Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́jọ Ọdún 2013
Ìtọ́jú
Fi àdúrà ṣàṣàrò lórí ohun yìí àti, bí ó bá bójú mu, ṣe àjọsọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arábìnrin tí ò ó mbẹ̀ wò. Lo àwọn ìbéèrè náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìfúnlókun àwọn arábìnrin rẹ àti láti mú Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ jẹ́ ipá tí ó láapọn nínú ayé rẹ. Fún ìmọ̀ síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Àwọn ìpinnu ti ìtọ́jú ní ìjọ ní láti ran àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lọ́wọ́ láti gba ìdádúro-ara ẹni, láti bojúto àwọn tálákà àti aláìní, àti láti pèsè ìṣẹ́-ìsìn. Ìtọ́jú ṣe kókó sí iṣẹ́ Ègbẹ́ Aranilọ́wọ́. Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kíní nínú Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, ti kọ́ni:
Láti ìbẹ̀rẹ̀ àkókò, [Olúwa] ti pèsè àwọn ọ̀na fún àwọn ọmọ ẹ̀hin rẹ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́. Ó ti rọ àwọn ọmọ Rẹ̀ láti ya àkókò wọn, ohun ìní wọn, àti ara wọn sọ́tọ̀ láti darapọ̀ mọ́ Òun láti ṣe ìṣẹ́ ìsìn fún àwọn ẹlòmíràn. …
“Ó ti rọ̀, ó sì pàṣẹ fún wa láti kópa nínú iṣẹ́ rẹ̀ láti gbé àwọn aláìní sóké. A dá májẹ̀mú láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn omi ìrìbọmi àti nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ Ọlọ́run. A ṣe àtúndá májẹ̀mú náà ní ọ̀sẹ̀sẹ̀ nígbà tí a bá kópa nínú oúnjẹ ara Oluwa.”1
Lábẹ́ ìdarí ti bíṣọ́pù tàbí ààrẹ ẹ̀ka kékeré, àwọn olùdarí ibi tí a wà nṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ìtọ́jú ẹ̀mí àti ara. Àwọn ànfàní láti ṣe ìṣẹ́ ìsin nígbàkúgbà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni abẹniwò tí wọ́n ń wá ìmísí láti mọ bí wọ́n ṣe lè fèsì sí àwọn àìní olúkúlùkù arábìnrin tí wọ́n ń bẹ̀wò.
Láti Àwọn ìwé Mímọ́
Lúkù 10:25–37; Jákọ́bù 1:27; Mòsíàh 4:26; 18:8–11; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 104:18
Láti Ìtàn Wa
Ní Oṣù kẹfà, Ọdún 1842, Wòlíì Joseph Smith kàn sí àwọn arábìnrin Ẹ̀gbẹ́ Aranílọ́wọ́ láti “ṣè rànlọ́wọ́ fún àwọn tálákà” àti láti “gba àwọn ọkàn là.”2 Àwọn ìwọ̀n díwọ̀n yí ṣì wà ní ọkàn Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́, a sì ṣe àfihàn rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àkọlé wa hese, “Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ kìí yẹ̀ láí” (Kọ́ríntì Kíni 13:8).
Ààrẹ gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ kárún, Emmeline B. Wells, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ àkọlé yí jáde ní ọdún 1913 ní ìrántí àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ ìdásílẹ̀ wa: “A kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́bí èrò wa láti … [di] àwọn ẹ̀kọ́ onímísí ti Wòlíì Joseph Smith mú ṣinṣin nígbà tí ó ṣe àfihàn ìlànà nípa tí àwọn obìnrin yíó gbagbára nípasẹ ìpè ti oyè àlùfáà láti di kíkó jọ sínú àwọn ẹgbẹ́ tí ó yẹ fún èrò láti bójútó àwọn aláìsàn, ran àwọn aláìní lọ́wọ́, tu àwọn arúgbó nínú, kìlọ̀ fún àwọn tí ó ń ṣáko, àti ṣàtìlẹhìn fún àwọn ọmọ òrukàn.”3
Lóní, Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ ti ran ká àgbáyé bí àwọn arábìnrin ṣe é ń nawọ́ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìfẹ Krístì tí kò ní àbàwọ́n, sí àwọn ọmọ ẹnìkejì wọn. (rí Mòrónì 7:46–47).
© Ọdún 2013 nípasẹ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/13. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/13. Àyípadà èdè ti Iṣẹ́ Olùkọ́ni Abẹniwò, Oṣù Kẹ́jọ Ọdún 2013 Yoruba. 10667 779