2013
Ṣe Ìdámọ̀, Rántí, àti Ṣe Ìdúpẹ́
August 2013


Ọ̀rỌ̀ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kẹ́jọ Ọdún 2013

Ṣe Ìdámọ̀, Rántí, àti Ṣe Ìdúpẹ́

Ààrẹ Henry B. Eyring

Ọlọ́run ńbi wá kí a f’ọpẹ́ fún Òun fún àwọn ìbúkún k’íbùkún tí a rí gbà láti ọwọ́ Rẹ̀. Ó rọrùn fún wa láti má a ṣe àwọn àdúrà ìmoore wa lásán, ní títún àwọn ọ̀rọ̀ kannáà sọ nígbàkúgbà ṣùgbọ́n láìní ìpinnu láti ṣe ìdúpẹ́ wa gẹ́gẹ́bíi ẹ̀bùn ti ọkàn sí Ọlọ́run. A níláti “dúpé … nínú Ẹ̀mí” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 46:32) kí a ba lè ní ìmoore tó dájú fún ohun tí Ọlọ́run ti fún wa.

Báwo ni a ṣe tilẹ̀ lè rántí lára gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa? Àpóstélì Jòhánnù ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí Olùgbàlà kọ́ wa nípa ẹ̀bùn ìrántí kan tí ó nwá nípasẹ ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́: “Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, tí ó jẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, ẹniti Bàbá yíó rán lí orúkọ mi, òhun ní yíó kọ́ọ yín ní ohun gbogbo, yíó sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín” (Jòhánnù 14:26).

Ẹ̀mí Mímọ́ nmú àwọn ìrántí ohun tí Ọlọ́run ti kọ́ wa padà. Àti ìkan nínú àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run nkọ́ wa ni pẹ̀lú àwọn ìbùkún rẹ̀; àti nípa bẹ́ẹ̀, tí a bá yàn láti lo ìgbàgbọ́, Ẹ̀mí Mímọ́ yíó mú àwọn àánú Ọlọ́run wá sí ìrántí wa.

O lè dán ìyẹn wò nínú àdúrà lóní. Ó yẹ kí o tẹ̀lé aṣẹ yìí “Ìwọ́ yíó dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ nínú ohun gbogbo” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:7).

Ààrẹ Ezra Taft Benson (1899–1994) gbà àmọ̀ràn wípé àdúrà npèsè àkókò láti ṣe ìyẹn. Ó wípé: “Wòlíì Jósẹ́fù sọ nígbà kan wípé ìkan nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nlá tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ọjọ́ ìkẹhìn yíó jẹ̀bi rẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ àìmoore. Mo lérò wípé pùpọ́ nínú wa ò ronú nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ nlá. Ìdarísí nlá wà fún wa nínú àwọn àdúrà wa àti àwọn ìbèèrè wa pẹ̀lú Olúwa láti bèrè fún àfikú àwọn ìbùkún. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà míràn, mo ní ìfẹ́ inú láti ya púpọ̀ nínú àwọn àdúrà wa sí àfihàn ìmoore àti ìṣọpẹ́ fún àwọn ìbùkún tí a ti gbà tẹ́lẹ̀. À á ngbádùn púpọ̀.”1

O lè ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lóní. O lè bẹ̀rẹ̀ àdúrà tara ẹni pẹ̀lú ìdúpẹ́. Ó lè bẹ̀rẹ̀ láti ka àwọn ìbùkún rẹ kí o sì dúró fún ìgbà díẹ̀. Tí o bá lo ìgbàgbọ́, pẹ̀lú ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, o ó rí wípé àwọn ìrántí ti àwọn ìbùkún míràn yíó ṣàn bí odò sínú ọkàn rẹ. Tí o bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìmoore fún ìkọ̀ọ̀kan wọn, àdúrà rẹ yíó pẹ́ díẹ̀ ju ti tílẹ̀ lọ. Ìrántí yíó wa, àti bẹ́ẹ̀ ní ìmoore.

O lè tún ṣe ìrú nkan bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó bá nṣe àkọsílẹ̀ kan sínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ. Ẹ̀mí Mímọ́ ti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ pẹ̀lú ìyẹn láti ìbẹ̀rẹ̀ àkókò. Ṣe o rántí pé ìwé ti Mósè wípé, “Àti ìwé ìrántí kan ní a tọ́jú, nínú èyí tí a ṣe àkọsílẹ̀, ní èdè ti Àdámù, nítorí tí a fífún iye àwọn tí ó képe Ọlọ́run láti kọ nípasẹ ẹ̀mí ìmísí” (Mósè 6:5).

Ààrẹ Spencer W. Kimball (1895–1985) ṣàpèjúwe ìlà ẹsẹsẹ ti kíkọ ti onímísí: “Ó tún bọ̀ ṣe é ṣe fún àwọn tí ó tọ́jú ìwé ìrántí láti mú Olúwa sí ìrántí ní ayé wọn lójojúmọ́. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti ka àwọn ìbùkún wa àti ti fífi ètò kíka àwọn ìbùkún wọ̀nyí sílẹ̀ fún àwọn ìran wa.2

Bí o bá ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kọ, o lè bi ara rẹ, “Báwo ni Ọlọ́run ṣe bùkún mi àti àwọn tí mo fẹ́ràn lóní?” Tí o bá ṣe ìyẹn tó nígbàkúgbà àti pẹ̀lú ìgbàgbọ́, o ó rí ara rẹ tí ò ó nrántí àwọn ìbùkún. Àtí nígbàmíràn, o ó ní àwọn ẹ̀bùn wá sí ọkàn rẹ tí o kùnà láti ṣàkíyèsí láarín ọjọ́ ṣùgbọ́n tí wà mọ̀ nígbà yẹn pé ó jẹ́ ìfọwọ́kan ọwọ́ Ọlọ́run nínú ayé rẹ.

Mo gbàdúrà pé a ó ní ipá tí ó ntẹ̀ síwájú nínú ìgbàgbọ́ láti ṣe ìdámọ̀, rántí àti láti ṣe ìdúpé fún nkan ti Bàbá Ọ̀run àti Olùgbàlà wa ti ṣe àti tí wọ́n nṣe láti ṣi ọ̀nà padà sílé sí ọ̀dọ̀ Wọn.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Ezra Taft Benson, God, Family, Country: Our Three Great Loyalties (Ọdún 1974), 199.

  2. Spencer W. Kimball, “Listen to the Prophets,” Ensign, Oṣù Kárún Ọdún 1978, 77.