2013
Awọn Ènìyàn Mímọ́ fun Gbogbo Àwọn Àkókò
OṢù Owewe 2013


Ọ̀rỌ̀ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kẹsànán 2013

Awọn Ènìyàn Mímọ́ fún Gbogbo Awọn Àkókò

Àwòrán
Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf

Mo ní awọn ìrántí ìgbà èwe nipa apákan ayé tí ó le ṣeé lò bí àwòrán alágbèéká kan fun ìyàtọ̀ awọn àkókò inú ọdún. Oṣù kọ̀ọ̀kan tí ó ń kọja jẹ́ ológo ati ìyanu. Ní àkókò òtútù bí ó ti yẹ kí ó rí, àwọn yìnyín titun máa ńbo àwọn òkè ati awọn òpópónà ilu. Àkóko ìrúwé a máa mú awọn òjò oníwẹ̀mọ́ wá ati awọn ariwo ńlá tí ó gbé àwọ̀ ewéko wọ̀. Awọn ojú ọ̀run ti ó ya ọ̀lẹ ní ìgbà ooru máa ńṣiṣẹ́ bíi aládùn àwòrán aláwọ̀ rẹ́súrẹ́sú fun gbígbóná ti ìmọ́lẹ̀ òòrùn. Ati pé ọ́tọ́mù ninu ọlá rẹ̀ máa ń yí àdáyébá padà sí awọn àwọ̀ dáradára ti olómi ọsàn, èsúrú, ati pupa. Gẹ́gẹ́bí ọmọdé, mo fẹ́ràn àkókò kọ̀ọ̀kan, ati titi di òní, mo fẹ́ràn ìwà ati àìlẹ́gbẹ́ ti ìkọ̀ọ̀kan wọn.

A ní awọn àkókò ninu ayé wa bákannáà. Díẹ̀ jẹ́ lílọ́ wọ́rọ́wọ́rọ́ tí ó sì ládùn. Awọn miran kìi ṣe bẹ́. Díẹ ninu awọn ọjọ́ ayé wa máa ńrẹwà bíi awọn àwòrán inú kàlẹ́ndà. Ati síbẹ̀síbẹ̀ awọn ọjọ́ ati sànmọ̃nì míràn wà tí ó máa ńfa ìrora ọkàn tí ó sì máa ńmú ìjìnlẹ̀ ìmọ̀lára ti àìnírètí, ìkóríra, ati ìbínú wá sínú ayé wa.

Mo mọ̀ dájú pé ní àkókò kan tàbí òmiràn gbogbo wa ti ní èrò pé yío dára bí a bá le gbé ni ilẹ̀ tí ó kún fún awọn ọjọ́ ati àkókò tí ó dara bĩ àwòrán kí a sì yẹra fun awọn ìgbà tí kò ládùn tí ó wà lãrin rẹ̀.

Ṣùgbọ́n eléyĩ kò ṣeéṣe. Tàbí kí ó ṣeé fẹ́.

Bí mo ṣe wo ìgbé ayé tèmi fúnra mi, ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú awọn àkókò ìdàgbàsókè nla ni wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ mi nigbati mo ńla awọn àkóko ìdàrúdàpọ̀ kọjá.

Baba wa Ọ̀run ọlọ́gbọ́n-gbogbo mọ̀ pé fún awọn ọmọ Rẹ̀ lati dàgbà di ẹ̀dá tí a dá wọn lati dà, wọ́n nilati ní ìrírí awọn àkókò ìpèníjà ní ìgbà àtìpó wọn ninu ara ikú. Wolĩ Léhì ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ pé láìsí àtakò, “òdodo kò le wá sí ìmúṣẹ” (2 Nephi 2:11). Dájúdájú, ìkorò inú ayé ni ó ń jẹ́ kí á ṣe ìdámọ̀, ìfiwé, ati kí a le dúpẹ́ fun adùn rẹ̀ (rí D&C 29:39; Moses 6:55).

Olùdarí Brigham Young sọọ́ ní ọ̀nà yìi: “Gbogbo awọn olóye ẹ̀dá ti wọn ti dé ni awọn adé ògo, àìkú, ati ìyè ayérayé gbọ́dọ̀ la awọn ìdánwò kọja èyítí a ti yàn fun awọn olóye ẹ̀dá lati là kọjá, lati le ní ògo ati ayọ̀ wọn. Olukúlùkù àjálù tí ó bá le wá sí orí awọn ẹ̀dá ninu ara ikú ni yío di fífi ara dà … lati pèsè wọn lati gbádùn wíwà pẹlu Oluwa. … Olukúlùkù ìdánwò ati ìrírí tí ẹ ti là kọjá ṣe dandan fun ìgbàlà yin.”1

Ìbẽrè nã kìí ṣe bóyá a ó ní ìrírí awọn àkókò ìpèníjà ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe fi ara da ìjì náà. Ànfãní nla wa nínú awọn àkókò ìgbé ayé tí ó ńyípadà ṣáà ni lati di òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ṣinṣin, nitoripe a dá ìmọ̀ràn Rẹ̀ kìí ṣe lati ràn wá lọ́wọ́ fi ara da ìjì ayé nìkan ṣùgbọ́n lati darí wa kọjá wọn bákannã. Baba wa Ọ̀run ti fi ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fúnni lati ipasẹ̀ awọn wòlĩ Rẹ̀ — ìmọ̀ iyebíye tí a dá lati ṣe amọ̀nà wa lãrin awọn ìdojúkọ ti awọn àkókò tí ó ṣòro ní títẹ̀síwaju si ayọ̀ tí kò ṣẽ fi ẹnu sọ ati ìmọ́lẹ̀ dáradára ti ìyè ayérayé. Ó jẹ́ ipa pàtàkì kan ninu ìrírí ti ayé wa lati le ní okun, ìgboyà, ati ìwa àìlábùkù lati di òtítọ́ ati òdodo mú ṣinṣin láì ka ìjìyà tí a le ní ìrírí rẹ̀ sí.

Awọn tí wọn ti wọ inú omi ìrìbọmi ti wọn sì ti gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi ẹsẹ̀ wọn lé ọ̀nà ọmọlẹ́hìn a sì gbà wọ́n ni ìyànjú lati tẹ̀lé ipasẹ̀ Olùgbàlà pẹ̀lú ìdúróṣinṣin ati ìgbàgbọ́.

Olùgbàlà kọ́ni pe õrùn ńràn “sí ori búburú ati rere, ati … òjò [ń rọ̀] sí ori olódodo ati aláìṣòdodo” (Màttéù 5:45). Nígbàmíràn kò lè yé wa ìdí tí ohun tí ó ṣòro, àní tí kò dára tó, fi ńṣẹlẹ̀ ninu ayé. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bĩ ọmọlẹ́hìn Krístì, a ní ìgbàgbọ́ pé bí a bá “wá kiri pẹ̀lú ãpọn, gbàdúrà nígbà gbogbo, tí a sì jẹ́ onígbàgbọ́, … ohun gbogbo yío ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere [tiwa], [a bá] rìn ní títọ́” (D&C 90:24; a fi àtẹnumọ́ kún un).

Gẹ́gẹ́bí awọn ọmọ ìjọ Rẹ̀, gẹ́gẹ́bí awọn ènìyàn Mímọ́, a ńsìn tayọ̀tayọ̀ ati pẹ̀lú inú dídùn nínú gbogbo ojú ọjọ́ ati ní gbogbo awọn àkókò. Ati bí a ti ńṣe bẹ̃, ọkàn wa di kíkún fún ìgbàgbọ́ ọ̀wọ̀, ìrètí ìmúláradá, ati ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.

Síbẹ̀síbẹ̀, a ní lati la gbogbo awọn àkókò kọjá — èyítí ó ládùn ati èyítí ó kún fún ìnira. Ṣùgbọ́n èyíkéyĩ àkókò tí ó jẹ́, gẹ́gẹ́bĩ ọmọlẹ́hìn ti Jésù Krístì náà, a ó gbé ìrètí wa sí orí Rẹ̀ bí a ti ńrìn tọ ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ lọ.

Ní kúkúrú, a jẹ́ èniyàn Mímọ́ ti Ọlọ́run, pẹ̀lú ìpinnu lati kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, lati ní ìfẹ́ Rẹ̀, ati lati ní ìfẹ́ ọmọnìkejì wa. A jẹ́ arìnrìn àjò ní ojú ọ̀nà oníbùkún ti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn, a ó sì rìn pẹ̀lú ìdúroṣinṣin ní títọ èrèdí wa ti ọ̀run lọ.

Nítorínã, ẹ jẹ́ kí á jẹ́ ènìyàn Mímọ́ ní ìgbà rírú ewé, ní ìgbà ooru, ní ìgbà rírọ̀ òjò, ati ní ìgbà òtútù. Ẹ jẹ́ kí á jẹ́ ènìyàn Mímọ́ fun gbogbo awọn àkókò.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Ìdánilẹ́kọ́ ti Àwọn Olùdarí Àgbà ti Ìjọ: Brigham Young (1997), 67.

Ìdánilẹ́kọ́ láti Iṣẹ́ Yìí

Àjọ Awọn Olùdarí Àgbà ti kọ́ni, “Díẹ̀ nínú awọn ìwãsù tí ó tóbi jù ní a sọ nípa kíkọ awọn orin” (Awọn Orin, ix). Bí ẹ ṣe ńfi ọ̀rọ̀wérọ̀ lórí iṣẹ́ yĩ, ẹ rò nípa kíkọ orin pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ẹ̀ ńkọ́ nínú awọn orin wọ̀nyí tabí orin òmíràn tí ó nĩ ṣe pẹ̀lú fífi ara da ìdojúkọ: “How Firm a Foundation” (no. 85); “The Lord Is My Shepherd” (no. 108); or “Let Us All Press On” (no. 243). Bí ẹ bá ní ìmọ̀lára, ẹ sọ nipa àsìkò kan nígbàtí àkókò ìjì ninu ayé rẹ yípadà lati di ìbùkún.

Tẹ̀