2013
Míṣọ̀n Ọlọ́run ti Jésù Kristì Náà: Aṣẹ̀dá
October 2013


Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹwã 2013

Míṣọ̀n Ọlọ́run ti Jésù Kristì Náà: Aṣẹ̀dá

Fi tàdúrà tàdúrà kọ́ ohun èlò yí àti pé bí ó bá ṣe tọ́, sọọ́ pẹ̀lú àwọn arábìnrin tí ò ńbẹ̀wò. Lo àwọn ìbèèrè náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fún àwọn arábìnrin rẹ lókun àti láti mú Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ jẹ́ ipá tó làápọn ti ayé ara rẹ. Fún ìwífúnni púpọ̀ si, lọ sí reliefsociety.lds.org

Ìgbàgbọ́, Ìdílé, Ìrànlọ́wọ́

Jésù Krístì. “dá ọ̀run àti ayé” 3 Nífáì 9:15 Ẹ kíyèsíi, èmi ni jésù Krístì Ọmọ Ọlọ́run. Èmi ni ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn. Èmi wà pẹ̀lú Bàbá láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Mo wà nínú Bàbá, Bàbá náà sì wà nínú mi: nínú mi sì ni Bàbá ti ṣe orúkọ rẹ̀ lógo. Ó ṣeé nípa agbára ti Oyè àlùfáà, lábẹ́ ìdarí ti Bàbá wa Ọ̀run (rí) Moses 1:33.

Báwo ni ìmoore wa ṣe gbúdọ̀ jẹ́ pé ọlọ́gbọ́n aṣẹ̀dá kan tó ṣe ayé kan àti pé Ó fi wá síbí Ààrẹ Thomas S. Monson,” sọ pé,”… kí a balè ní ìrírí ìdánwò ti àsìkò kan, àyè kan láti jẹ́wọ́ ara wa ni ọ̀nà láti yege fún gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún wa láti gbà.”1 Nígbà tí a bá lo agbára láti yàn wa láti gbọ́ran sí àwọn òfin ti Ọlọ́run àti pe tí a di yíyẹ láti padà láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀.

Ti ẹ̀dá, Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf, Olùdámọ̀ràn kejì nínú Ààrẹ Kínní, sọ pé:

“Àwa ni ìdí tí Ó fi dá gbogbo ayé! …

“Èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ méjì kan tí ó dàbí ẹni pé ó jọra ti ènìyàn: ní àfiwé sí Ọlọ́run, ènìyàn kò jẹ́ nkankan, síbẹ̀síbẹ̀ a jẹ́ gbogbo nkan sí Ọlọ́run”2 Mímọ̀ pé Jésù Krístì dá ayé fún wa nítorí a jẹ́ ohun gbogbo sí Bàbá wa Ọ̀run lè ràn wá lọ́wọ́ láti fikún ìfẹ́ wa fún Wọn.

Láti Àwọn ìwé Mímọ́

John 1:3; Hebrews 1:1–2; Mosiah 3:8; Moses 1:30–33, 35–39; Abraham 3:24–25

Láti Ìtàn Wa

A ti dá wa ní àwòrán ti Ọlọ́run (see Moses 2:26–27), àti pé a ní agbára ti Ọlọ́run. Wòlíì Joseph Smith kìlọ̀ fún àwọn arábìnrin ní Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé sókè sí ànfàní [wọn]3 Pẹ̀lú ìgbìyànjú náà gẹ́gẹ́bí ìpìlẹ̀ kan, àwọn arábìnrin ní Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn ní a ti kọ́ láti gbé ìgbé ayé sókè sí agbára ti Ọlọ́run wọn nípa mímú àwọn èrò ti Ọlọ́run fún wọn ṣẹ. Gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe wá láti ní òye ẹni tí wọ́n jẹ́ lótítọ́, ọmọbìnrin ti Ọlọ́run, pẹ̀lú ipá àbínibí kan láti nífẹ́ àti láti tọ́ni, wọ́n débi agbara wọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn obìnrin mímọ́.”4

“Báyìí a fi ọ sí ipò kan níbití ó lè ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn ìbákẹ́dùn èyí tí Ọlọ́run ti gbìn sí àwọn oókan àyà yín,” ni Wòlíì Joseph Smith sọ. “Tí o bá gbé ìgbé ayé tó ga dé àwọn ìpìnlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí báwo ni títóbi àti ògo Tí o bá gbé ìgbé ayé tó ga dé ànfàní rẹ, àwọn ángẹ́lì kò ní lè dá ọ lẹ́kun láti jẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ.5

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Thomas S. Monson, “The Race of Life,” Liahona, May 2012, 91

  2. Dieter F. Uchtdorf, “You Matter to Him,” Liahona, Nov. 2011, 20

  3. Joseph Fielding Smith, nínú Daughters in My Kingdom: The History and Work of Relief Society (Ọdún 2011), 97.

  4. Daughters in My Kingdom, 171.

  5. Joseph Smith, nínú Daughters in My Kingdom, 169.

Tẹ̀