Àwọn Ọmọdé
Ṣe Àbápín Ẹ̀rí Rẹ
Ẹ lè ṣe àbápín ẹ̀bùn ti ìhìnrere ní Kérésìmesì yĩ nipa fífún ọ̀rẹ́ kan tabi aládugbo kan ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan pẹ̀lú ẹ̀rí rẹ ní kíkọ sí inú rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé awọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí lati pèsè rẹ̀ sílẹ̀:
-
Lórí ìwé pélébé kan, wọn ìlà bĩ onígunmẹ́rin kan bĩ ìwọ̀n ínshì mẹ́rin àbọ̀ sí mẹ́fà àbọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjẽjì (sẹ̀ntímítà mọ́kànlá àbọ̀ sí mẹ́rìndínlógún àbọ̀) kí o sì jẹ́ kí àgbàlagbà kan bá ọ gée jáde.
-
Fí àwòrán ara rẹ sí—yálà àfọwọ́yà kan tàbí fọ́tò — apá òkè ti ojú ewé nã.
-
Kọ ẹ̀rí rẹ sí abẹ́ àwòrán rẹ nã.
-
Jẹ́ kí àgbàlagbà kan ràn ọ́ lọ́wọ́ lati so ìwé náà mọ́ inú páálí ẹ̀hìn Ìwé ti Mọ́mọ́nì náà.