúwa wá láti ran àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìdílé yín lọ́wọ́. Wọ́n yíó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan ọ̀nà ilé lọ́ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àní bí Sàtánì àti àwọn atẹ̀lé re bá dojú ìjà kọ wọ́n, ẹnití èrò rẹ̀ ní láti rún àwọn ìdílé nínú ayé yí àti nínú ayérayé.

Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí ángẹ́lì náà sọ sí Alma Kékeré àti àwọn ọmọkùnrín ti Mòsíà nínú ìwarùnkì wọn: “Àti pẹ̀lú, ángẹ́lì náà sọ wípé: Kíyèsí i, Olúwa ti gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn rẹ̀, àti àdúrà ìránṣẹ́ rẹ̀, Álmà, ẹnití ì ṣẹ bàbá rẹ; nítorítí ó ti gbàdúrà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́ nípa rẹ, pé kí a mú ọ wá sínú ìmọ̀ òtítọ́ nnì; nítorínáà, nítorí ìdí èyí ní èmí wá láti lè fún ọ ní ìdánilọ́jú nípa agbára àti àṣẹ Ọlọ́run, kí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ̀ jẹ́ gbígbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn.”14

Ìlérí mi sí ènyin tí ó ngbàdúra tí ẹ sì í nsin Olúwa kò lé è jẹ́ pé kí ẹ ní gbogbo ìbùkún tí ẹ̀ ẹ́ nfẹ́ fún ara yín àti ìdílé yín. Ṣùgbọ́n mo lè ṣèlérí fún un yín pé Olúgbàlà yíó súnmọ́ yín yíó sì bùkún yín àti ìdílé yín pẹ̀lú ohun tí ó dára jùlọ. Ẹ ó ní ìtùnú ti ìfẹ́ Rẹ̀ àti pé ẹ ó ní ìmọ̀-inú ti ìdáhùn ti sísúnmọ́ Rẹ̀ bí ẹ ṣe n na apá yín síta láti ṣe ìsìn fún àwọn ẹlòmíràn. Bí ẹ ṣé di egbò àwọn tí ó wà ní àìní àti pèsè ìwẹ̀nùmọ́ ti Ètùtù Rẹ̀ fún àwọn tí ó nkẹ́dùn nínú ẹ̀ṣẹ̀, agbára Olúwa yíó mú yín dúró. Àwọn apá Rẹ̀ wà ní níná sítà pẹ̀lú ti yín láti tìlẹ́hìn àti láti bùkún àwọn ọmọ ti Bàbá Ọ̀run wa, pẹ̀lú àwọn tí ó wà nínú ìdílé yín.

Ìpadàsílé ológo wà ní ìpèsèsílẹ̀ fún wa. Nígbà náà a ó rí ìmúṣẹ ilérí ti Olúwa tí a ti fẹ́ràn. Òhun ní yíó kí wa káàbọ̀ sí iyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀ àti Bàbá Ọ̀run wa. Jésù Krístì ṣà pé júwe rẹ̀ ní ọ̀nà yí:

“Wá láti ṣe àmúwá àti gbígbé kalẹ̀ Síónì mi. Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ nínú ohun gbogbo

“Àti pé, tí ó bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́ àti pé tí ó forítì dé òpin, ìwọ yíó ní iyè ayérayé, ẹ̀bùn èyí tí ó tóbi jù nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.”15

“Nítorí àwọn tí ó yè yíó jogún ayé, àti àwọn tí ó kú yíó simi láti gbogbo làálàá wọn, àti àwọn iṣẹ́ wọn yíó tẹ̀lé wọn; àti wọn yíó gba àdé nínú àwọn ilé Bàbá mi, èyí tí mo ti pèsè fún wọn.”16

Mo jẹ́rí pé a lè, nípasẹ Ẹ̀mí náà, tẹ̀lé ìpè ti Bàbá Ọ̀run: “Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Ọ!”17

Nípasẹ àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti àpẹrẹ Rẹ̀, Krístì tí fi hàn wá bí a ṣe lè súnmọ́ Òhun. Olúkúlùkù ọmọ Bàbá Ọ̀run tí ó ti yàn láti wòlé nípa ẹ̀nù ọ̀nà ti ìrìbọmi sínú Ìjọ Rẹ̀ yíó ní ànfàní nínú ayé yí láti gba ẹ̀kọ́ ìhìnrere Rè àti láti gbọ́ ìpè Rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí a pè, “Wá sọ́dọ̀ mi.”18

Olúkùlùkù ìránṣẹ́ oní májẹ̀mú Rẹ̀ nínú ìjọba Rẹ̀ lórí ayé àti nínú ayé ti ẹ̀mí yíó gba ìtọ́sọ́nà nípa Ẹ̀mí láti bùkún àti láti sín àwọn ẹlòmíràn fún Un. Àti wọn yíó ní ìmọ̀-inú ti ìfẹ́ Rẹ̀ àti rí ayọ̀ ti dídi fífà súnmọ́ Rẹ̀.

Mo jẹ́ ẹlẹ́rí ti Àjíìnde ti Olúwa dájúdájú bí ẹnipé mo wa níbẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ yẹn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹhìn méjì nínú ilé náà ní ọ̀nà Ẹmmausì. Mo mọ̀ pé Ó wà láyé dájúdájú bí Josefu Smith ṣe mọ̀ nígbà tí ó rí Bàbá àti Ọmọ nínú ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ dídán kan nínú igbó kékeré ti igi kan ní Palmyra.

Èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì tòtítọ́. Àfi nínú àwọn kọ́kọ́rọ́ ti Ààrẹ Thomas S. Monson dìmú ní agbára fún wa láti ṣe èdìdì pẹ̀lú àwọn ìdílé wa láti gbé títí ayérayé pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run wa àti Jésù Krístì Olúwa. A ó dúró ní Ọ̀jọ́ Ìdájọ́ níwájú Olùgbàlà, ojú kan ojú. Yí ó jẹ́ àkókò ayọ̀ fún àwọn tí ó ti súnmọ́ Rẹ̀ nínu ìsìn wọn fún Un nínú ayé yí. Yí ó jẹ́ ayọ̀ láti gbọ́ àwọn òrọ̀: “Káàre dáradára, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóótọ́.”19 Mo jẹ́rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́bí i ẹlẹ́rí ti Olùgbàlà Àjíìnde àti Olúràpadà wa ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.