2013
Ṣètò Kíkà
August 2013


Ọ̀dọ́

Ṣètò Kíkà

Ààrẹ Eyring ṣe àtúnsọ Ààrẹ Spencer W. Kimball (1895–1985) tí ó wípé “Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti ka àwọn ìbùkún wa àti ti fífi ètò kíka àwọn ìbùkún wọ̀nyí sílẹ̀ fún àwọn ìran wa.” Ní Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbòò ti Oṣù Kẹ́wá Ọdún 2012, Ààrẹ Thomas S. Monson fúnni ní ẹ̀rí rẹ̀ nípa kíkọ ìwé àkọsílẹ̀. Ó ṣe alábápín àwọn ìrírí kan láti ayé rẹ̀, ní àfikún, “Ìwé àkọsílẹ̀ mi tojojúmọ́, tí a tọ́jú ní gbogbo ọdún yìí, ti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti pèsè àwọn oun pàtó kan tí ó ṣe é ṣe pé láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ un ò ní lè rántí.” Ó gbaninímọ̀ràn, “Sètò àgbéyẹ̀wò ayé rẹ kí o sì wa àwọn ìbùkún, nlá àti kékeré, ní pàtó tí ó ti rígbà.” (“Consider the Blessings,” Liahona àti Ensign, Oṣù Kọkànlá Ọdún. 2012, 86). Múra láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn wòlíì wọ̀nyi kí o sì dá ìdíwọ̀n láti kọ sínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ.

Tẹ̀