2013
The Divine Mission of Jesus Christ: The Only Begotten Son
December 2013


Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kejìlá 2013

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì Náà: Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo

Fi tàdúrà tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí o sì wákiri lati mọ ohun ti õ ṣe àbápín. Báwo ni níní òye ìgbé ayé ati iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà ṣe fikún ìgbàgbọ́ yin ninu Rẹ̀ ati bùkún awọn tí ẹ nṣe olùṣọ́ lé lórí nipasẹ̀ ìbẹniwò kíkọ́ni? Fún ìmọ̀ síi, lọ sí reliefsociety.lds.org

Àwòrán
èdìdí Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́

Ìgbàgbọ́, Ìdílé, Ìrànlọ́wọ́

Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ni a pè ní Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo nitoripé Oun nikan ni ẹni nã ni ori ilẹ̀ ayé tí a bí nipasẹ̀ ìyá kan ti kíkú ati Baba kan ti àìkú. Ó jogún awọn agbára àtọ̀runwá lati ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba Rẹ̀. Lati ọ̀dọ̀ ìyá Rẹ̀, Maria, Ó jogún kíkú a sì fi sí ipò ebi, òngbẹ, ãrẹ̀, ìrora, ati ikú.1

Nitoripé Jésù Kristì jẹ́ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba, o ṣẽṣe fun Un lati fi ayé Rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì tun gbã padà. Awọn ìwé mimọ kọ́ni pé “nipasẹ̀ ètùtù ti Krístì,” a “gba àjínde” (Jacob 4:11). A tún kọ́ bakannã pé gbogbo ẹ̀dá “le dìde ní àìkú sí inú ìyè ayérayé” bí a bá “lẽ gbàgbọ́” (D&C 29:43).

Bí a ṣe nwá sí níní òye ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sĩ nipa ohun tí ó túmọ̀ sí fun Jésù lati jẹ́ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba, ìgbágbọ́ wa nínú Kristì yío lékún sĩ, Alàgbà D. Todd Christofferson ti Àjọ awọn Apóstélì Méjìlá sọ pé, “Igbàgbọ́ ninu Jésù Krístì ni ìgbẹ́kẹ̀lé ati ìdánilójú ti (1) ipò Rẹ̀ gẹ́gẹ́bí Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Ọlọ́run, (2) Ètùtù Rẹ̀ tí kò ní òdiwọ̀n, ati (3) Àjínde òtítọ́ Rẹ̀.”2 Awọn wòlĩ òde òní ti jẹ́rĩ: “Jésù Krístì jẹ́ … Ọmọ Bibi Kanṣoṣo ninu ẹran ara, Olùràpadà ti gbogbo ayé.”3

Láti Àwọn ìwé Mímọ́

Johanu 3:16; Doctrine and Covenants 20:21–24; Moses 5:6–9

Láti Ìtàn Wa

Ninu Májẹ̀mú Titun a kà nipa awọn obìnrin, tí a dá orúkọ ati tí a kò dá orúkọ, awọn tí wọn lo ìgbàgbọ́ ninu Jésù Krístì, tí wọn kọ́ ati tí wọn sì gbé ìgbé ayé awọn ìkọ́ni Rẹ̀, tí wọn sì jẹ́rìí sí iṣẹ́ ìránṣẹ́, awọn iṣẹ́ ìyanu, ati títóbi Rẹ̀. Awọn obìnrin wọ̀nyí di alápẹrẹ rere awọn ọmọ ẹ̀hìn ati olùjẹ́rĩsí pàtàkì ninu isẹ́ ìgbàlà.

Fun àpẹrẹ, Martha jẹ́ ẹ̀rí tí ó lágbára nipa pé Olùgbàlà jẹ́ ẹni ẹ̀mí nigbati ó sọ fun Un pé, “Mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Krístì náà, Ọmọ Ọlọ́run náà, tí ó nílati wá sínú ayé” (Jòhánù 11:27).

Díẹ̀ ninu awọn ẹni ìṣãjú jùlọ olùjẹ́rĩ nipa pé Olùgbàlà jẹ́ ẹni ẹ̀mí ni iya Rẹ̀, Màríà, ati ìbátan rẹ̀ Èlísábẹ́tì. Ní kété lẹhìn ti ángẹ́lì Gabriel bẹ Màríà wò, ó ṣe àbẹ̀wò sí Èlísábẹ́tì. Ní kété tí Èlísábẹ́tì gbọ́ ìkíni Màríà, ó “kún fún Ẹ̀mí Mímọ́” (Luke 1:41) ó sì jẹ́ ẹ̀rí pé Màríà yío di ìyá sí Ọmọ Ọlọ́run náà.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Wo Gospel Principles (2009), 52–53.

  2. D. Todd Christofferson, “Kíkọ́ Igbàgbọ́ ninu Krístì,” Liahona, Sept. 2012, 13.

  3. “Krístì Alãyè Náà: Ẹ̀rí ti Awọn Àpóstélì,” Liahona, Apr. 2000, 2–3.

Tẹ̀