2013
Àwọn Ìkọni fún Ìgbà Wa
May 2013


Àwọn Ìkọni fún Ìgbà Wa

A ó ya àwọn ẹ̀kọ́ tí Oyè Àlùfáà ti Mẹlkisẹ́dẹ́kì àti ti Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ tí Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kẹ́rin fún “Àwọn Ìkọni fún Ìgbà Wa.” A lè pèsè ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan láti àwọn ọ̀rọ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí a sọ nínú ìpàdé gbogbogbòò tí ó súnmọ́ jùlọ (rí àwòrán tí ó wà nísàlẹ̀). Àwọn ààrẹ èèkàn àti agbègbè lẹ̀ yàn àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí a lò, tàbí kí wọ́n fi ojúṣe yẹn lé àwọn bíṣọ́pù àti àwọn ààrẹ ẹ̀ka lọ́wọ́. Àwọn aṣíwájú ń ṣàtẹnumọ́ iyì ti kí àwọn arákùnrin ti Oyè Àlùfáà ti Mẹlkisẹ́dẹ́kì àti àwọn arábìnrin ti Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ máa ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ kannáà ní àwọn Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kannáà.

Àá ń gba àwọn tí wọ́n npéjọ fún àwọn ẹ̀kọ́ ti Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀-kẹ́rin láti ṣàṣàrò àti láti mú ẹ̀yà ti ìwé ìròhìn ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò tí ó súnmọ́ jù wá sí kílásì.

Àwọn Àbá fún Mímúra fún Ẹ̀kọ́ kan láti Àwọn Ọ̀rọ̀

Gbàdúrà kí Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹ̀lú rẹ̀ bí ó ṣé nṣàṣàrò tí o sì nkọ́ni ní ọ̀rọ̀ (tàbí àwọn ọ̀rọ̀) náà. O lè ní àdánwò láti múra fún ẹ̀kọ́ náà nípa lílo àwọn èlò míràn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ ni ìlànà kíkọ́ni lẹ́kọ́ ti a fàṣẹ sí. Ojúṣe rẹ ni láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ́ àti láti gbé ìgbé ayé ti ìhìnrere tí a kọ́ni nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò ti Ìjọ tí ó súnmọ́ jùlọ.

Se àtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ (tàbí àwọ̀n ọ̀rọ̀) náà, ní wíwá àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ tí ó bá àìní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kílásì mu. Bákannáà wá àwọn ìtàn, àwọn atọ́ka tí ìwé mímọ́, àti àwọn ọ̀rọ̀ ti a là sílẹ̀ láti ọ̀rọ̀ (tàbí àwọn ọ̀rọ̀) tí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn òtítọ́ yìí.

Ṣe àkọsílẹ̀ ètò bí o ó ṣe kọ́ àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ náà. Ronú nípa ṣíṣe àfikún àwọn ìbéèrè tí yíó ran àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kílásì lọ́wọ́.

  • Ṣe àwárí àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ nínú ọ̀rọ̀ (tàbí àwọn ọ̀rọ̀) náà.

  • Ronú nípa ìtunmọ̀ wọn.

  • Ṣalábápín òye, àwọn iyè inú, àwọn ìrírí, àti àwọn ẹ̀rí.

  • Lo àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí nínú ayé wọn.

Àwọn Oṣù tí à á ń kọ́ Àwọn Ẹ̀kọ́

Àwọn Èlò Ẹ̀kọ́ ti Ọ̀sẹ̀- Kẹ́rin

Oṣù Kẹ́rin Ọdún 2013–Oṣù Kẹ́wá Ọdún 2013

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ ní ìpàdé gbogbogbòò ti Oṣù Kẹ́rin Ọdún 2013*

Oṣù Kẹ́wá Ọdún 2013–Oṣù Kẹ́rin Ọdún 2014

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ ní ìpàdé gbogbogbòò ti Oṣù Kẹ́wá Ọdún 2013*

  • Fún àwọn ẹ̀kọ́ ti Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀-kẹ́rin ti Oṣù Kẹ́rin àti Oṣù Kẹ́wá, a lè yan ọ̀rọ̀ (tàbí àwọn ọ̀rọ̀) láti ìpàdé gbogbogbòò ti tẹ́lẹ̀ tàbí ti èyí tí ó súnmọ́ jùlọ. Àwọn ọ̀rọ̀ náà wà ní oniruru èdè conference.lds.org.

Tẹ̀