2013
Ojúṣe wa láti gbanisílẹ̀
October 2013


Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kẹwã 2013

Ojúṣe Wa látigbanisílẹ̀

Àwòrán
Ààrẹ Thomas S. Monson

Fún Àwọn Ènìyàn Mímọ́, a nílò láti gba àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa sílẹ̀ tí wọ́n tí, fún ìdí kan tàbí òmíràn, ṣáko lọ kúrò lọ́nà ti aápọn Ìjọ jẹ́ ti àpẹrẹ ayérayé. Njẹ́ a mọ nípa irú àwọn ènìyàn tí ó fìgbàkan gba ìhìnrere náà mọ́ra? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kíni ojúṣe wa láti gbà wọ́n sílẹ̀?

Wáìdí àwọn tó sọnù láárín ogbó, opó, àti aláìsàn náà. Nígbà púpọ̀ pẹ̀lú à ńrí wọn nínú ìyàngbẹ àti ìsọdahoro aginjù ti ìdádúró tí à ńpè ní ìdágbé. Nigbàtí ọ̀dọ́ ti lọ kúrò, nígbàtí ìlera dínkù, nígbàtí agbára ńsúnmọ́ òpin, nígbàtí ìmọ́lẹ̀ ti ìrètí tó Àwọnńjó bàìbàì nígbàgbogbo sì ṣú gidigidi, wọ́n lè ní àtìlẹhìn àti ìmúdúró nípa ọwọ́ tó ńṣèrànwọ́ àti ọkàn náà tí ó mọ àánú.

Àwọn kan wà, ní ipa ọ̀nà, àwọn míràn tí ó nílò gbígbàsílẹ̀. Àwọn kan ńjìjàkadì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ nígbàtí àwọn míràn ńṣáko nínú ẹ̀rù tàbí àìbìkítà tàbí àìmọ̀. Fún èyíkéyí ìdí, tí wọ́n fi ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò ní ṣíṣe aápọn nínú Ìjọ. Àti pé wọn yíò fẹ́rẹ̀ wà ní sísọnù dájúdájú àyàfi bí ìfẹ́ kan láti gbàlà àti láti gbanisílẹ̀ bá jídìde nínú àwa ọmọ Ìjọ tó láápọn.

Ẹnìkan láti fi ọ̀nà hàn

Ní ìgbà kan sẹ́hìn mo gba lẹ́tà tí a kọ nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti ṣáko kúrò ní Ìjọ. Ó fi àwòrán àwọn púpọ̀ jù hàn lára àwọn ọmọ ìjọ wa. Lẹ́hìn tí ó ṣe àpèjúwe bí ó ṣe di aláìláápọn, ó kọ pé.

“Mo ní ohun púpọ̀ gidi tẹ́lẹ̀ àti pé nísisìnyí mo ní ohun kékeré gidi. Inú mi kò dùn àti pé mo ní ìmọ̀ara bíí pé èmi ńkùnà nínú ohun gbogbo. Ìhìnrere náà kò fi ọkàn mi sílẹ̀ láéláé, bí ó tilẹ̀jẹ́ pé ó ti fi ayé mi sílẹ̀. Mo bèèrè fún àwọn àdúrà yín.

Jọ̀wọ́ máṣe gbàgbé àwọn wọnnì lára wa tí wọ́n wà níta níbí, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn tó sọ́nù. Mo mọ ibi tí Ìjọ wà, ṣùgbọ́n àwọn ìgbàmíràn mo lérò pé mo nílò ẹnìkan míràn láti fi ọ̀nà hàn mí, gbà mí níyànjú, mú ẹ̀rù mí kúrò, àti láti ṣe ìjẹ́rí sí mi.”

Nígbà náà tí mò ńka lẹ́tà yí, àwọn èrò mí yípadà sí ìbẹ̀wò kan tí mo ṣe sí ìkan lára àwọn ọnà ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ti àgbáyé, ti Victoria olókìkí àti Albert Museum ní London, England. Níbẹ̀, tí jígí dídára, jẹ́ olùborí iṣẹ́ kan tí a fi ọ̀dà kùn ní ọdún 1831 nípasẹ̀ Joseph Mallord William Turner. Ọ̀dà kíkùn náà jẹ́ wíwò ojú ẹrù wúwo ti ìkùkù dúdú àti ìrunú ti ìjì líle òkun kan tí ó ńfi àmi ewu kan tó ńbọ àti ikú hàn. Ìmọ́lẹ̀ kan tó jìnà kúrò níbí ọkọ̀ omi kan tí ó ti tàn ní ìtànṣán ìmọ́lẹ̀. Ní ilẹ̀ iwájú, tó ńbìsíwájú bìsẹ́hìn gíga nípa rírú omi tó ńbọ̀ níti ìfófó omi, jẹ́ ọkọ̀ ńlá kan tí a fi ńgba ènìyàn là. Àwọn arákùnrin náà fàá gidigidi ní àwọn òbèlè bí ọkọ̀ ńlá tí a nfi gba ènìyàn là náà ṣe rì sínú ìjì líle. Ní èbúté náà ni aya kan àti àwọn ọmọ méjì dúró sí, wọ́n tutù pẹ̀lú òjò àti pé a lù wọ́n nípa afẹ́fẹ́ Wọ́n ńwò pẹ̀lú àníyàn níwájú òkun. Ní inú mi mo ṣẹ́ orúkọ ti ọ̀dà kíkùn náà kù. Fún mi ó ti diLílọ gbànisílẹ̀.1

Láárín àwọn ìjì ti ayé, ewu ńlùmọ̀. Àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin, àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin ńrí ara wọn ní títàn àti dídojúkọ ìparun. Tani yíò tọ́ àwọn ọkọ̀ ńlá tí ó ńgba àwọn ènìyàn là sọ́nà, ní fífi àwọn ìtura ti ilé àti ẹbí, àti lílọ láti gbàni sílẹ̀?

Iṣẹ́ wa kìí ṣe àìlèborí. A wà ní ìránṣẹ́ ti Olúwa, a ní ẹ̀tọ́ sí ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀.

Ní àsìkò iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Olórí, Ó pe àwọn arákùnrin apẹja ní Galilee láti fi àwọn àwọ̀n wọn sílẹ̀ àti láti tẹ̀lé Òun, ní kíkéde, Èmi yíò sọ yín di àwọn apẹja ènìyàn.”2 Njẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀gbà ti àwọn apẹja ti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin, kí a lè pèsè èyíkéyí ìrànlọ́wọ́ tí a lè ṣe.

Ti wa ni ojúṣe láti nawọ́ síta láti gba àwọn tí ó ti fi ibi àìléwu ti aápọn sílẹ̀, kí a lè mú irú èyí wá sí tábìlì ti Olúwa láti ṣe àpèjẹ lórí ọ̀rọ̀ Rẹ̀, láti gbádùn ojúgbà ti Ẹ̀mí Rẹ̀, àti láti jẹ́ “ẹ̀yin kìí ṣe àlejò àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀ jẹ́ ọlọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run.”3

Ìpìlẹ̀ ti Ìfẹ́ náà

Mo ti ríi pé àwọn ìdí pàtàkì méjì ni ó ńdáhùn fún pípadà kan sí aápọn lọ́pọ̀lọpọ̀ àti fún àwọn ìyípadà ti àwọn ìwà, àwọn bárakú, àti àwọn ìṣe. Ìkínní, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ńpadà nítorí ẹnìkan ti ńfi lílèṣe ayérayé wọn hàn wọ́n àti pé wọ́n rànwọ́n lọ́wọ́ láti pinnu àti láti ṣe àṣeparí wọn. Àwọn tó láápọn kéréjù kò lè simi pẹ́ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àìbìkítà lẹ́ẹ̀kan tí wọ́n bá ríi pé àṣeyege wà ní àrọ́wọ́tó wọn.

Ìkejì, àwọn míràn padà nítorí àwọn olólùfẹ́ tàbí wọn àjùmọ̀ jẹ́ ọlọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́” ti tẹ̀lé ìkìlọ̀ ti Olùgbàlà, wọ́n ti nífẹ́ àwọn aládúgbò wọn gẹ́gẹ́bí ara wọn,4 àti pé wọ́n ti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú àwọn àlá wọn wá sí ìmúṣẹ àti ìfẹ́ agbára wọn wá sí àfojúbà.

Ẹni tó jẹ́ olùṣe ní ọ̀nà yí ti jẹ́, àti pé yíò máa wà títí láti jẹ́, ìpìlẹ̀ ti ìfẹ́ náà.

Ní òye kan tó dájú gan, àwọn ènìyàn tí ó tàn sínú ìjì òkun tó ńbìsíwájú bìsẹ́hìn níti ọ̀dà kíkùn ti Turner dàbí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó láápọn kéréjù ní àwọn ọmọ ìjọ wa tí ó ńdúró de gbígbà sílẹ̀ nípa àwọn tó ńtọ́ ọkọ̀ omi ńlá tó ńgba àwọn ènìyàn là sọ́nà. Àwọn ọkàn wọn ńṣe ìyọ́nú fún ìrànlọ́wọ́. Àwọn ìyá àti àwọn bàbá ńgbàdúrà fún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn. Àwọn aya ńbẹ̀bẹ̀ sí ọ̀run pé kí a lè nàwọ́ sí àwọn ọkọ wọn. Nígbà míràn àwọn ọmọ ńgbàdúrà fún àwọn òbí wọn.

Ó jẹ́ àdúrà mi pé kí a lè ní ìfẹ́ kan láti gba àwọn tó láápọn kéréjù sílẹ̀ àti láti mú wọn padà sí ayọ̀ ti ìhìnrere ti Jésù Krístì, pé kí wọ́n lè ṣe alábápín pẹ̀lú wa nípa gbogbo ohun tí ìdàpọ̀ kíkún níláti fifún wa.

Njẹ́ kí a nawọ́ jáde láti gbà àwọn ẹni tó sọnù tí wọ́n yíwaká: àwọn ogbó, àwọn opó, àwọn aláìsàn, àwọn to wà pẹ̀lú àwọn àìlera, àwọn tó láápọn kéréjù, àti àwọn tí kìí pa àwọn òfin mọ́. Njẹ́ kí a nawọ́ sí wọn, ọwọ́ tí ó ńṣèrànwọ́ àti ọkàn tí ó mọ àánú. Nípa ṣíṣe èyí, a ó mú ayọ̀ wá sínú ọkàn wọn, àti pé a ó ní ìrírí ọrọ̀ ìtẹ́lọ́rùn tí ó ńwá sọ́dọ̀ wa nígbàtí a bá ran ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní ọ̀nà ipá sí ìyè ayérayé.

Ìdánilẹ́kọ́ láti Iṣẹ́ Yìí

Gbèrò láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ò ńbẹ̀wò, tí wọ́n bá mọ ẹnìkankan tí ó ńtiraka láti wá sí ìjọ. O lè yan ẹnì kan, kí o sì sọ àwọn ọ̀nà tí a lè fi ìfẹ́ hàn, gẹ́gẹ́bí kí a pè ọkùnrin tàbí obìnrin láti kópa ní ìpàdé ilé ẹbí ìrọ̀lẹ́ kan tàbí láti wá fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan.

Tẹ̀