Ọ̀rọ̀ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kárún Ọdún 2013
Ìgbọràn ń mú àwọn Ìbùkún wá
Ìmọ̀ ti òtítọ́ àti àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa nlá jùlọ máa ń wá sí ọ̀dọ̀ wa bí a bá ṣe gbọ́ràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi olùfẹ́, ọpẹ́ mi ti pọ̀ tó lati wà pẹ̀lú yín ní òwúrọ̀ yí. Mo tọrọ fún ìgbàgbọ́ àti àwọn àdúrà yín bí mo ṣe nfèsì sí ànfàní láti báa yín sọ̀rọ̀.
Ní gbogbo àwọn ọjọ́, àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti ń wá ìmọ̀ àti òye kiri nípa ìwàláyé ikú yìí àti ipò wọn àti èrèdí wọn nínú rẹ̀, àti bákannáà fún ọ̀nà sí àláfíà àti ìdùnnú. Olukúlùkù wa nṣe irú ìwákiri bẹ́ẹ̀.
Ìmọ̀ àti òye yìí wà ní àrọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn. Wọ́n wà nínú àwọn òtítọ́ tí ó jẹ́ ti ayérayé. Nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, ìpín kíní, ẹsẹ̀ kọkàndínlógójì, a kà: “Kíyèsíi, àti wòó, Olúwa ni Ọlọ́run, àti pé ẹ̀mí ṣe ìjẹ́rí, àti pé ẹ̀rí náà jẹ́ òtítọ́, àti pé òtítọ́ dúró láéláé àtí láé.”
Akéwì kan kọ:
Bí àwọn ọ̀run tilẹ̀ sálọ àti tí àwọn orísun omi ayé fọ́,
Òtítọ́, àkópọ̀ ìwàláyé, yíó borí ohun tí ó lè burú jù,
Ayérayé, àìyípadà, títí láé.1
Àwọn kan yíó bèrè, “Níbo ni ó ti rí irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀, àti báwo ni á o ṣe dá a mọ̀?” Nínú ìfihàn kan tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith ní Kirtland, Ohio, ní Oṣù Kárún ti Ọdún 1833, Olúwa kéde:
“Òtítọ́ ni ìmọ àwọn nkan bí wọ́n ṣe wà, àti bí wọ́n ṣe ti wà rí, àti bí wọn yíó ṣe wá. …
“Ẹ̀mí ti òtítọ́ jẹ́ ti Ọlọ́run. …
“Àti pé kò sí ẹnití yíó gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àfí tí ó bá pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.
“Ẹnití ó bá pa àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] mọ́ gba òtítọ́ àti ìmọ́lẹ̀, títí di ìgbà tí yíó di ológo nínú òtítọ́ tí ó sì mọ ohun gbogbo.”2
Irú ìlérí ológo wo ni èyí! “Ẹnití ó bá pa àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] mọ́ gba òtítọ́ àti ìmọ́lẹ̀, títí di ìgbà tí yíó di ológo nínú òtítọ́ tí ó sì mọ ohun gbogbo.”
Kò sí ìwúlò fún ìwọ tàbí fún èmi, ní ayé ọ̀làjú yìí tí a ti ṣe àmúpadàsípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere, láti wa ọkọ̀ ní àwọn òkun tí a kò í tíì dámọ̀ tàbí rìn ìrìn àjò ní àwọn ọ̀nà tí a kò sàmì sí láti wá òtítọ́. Bàbá Ọ̀run olóore tí ya ọ̀nà wa, Ó sì ti pèsè atọ́nisọ́nà tí kìí yẹ̀—àní ìgbọràn. Ìmọ̀ ti òtítọ́ àti àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa tí ó tóbi jùlọ ńwá sí ọ̀dọ̀ wa bí a bá ṣe ngbọ́ràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run.
À ń kọ́ ìgbọràn ní gbogbo ìgbé ayé wa. Bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí a kéré gan, àwọn tí wọ́n ní ojúṣe fún ìtọ́jú wa ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìtọ́sọ́nà àti àwọn òfin láti ṣe ìdánilojú ààbò wa. Ayé yíó rọrùn fún gbogbo wa tí a bá lè gbọ́ràn sí irú òfin bẹ́ẹ̀ pátápátá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa, síbẹ̀síbẹ̀, n kẹ́kọ́ nípa ìrírí tí ọgbọ́n ti jíjẹ́ olùgbọ́ràn.
Nígbà tí mó ndàgbà, ní olúkúlùkù ìgbà oòrùn láti ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù kéje títí di ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù kẹ́sán, àwọn ìdílé mi gbé ní ilé inú oko ní Vivian Park ní Ọ̀gbùn Provo ní Utah.
Ìkan nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ nígbà àwọn ọjọ́ àìbìkítà wọ̀nnì nínú ọ̀gbùn nã ni Danny Larsen, tí ìdílé tirẹ̀ náà ní ilé nínú oko kan ní Vivian Park. Lójojúmọ́ òun àti èmí ń jẹ̀ káàkiri párádísè ọmọkùnrin yìí, à máa npa ẹja nínú odò ṣíṣàn àti odò nla, à máa nṣa òkúta àti àwọn ìṣura míràn, ní rírìn, ní gígùn òkè, àti ní gbígbádùn olúkúlùkù ìṣẹ́jú ti olúkúlùkù wákàtí ti olúkúlùkù ọjọ́.
Ní òwúrọ̀ kan, Danny àti èmi pinnu pé a fẹ́ ní iná-àgọ́ ní ìrọ̀lẹ́ nã pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa nínú ọ̀gbun. A kàn nílò láti palẹ̀mọ́ agbègbè kan ní pápá kan tí ó súnmọ́ níbi tí gbogbo wa lè péjọ sí. Koríko ìgbà Oṣù kẹ́fà ti bo gbogbo pápá náà wọ́n sì ti gbẹ wọ́n sì ní ẹ̀gún , èyí tí ó mú kí pápá náà ṣe àìwúlò fún èrò wa. A bẹ̀rẹ̀ láti má a fa àwọn koríko gíga náà ní ìpinnu láti palẹ̀mọ́ agbègbè nlá róbótó kan. A fà a sì ja a pẹ̀lú gbogbo ipá wa, ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí a lè rí kò ju àwọn ẹ̀kúnwọ́ àwọn èpo líle nã lọ. A mọ wípé iṣẹ́ yìí yíó gba gbogbo ọjọ́, àti pé okun-inú àti ìyá gágá ara wa ti ń díkù.
Àti nígbànáà ohun tí mo rò wípé ó jẹ́ àbáyọ pípé wá sínú ọkàn ọmọ-ọdún-mẹ́jọ mi. Mo wí fún Danny, “Ohun tí a kàn nílò láti ṣe ni kí a dáná sun àwọn èpo yìí. À ó kàn jó ibi róbótó kan nínú àwọn èpo náà!” Lọ́gán ni ó gbà, mo sì sáré lọ́ sí ilé inú oko wa láti mú àwọn ìṣáná díẹ̀.
Kí a máṣe rí ẹ̀nikẹ́ni yín tí ó rò wípé ní ọmọ ọdún mẹ́jọ jẹ́jẹ́, a ní ìyọ̀nda láti lo ìṣáná, mo fẹ́ fi yé e yín dájú pé a ti kà á ní èèwọ̀ fún Danny àti èmi láti lò wọ́n láì sí àbojútó àgbàlagbà. A ti kìlọ̀ léraléra fún àwa méjìjì nípa àwọn ewu iná. Síbẹ̀síbẹ̀, mo mọ ibi tí àwọn ìdílé mi fi ìṣáná pamọ́ sí, àti pé a nílò láti palẹ̀mọ́ pápá nã. Láì tilẹ̀ ronú si lẹ́ẹ̀mejì, mo sáré lọ sí ilé inú oko wa, mo sì mú igi ìṣáná díẹ̀, ní rírĩ dájú pé kò sí ẹnìkankan tí ó ńwò mí. Mo tètè fi wọ́n pamọ́ sínú ìkan nínú àwọn àpò mi.
Mo sáré padà sọ́dọ̀ Danny , ní ìrúsóké pé nínú àpò mi, mo ní àbáyọ sí wàhálà wa. Mo rántí ìronú mi pé ina náà yíó kàn jó dé ibi tí a fẹ́ àti lẹ́hìnnáà yíó kàn pa ara rẹ̀ bĩ idán.
Mo ṣá ìṣáná kan lórí òkúta mo sì dáná sí koríko ìgbà Oṣù kẹ́fà gbígbẹ náà. Ó gbiná bí ẹnipé a ti rìí sínú epo pẹtirólù. Lákọ́kọ́, ìnú Danny àti èmi ndùn bí a ṣé nwò àwọn èpo náà tí ó npoorá, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ó hàn kedere pé iná náà kò ṣetán láti kú fún ara rẹ̀. A jáyà nígbà tí a ṣe àkíyèsí pé kò sí ohun tí a lè ṣe láti dáa dúró. Àwọn ọwọ́ iná ìlẹ́ru náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé koríko líle náà gun òkè gba ẹ̀gbẹ́ orí òkè, wọ́n sì ń ṣe àkóbá fún àwọn igi pine àti ohun gbogbo tí ó kù ní ọ̀nà rẹ̀.
Níkẹhìn, a kò ní ìyàn kankan ju kí a sáré lọ fún ìrànlọ́wọ́. Láìpẹ́, gbogbo àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó wà ní àrọ́wọ́tọ́ ní Vivian park ń sáré lọ sábọ̀ pẹ̀lú àwọn àpò Burlap tutu, tí wọ́n sì nlu àwọn ọwọ́ iná náà ní ìyànjú láti pa wọ́n. Lẹ́hìn wákàtí díẹ̀, àwọn ẹ̀gẹ́ iná tí ó kù di pípa. A ti gba àwọn igi ọlọ́jọ́ pípẹ́ pine náà là, àti àwọn ilé tí àwọn ọwọ́ iná náà kò bá ti dé níkẹhìn.
Danny àti èmí kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ líle ṣùgbọ́n pàtàkì ní ọjọ́ náà—kókó rẹ̀ tí ó jẹ́ pàtàkì ti ìgbọràn.
Àwọn àkóso àti àwọn òfin wà láti ṣè ìrànlọ́wọ́ fún àrídájú àbò ti ara wa. Bákannáà, Olúwa ti pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà àti àwọn àṣẹ láti ṣè ìrànlọ́wọ́ fún àrídájú àbò ti ẹ̀mí wa kí a ba lè yege nínú ìrin ìgbé ayé tí ara ikú alárékérekè yí kí a sì padà níkẹhìn sí ọ̀dọ̀ Bàbá Ọ̀run.
Ní ọgọgọ́rún ọdún sẹ́hìn, sí àwọn ìran kan tí wọ́n jínlẹ̀ nínú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti ìrúbọ ẹranko, Sámúẹ́lì fí ìgbóyà kéde: “Ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.”3
Ní ìgbà yìí, Olúwa fi han Wòlíì Joseph Smith pé Òun nílò “ọkàn àti ẹ̀mí tí ó yọ̀nda; àti ẹni tí ó yọ̀nda tí ó sì gbọ́ràn yíó jẹ ire ti ilẹ̀ Síónì ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn yìí.”4
Gbogbo àwọn wòlíì, ti àtijọ́ àti ti ìgbàlódé, ti mọ̀ wípé ìgbọràn jẹ́ kòṣeémání fún ìgbàla wa. Nífáì kéde, “Èmi yíò lọ láti ṣe àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ.”5 Bí àwọn míràn tilẹ̀ kọsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn wọn, Nífáì kò fi ìgbà kan kùnà láé láti ṣe ohun tí Olúwa bèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn ìran tí a kò lè sọ ti di alábùkún ní ẹ̀san rẹ̀.
ìgbọràn kan tí nfúnni ní ìmísí ìjìnlẹ̀ ọkàn niti Abrahamu àti Isaaki. Àkọsílẹ̀ kan nípa ìgbọràn ti ó ní ìmísí ìjìnlẹ̀ sí ọkàn ni ti Abrahamu àti Isaaki. Ó ti má a jẹ́ ìrora líle tó fún Abrahamu, ní ìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, láti mú àyànfẹ́ rẹ̀ Isaakì lọ sí ilẹ̀ Moria láti fi ṣe ìrúbọ. Njẹ́ a lè wòye bí ọkàn Abrahamu ṣe wúwo tó bí ó ṣe rìn ìrìnàjò lọ sí ibi yíyàn náà? Dájúdájú, àròkàn gbọ́dọ̀ ti run ara rẹ̀ kí ó sì fi ìyà jẹ ọkàn rẹ̀ bí ó ṣe de Isaaki, gbé e sí órí pẹpẹ, tí ó sì mú ọ̀bẹ láti pa á. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àìṣiyèméjì àti ìgbẹ́kẹ̀lé tó péye nínú Olúwa, ó jẹ́ ìpè sí àṣẹ Olúwa. Báwo ni àsọsíta nã ti ní ógo tó, àti pẹ̀lú irú ìkíni káàbọ̀ ìyanu wo ní ó wá: “Maṣe fọwọ́kan ọmọdé nì, bẹ́ẹ̀ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe é ní nkan: nítorí nísisìnyí èmí mọ̀ pé ìwọ́ bẹ̀rù Ọlọ́run, nígbàtí ìwọ kò ti dùnmí ní ọmọ rẹ, ọmọ rẹ náà kanṣoṣo.”6
A ti pe Abrahamu lẹ́jọ́ a sì ti dán an wò, àti fún ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn rẹ̀, Olúwa fún un ní ìlérí ológo kan: “Nínú irú-ọmọ rẹ ní a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé: nítorí tí ìwọ́ ti gba ohùn mi gbọ́.”7
Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò ní kí a dán ìgbọràn wa wò ní irú ọ̀nà onídárayá tí ó nrin ni lọ́kan bẹ́ ẹ̀, a nílò ìgbàgbọ́ lọ́wọ́ wa bákan náà.
Ààrẹ Joseph F. Smith kéde ní Oṣù kẹ́wa Ọdún 1873, “Ìgbọràn ní òfin kíní ní ọ̀run.”8
Aàrẹ Gordon B. Hinckley wípé, “Ìdúnnú ti àwọn ènìyàn mímọ́ ti ọjọ́ ìkẹhìn, àláfíà ti àwọn ènìyàn mímọ́ ti ọjọ́ ìkẹhìn, ìtẹ̀síwájú ti àwọn ènìyàn mímọ́ ti ọjọ́ ìkẹhìn, ìṣoríire ti àwọn ènìyàn mímọ́ ti ọjọ́ ìkẹhìn, àti ìgbàlà àti ìgbéga ológo jùlọ ayérayé ti àwọn ènìyàn wọ̀nyí dá lé rírìn nínú ìgbọràn sí àwọn ìmọ̀ràn ti …Ọlọ́run.”9
Ìgbọràn ni àmì ìdánimọ̀ àwọn wòlíì; Ó ti pèsè okun àti ìmọ̀ fún wọn ní gbogbo ọjọ́. Ó ṣe kókó fún wa kí a kíyèsí pé àwa, bákannáà, ní ẹ̀tọ́ sí orísun okun àti ìmọ̀ yí. Ó wà lọ́gan ní àrọ́wọ́tó olúkúlùkù wa bí a bá ṣe gbọ́ràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run.
Jákèjádò àwọn ọdún, mo ti mọ àìmoye ènìyàn tí wọ́n ti jẹ́ olódodo tí wọ́n sì gbọ́ràn. Mo ti jẹ́ alábùkún fún mo sì ní ìmísí nípa wọn. Njẹ́ kí nṣe alábápín ìtàn ìrú ènìyàn méjì bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú yín.
Walter Krause jẹ́ ọmọ Ìjọ tí ó dúró ṣinṣin tí, pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí rẹ̀, ó gbé ní ohun tí a wá mọ̀ bíi Germany ti Ìla Oòrun lẹ́hìn Ogun Àgbáyé Kejì. Láì ka àwọn ìṣòro tí ó dojúkọ sí nítorí àìsí òmìnira ní apá ayé náà ní ìgbà náà, Arákùnrin Krause jẹ́ ọkùnrin kan tí ó fẹ́ràn tí ó sì sin Olúwa. Ó ṣe àmúṣẹ gbogbo ojúṣe tí wọ́n fún pẹ̀lú ìgbágbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn.
Arákùnrin kejì, Johann Denndorfer, ọmọ ìlú Hungary, di ayípadà sí Ìjọ ní Germany, ó sì ṣe ìrìbọmi níbẹ̀ ní Ọdún 1911 ní ọmọ ọdún métadínlógún. Kò pẹ́ léhìn náà, ó padà sí Hungary. Lẹ́hìn Ogun Àgbáyé Kejì, ó di ẹlẹ́wọ̀n ní ìlú ara rẹ̀, ní ìlú Debrecen. A ti gba òmìnira bákan náà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Hungary.
Arákùnrin Walter Krause, tí kò mọ Arákùnrin Denndorfer, gba ojúṣe láti jẹ́ olùkọ́ni ilé rẹ̀ àti láti bẹ̀ẹ́wò lóòrèkóòrè. Arákùnrin Krause pe ẹnìkejì olùkọ́ni ilé rẹ̀ ó sì wí fún un: “A ti gba ojúṣe láti bẹ Arákùnrin Johann Denndorfer wò. Sé o ó wà ní àrọ́wọ́tọ́ láti lọ pẹ̀lú mi ní ọ́sẹ̀ yí láti ríi kí a sì fún un ní iṣẹ́ ìhìnrere kan?” Àti nígbànáà, ó ṣe àfikún, “Arákùnrin Denndorfer n gbé ní Hungary.”
Ẹnìkejì rẹ̀ tí ẹ̀rù báà bèrè, “Nígbà wo ní a ó kúrò?”
“Òla,” ní ìdáhùn tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Arákùnrin Krause.
“Nígbà wo ní a ó padà sílé?” ẹníkẹjì rẹ̀ bèrè.
Arákùnrin Krause da lóhùn, “A, ní bí ọ̀sẹ̀ kan – tí a bá padà.”
Àwọn alájọrìn olúkọ́ní ilé méjèjì lọ láti bẹ Arákùnrin Denndorfer wò, ní ìrìnàjò nípa ọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ ojú ọ̀nà láti agbègbè ìha àriwá mọ́ ìla òòrun ti Germany sí Debrecen, Hungary – ìrin nlá gidi. Arákùnrin Denndorfer kò ní àwọn olùkọ́ni ilé láti ṣìwájú ogun. Nísisìyí, nígbà tí ó rí àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yìí, ó kún fún ìmoore pé wọ́n wá. Lákọ́kọ́, ó kọ̀ láti bọwọ́ pẹ̀lú wọn. Dípò, ó lọ sí iyàrá rẹ̀ ó sì mú àpótí tí ó ní ìdáméwá rẹ̀ nínú, tí ó ti dájọ fún ọdún díẹ̀. Ó na ìdámẹ́wá rẹ̀ sí àwọn olùkọ́ní ilé rẹ̀ ó sì wípé, “Nísisìyí, mo wà ní rẹ́gí pẹ̀lú Olúwa.” Nísisìyí mo ní ìmọ̀lára jíjẹ́ yíyẹ láti bọ ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa!” Arákùnrin Krause sọ fún mi lẹ́hìn náà pé òun kò leè fi ọ̀rọ̀ júwe ìmọ̀-inú tí òhun ní láti ríi pé arákùnrin olóótọ́ yìí, tí kò ní ìfarakanra kankan pẹ̀lú Ìjọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ti yọ ìpín kẹ̀wá lára owo iṣẹ́ ṣíkíní rẹ̀ ní ìgbọràn àti ní déédéé láti fi san ìdámẹ́wá rẹ̀. Ó ti fí pamọ́ láì mọ ìgbà tàbí bí yíó tilẹ̀ ní ànfàní láti san án.
Arákùnrin Walter Krause ṣe aláìsí ní ọ́dún mésán sẹ́hìn ní ẹni ọdún mẹ́rìnléláádọ́rin. Ó sìn ní ódodo àti ní ìgbọràn ní gbogbo ayé rẹ̀, ó sì jẹ́ ẹni ìmísi fún mi àti gbogbo àwọn tí ó mọ̀ ọ́. Nígbátí a bá ní kí ó ṣe awọn ojúṣe, kò jẹ́ ní ìbéèrè láé, kò jẹ́ kùn láé, àti kò jé ni gáfárà láé.
Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi, ìdánwò nlá ti ayé yìí ni ìgbọràn. “A ó dán wọn wò ní báyí,” ni Olúwa wí, “láti ríi bóyá wọn yíó ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíó paláṣẹ fún wọn.”10
Olùgbàlá kéde: “Fún gbogbo àwon tí yíó gba ìbùkún láti ọwọ́ mi yíó ṣe ìbámú pèlú òfin tí a ti yàn fún ìbùkún nã, àti àwọn ètò ibẹ̀, gẹ́gẹ́bí a ti yàn ṣíwájú ìpilèṣẹ̀ ayé.”11
Kò sí àpẹrẹ ìgbọràn nlá tí ó wà ju ti Olùgbàlà wa lọ. Nípa Rẹ̀, Páùlù ṣe àkíyèsí:
“Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ Ọmọ, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọràn nípa ohun tí ó jìyà;
“Bí a sì ti sọ ọ́ di pípé, ó wá di orísun ìgbàlá àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ngbọ́ tirẹ̀.”12
Olúgbàlà ṣe àfihàn ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ ti Ọlọ́run nípa gbígbé aye pípé, nípa bíbọ̀wọ̀ fún ìpinnu mímọ́ jùlọ tí ó jẹ́ tirẹ̀. Láé kò jẹ́ rò wípé òun dára ju àwọn ẹlòmíràn lọ. Láé kò jẹ́ wú fún ìgbéraga. Láé kò jẹ́ jẹ́ aláìṣòótọ́. Títí láé nió jẹ́ ẹni ìrẹ̀lẹ̀. Títí láé nió jẹ́ ẹni aṣòótọ́. Títí láé nió jẹ́ ẹni ìgbọràn.
Bíótilẹ̀jẹ́pé a darí Rẹ̀ nípa ti Ẹ̀mí lọ́ sínú aginjù láti dán an wò nípasẹ ọ̀gá ẹ̀tàn, àní èṣù, bíótilẹ̀jẹ́pé ó ti rẹ̀ Ẹ́ láti gbígba àwẹ̀ fún ogójì ọjọ́ àti ogójì òru àti tí ebí npa á, síbẹ̀ ẹni ibi náà fi àwọn àbá onífanímọ́ra àti tí ndán niwò lọ Jésù, Ó fún wa ní àpẹrẹ ọ̀run ti ìgbọràn nípa kíkọ̀ láti yapa kúrò nínú òhun tí Ó mọ̀ wípé kó tọ́.13
Nígbàtí ìrora ti Getsemani dojú kọ Ọ́, níbití Ó ti farada irú ìrora tí ó jẹ́ wípé “ìlàágùn Rẹ̀ dàbí ríro ẹ̀jẹ̀ nlá tí o njábọ́ sílẹ̀,”14 Ó ṣàpẹrẹ Ọmọ ìgbọràn nípa wíwí, “Bàbá, bí Ìwọ́ bá fẹ́, gba ago yí lọ́wọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bíkòṣe tìrẹ ní kí a ṣe.”15
Bí Olùgbàlà ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ ìṣáájú, bẹ́ẹ̀ni Ó nkọ́ ìrẹ àti èmi: “Ìwọ má a tọ̀ mí lẹ́hìn.”16 Njẹ́ à á nfẹ́ láti gbọ́ràn?
Ìmọ́ tí à nwá, àwọn ìdáhùn tí à nfẹ́, àti okun tí a fẹ́ lóní láti dojú kọ àwọn ìpeiníjà tí ayé oníṣòro tí ó nyípadà lè jẹ́ tiwa nígbàtí a bá fí tọkàntọkàn gbọ́ràn sí àwọn àṣẹ Olúwa. Mo tún ṣe àròsọ àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa: “Ẹnití ó bá pa àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] mọ́ gba òtítọ́ àti ìmọ́lẹ̀, dígbà tí yíó da ológo nínú òtítọ́ àti tí ó mọ ohun gbogbo.”17
Ó jẹ́ àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ mi wípé a ó di alábùkún pẹ̀lú àwọn ọrọ̀ èrè tí a ṣèlérí fún àwọn onígbọràn. Ní orúkọ ti Jésù Krístì, Olúwa àti Olugbàla wa, àmín.
© Ọdún 2013 nípasẹ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/12. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/12. Àyípadà èdè ti First Presidency Message, May 2013. Yoruba. 10665 779