2013
Ìgbẹ́kẹ̀lé Ara Ẹni
OṢù Owewe 2013


Ọ̀rỌ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Osù Kẹsànán 2013

Ìgbẹ́kẹ̀lé Ara Ẹni

Fi àdúrà ṣàṣàrò lórí ohun yìí àti, bí ó bá bójú mu, ṣe àjọsọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arábìnrin tí ò mbẹ̀ wò. Lo àwọn ìbéèrè náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìfúnlókun àwọn arábìnrin rẹ àti láti mú Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ jẹ́ ipá tí ó láapọn nínú ayé rẹ. Fún ìwífuńni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni ni agbára, ìfọkànsìn, ati akitiyan lati pèsè nipa ti ẹ̀mí ati nipa ti ara fun àlãfíà tiwa ati ti awọn ẹbí wa.1

Bí a ṣe ńkọ́ ẹ̀kọ́ tí a sì ńṣe àmúlò awọn ìlànà ẹ̀kọ́ ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni ninu ilé ati awọn agbègbè wa, a ní awọn ànfãní lati ṣe ìtọ́jú awọn tí kò ní ànító ati awọn aláìní ati lati ran awọn ẹlòmíràn lọwọ lati le gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ kí ó le bã ṣẽṣe fun wọn lati le fi ara da awọn ìgbà ìdojúkọ.

A ní ànfãní ati iṣẹ́ ṣíṣe lati lo agbára lati yàn wa láti gbẹ́kẹ̀ lé ara wa nipa ti ẹ̀mí ati nipa ti ara. Ní sísọ̀rọ̀ nipa gbígbẹ́kẹ̀lé ara ẹni nipa ti ẹ̀mí ati gbígbé ara lé Baba ní Ọ̀run, Alàgbà Robert D. Hales ti Àpéjọpọ̀ awọn Àpóstélì Méjìlá ti kọ́ni: “A ńdi ẹni ìyípadà a sì ńle gbẹ́kẹ̀ le ara ẹni bí a ṣe ńfi tàdúrà tàdúrà gbé ìgbé ayé awọn májẹ̀mú wa —nípasẹ̀ gbígba oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ, jíjẹ́ yíyẹ fun ìwé ìkaniyẹ, ati fífi ara ẹni jì lati sin awọn ẹlòmíràn.2

Alàgbà Hales gbà wá ní ìmọ̀ràn lati di gbígbẹ́kẹ̀lé ara ẹni nipa ti ara, “èyítí kíka ìwe gíga tabi gbígba ẹ̀kọ́ iṣẹ ọwọ, kíkọ́ lati ṣe iṣẹ́, ati gbígbé ní àìṣe ju ara ẹni lọ wà ninu rẹ̀. Nípa yíyàgò fún gbèsè ati fífi owó pamọ́ nísisìnyí, a ti gbaradì fun sísin Ìjọ ní kíkún ni awọn ọdún tí ó ńbọ̀. Èrèdí líle gbẹ́kẹ̀ le ara ẹni nipa ti ẹ̀mí ati nipa ti ara ni lati lè gbé ara wa lé ilẹ̀ gíga kí ó le bã ṣẽṣe fun wa lati le gbé awọn ẹlòmíràn tí wọn wà ní ipò àìní sókè.3

Láti Àwọn ìwé Mímọ́

Mattiu 25:1–13; 1 Timoti 5:8; Alma 34:27–28; Ẹ̀kọ́ ati Àwọn Májẹ̀mú 44:6; 58:26–29; 88:118

Láti Ìtàn Wa

Lẹ́hìn tí Awọn Èniyan Mímọ́ ti ọjọ́ Ìkẹhìn ti gbárajọ ní Àfonífojì Salt Lake, èyítí ó jẹ́ aginjù tí ó dá wà, Olùdarí Brigham Young fẹ́ kí wọn ó ṣe rere kí wọn ó sì kọ́ awọn ibùgbé tí yío pẹ́ títí. Èyí túmọ̀ sí pé awọn ènìyàn Mímọ́ nílò lati kọ́ ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ tí yío gbà wọn lãyè lati le gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn. Ninu akitiyan yìí, Olùdari Young ni ìgbáralé nla ninu awọn agbára lílèṣe, awọn ẹ̀bùn, jíjẹ́ onígbàgbọ́, ati ìjọ̀wọ́ ara ẹni awọn obìnrin, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ni awọn iṣẹ́ ṣíṣe pàtó nipa ti ara. Nigbàtí awọn iṣẹ́ ṣíṣe pàtó ti awọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Arannilọ́wọ́ mã ńyàtọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà lóde òní, ìlànà ẹ̀kọ́ nã dúró ní àìyàtọ̀.

  1. Ẹ kọ́ lati fẹ́ràn iṣẹ́ kí ẹ sì yàgò fún àìníṣẹ́.

  2. Ẹ tẹ́wọ́ gba ẹ̀mí fífi ara ẹni jì.

  3. Ẹ tẹ́wọ́ gba ojúṣe ara ẹni fun okun nipa ti ẹ̀mí, ìlera, ẹ̀kọ́ kíkọ́, iṣẹ́ ṣíṣe, awọn ìṣúná, oúnjẹ, ati awọn ohun miran ti o ṣe dandan fun mímú ìgbé ayé ró.

  4. Ẹ gbàdúrà fun ìgbàgbọ́ ati ìgboyà lati kojú awọn ìpèníjà.

  5. Ẹ fi okun fun awọn ẹlòmíràn tí wọn nílò ìrànlọ́wọ́.4

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Handbook 2: Administering the Church (2010), 6.1.1.

  2. Robert D. Hales, “Coming to Ourselves: The Sacrament, the Temple, and Sacrifice in Service,” Liahona and Ensign, May 2012, 34.

  3. Robert D. Hales, “Bíbọ̀ sí Ara wa,” 36.

  4. Daughters in My Kingdom: The History and Work of Relief Society (Ọdún 2011), 20–21.

Kíni Mo Lè Se?

  1. Báwo ni mo ṣe ńran awọn arábìnrin tí mo ńbójútó lọ́wọ́ lati rí ojútùú sí awọn àìní wọn nipa ti ẹ̀mí ati nipa ti ara?

  2. Njẹ́ mo ńṣe àlékún ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni mi ní ti ẹ̀mi nipa gbígbaradì fun gbígba oúnjẹ Oluwa ati fífi ara jì lati sìn?