2013
Ẹ̀bùn ti Jen
October 2013


Ọ̀dọ́

Ẹ̀bùn ti Jen

Olùdásílẹ̀ náà ńgbé ní Utah, USA

Mo ṣe àwọn oníruurú àṣìṣe kan nípa agbára láti yàn ní àwọn ọdún mi ní ilé ìwé gíga. Àwọn agbára láti yàn wọnnì jásí ìparí tó lewu àti ìbànújẹ́, àti pé mo gbèrò láti lo àyè ìsinmi mi láti bẹ̀rẹ̀ sí ńṣe àwọn àtúnṣe Nígbàtí ilé ìwé bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, mo jẹ oúnjẹ ọ̀sán nínú balùwẹ̀ tí a to ẹrù sí tàbí tí ó sófo ní ọ̀nà yàrá ńlá láti dẹ́kun àwọn ìdàpọ̀ tó ńdúró láti kí mi káàbọ̀.

Èmi kò ní ìmọ̀ ara dídá wa láéláé.

Nígbànáà Ọlọ́run fún mi ní ẹ̀bùn kan: Ó rán Jen sí mi Kò dá mi lẹ́jọ́ rí fún àwọn àṣìṣe mi ṣùgbọ́n dípò èyí ó gbà mí níyànjú láti máa tẹramọ́ rírìn ní ọ̀nà tòtọ́ Mímọ̀ pé òun yíò wà ní ilé ìwé ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú láti ka àwọn ìwé mímọ́ mi àti láti tọ́ ẹ̀rí mi. Ní ìgbà tí àsìkò gbígba oyè àṣeparí ẹ̀kọ́ dé, mo ti jẹ́wọ́ sí ara mi pé mo ti tẹramọ́ láti yípadà.

Mo máa ńgbèrò nígbà míràn ibi tí èmí ìbá wà lóní tí Jen kò bá ti nawọ́ jáde sí mi. Njẹ́ èmi ìbá ti dìmọ́ àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ mi láìsí òun? Pẹ̀lú oríre, èmi kò lè mọ̀ láéláé nítorí òun wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, ó ṣetán àti pé ó ní ìfẹ́ láti ràn mí lọ́wọ́.

Tẹ̀