2013
Ó ṣeeṣe Fun Mi Lati Jọ̀wọ́ Ìbànújẹ́ Mi Lọ́wọ́ Lọ
OṢù Owewe 2013


Ọ̀dọ́

Ó ṣeeṣe Fun Mi Lati Jọ̀wọ́ Ìbànújẹ́ Mi Lọ́wọ́ Lọ

Olùkọ̀wé wa lati Taiwan

Nigbati awọn ọ̀rẹ́ mi Arákùnrin Chen ati ìyàwó rẹ̀ ṣe ìrìbọmi sínú ẹ̀ka wa, mo ní ayọ̀ púpọ̀jù. Ọdún kan lẹ́hìn ìrìbọmi wọn, a dè wọ́n nínú tẹ́mpìlì, ati pé ọmọkùnrin wọn tí ó ti kọjá lọ kí wọ́n ó tó darapọ̀ mọ́ ìjọ náà ni a dè mọ́ wọn. Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu lati ríi bí awọn Chen ṣe ńdàgbà ninu ìhìnrere.

Lẹ́hìnnáà Arákùnrin Chen kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ kan ní ọdún tí ó tẹ̀lée. Lẹ́hìn ìjàmbá náà, ikú rẹ̀ dàbí ẹnipé ó máa ńwà ní ọkàn mi ní gbogbo igbà ó sì máa ńdọdẹ awọn àlá mi nígbà kugbà Mo jí pẹ̀lú omijé mo sì bèèrè léraléra lẹ́ẹ̀kansi, “Torí Kínni? Torí kínni Oluwa ṣe gba irú àjálù bayĩ láàyè lati ṣẹlẹ̀? Torí kínni irú ohun yĩ ṣe níláti ṣẹlẹ̀ sí ìdílé dáradára yĩ? Ní ọjọ kan, nigbati mo ńtiraka pẹ̀lú awọn ìbeerè wọ̀nyí, mo mú ìwé ìkọ́ni kan mo sì ka awọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípasẹ̀ Olùdarí Spencer W. Kimball (1895–1985):

“Bí a bá wo kíkú bĩ ìdàkejì ti wíwà lãyè, nígbànáà ìrora, ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀ ati àìgùn ní ẹ̀mí yio jẹ́ ohun ibi. Ṣùgbọ́n bí a bá wo ayé gẹ́gẹ́ bĩ ohun ayérayé tí ó gùn jìnnà wọ inú wíwà ṣãjú ara ikú tí ó ti kọjá lọ dé inú ọjọ́ iwájú ayérayé ẹ̀hìn ikú, nígbànáà a ó le fi ojú inú tí ó dára wo gbogbo nkan tó ńṣẹlẹ̀. …

“Njẹ́ kĩ iṣe pé a ńfi awọn ìdẹwò hàn wá lati dán okun wa wò, àìsàn kí a le kọ́ sùúrù, ikú kí á le di àìkú ati ológo?”1

Ní àkókò náà, mo pinnu lati jọ̀wọ́ ìbànújẹ́ mi lọ́wọ́ lọ mo sì ńwòye sí inú ìlérí àti ọjọ́ iwájú tí ó ṣeéṣe. Mo rí nínú ojú ọkàn mi tí Arákùnrin Chen fi ayọ̀ dàpọ̀ pẹ̀lú ẹbí rẹ̀. Ìwòye náà mú àlãfíà wá fún mi Mo mọ̀ pé Baba Ọ̀run yío fun wa ni ọgbọ́n ati ìgboyà lati kojú awọn ìpèníjà.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Awọn ìkọ́ni Awọn Olùdarí ti Ìjọ: Spencer W. Kimball (2006), 15.

Tẹ̀