2013
Ìdílé ati Awọn Ọ̀rẹ́ Títí Láé
December 2013


Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kejìlá 2013

Ìdílé ati Awọn Ọ̀rẹ́ Títí Láé

Àwòrán
Olùdarí Henry B. Eyring

Ní ibikíbi tí ẹ ń gbé, ẹ ní awọn ọ̀rẹ́ tí wọn ń wá irú ayọ̀ nlá ti ẹ̀yin tí rí ninu ìgbé ayé ìhìnrere Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀ sípò. Wọ́n lè ma le ṣe àpèjúwe iru ayọ̀ náà pẹ̀lú awọn ọ̀rọ̀ sísọ, ṣùgbọ́n wọn le dã mọ̀ nigbati wọn bá ríi ninu ìgbé ayé yin. Wọn yío ní ìtara lati mọ̀ orísun ayọ̀ nã, pãpã nigbàtí wọn bá rĩ pé ẹ ń kojú awọn àdánwò gẹ́gẹ́bí awọn nã ti ṣe.

Ẹ ti ní ìmọ̀lára ìdúnnú bí ẹ ti pa awọn òfin Ọlọ́run mọ́. Èyíinì ni èso gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere tí a ṣe ìlérí rẹ̀ (rí Mosiah 2:41). Ẹ kò fi ìgbágbọ́ gbọ́ràn sí awọn òfin Olúwa kí awọn ẹlòmíran le bã ríi yin, ṣugbọn awọn ẹnití ó ba wo òye ìdùnnú yin ni a ń pèsè sílẹ̀ lati ọwọ́ Olúwa lati gbọ́ ìròhìn ayọ̀ nã ti Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere.

Awọn ìbùkún ti a ti fún yin ti ṣe àmúwá awọn ojúṣe ati awọn ànfãní àgbàyanu fun yin. Gẹ́gẹ́bĩ onímájẹ̀mú ọmọlẹ́hìn Jesu Kristi, ẹ ní ojúṣe lati ṣe ìtànká ànfãní sí ọ̀dọ̀ awọn ẹlòmíràn lati ṣe àwárí àlékún ìdùnnú, pãpã sí awọn ọ̀rẹ́ yin ati awọn mọlẹ́bí ní ìdílé yin.

Oluwa rí anfãní yin Ó sì ṣe àpéjúwe ojúṣe yin pẹ̀lú òfin yĩ: “Ó di dandan fun olukúlùkù ẹni tí a bá ti kìlọ̀ fún kí ó kìlọ̀ fún aládùgbò rẹ̀” (D&C 88:81).

Oluwa mú kí ó rọrùn lati gbọ́ràn sí òfin yi nipasẹ̀ ìyípadà tí ó mã ń wáyé ninu ọkàn yin bí ẹ ti gbà lati gbé ìgbé ayé ìhìnrere ti Jesu Kristi. Ní àyọrísí, ìfẹ́ yin si awọn ẹlòmíràn á dàgbà sĩ, bí ìwuni yin nã ti ṣe fún wọn lati ní irú ìdùnnú kannã tí ẹ̀yin ti ní ìrírí rẹ̀.

Àpẹrẹ kan ti irú ìyípadà nã ni bí ẹ ṣe ń tẹ́wọ́gba ãyè lati ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Oluwa. Awọn ìránṣẹ́ ní kíkún mã ń tètè mọ̀ pé awọn le retí èsì tí ó já gãra sí ibẽrè wọn fun ẹni lati kọ́ lati ọ̀dọ̀ ẹnití ó yípadà nítõtọ́. Ẹniti ó yípadà náà mã ń pòngbẹ fun awọn ọ̀rẹ́ ati awọn mọlẹ́bí ìdílé lati ṣe àbápín ninu ìdùnnú wọn.

Nigbati aṣíwájú iṣẹ́ ìránṣẹ́ tàbí awọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ninu ẹ̀ka yin bá bẽrè fun awọn orúkọ ẹnìkan lati kọ́, ó jẹ́ oríyìn nlá si yin. Wọn mọ̀ pé awọn ọ̀rẹ́ ti rí ìdùnnú yin ati pe, nígbànnã, awọn ọ̀rẹ́ wọ̃nnì ni a ti pèsè sílẹ̀ lati gbọ́ ati yàn lati gba ìhìnrere náà. Wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ ó jẹ ọ̀rẹ́ nã tí wọn yío nílò bí wọn ṣe mbọ̀ sínú ìjọba nã.

Ẹ kò ní lati bẹ̀rù pé ẹ ó sọ awọn ọ̀rẹ́ nù nipa pípe awọn ìránse Ọlọ́run lati bá wọn ṣe ìpàdé. Mo ní awọn ọ̀rẹ́ tí wọn kọ awọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣugbọn ti wọn dúpẹ́ lọwọ mi fún ọpọlọpọ ọdun fun fífi ohun ti wọn mọ̀ pé ó jẹ́ iyebíye sí mi lọ̀ wọn. Ẹ lè ní awọn ọ̀rẹ́ titi ayé nipa fífi ìhìnrere lọ̀, èyítí wọn ríi pé ó ti mú ìdùnnú wá fun yin. Ẹ maṣe pàdánù ànfãní kan lati pe ọ̀rẹ kan ati pãpã mọ̀lẹ́bí ìdílé kan lati yàn lati tẹ̀lé ìlànà ìdùnnú náà.

Kò sí ànfãní tí ó tóbi jùlọ fun ìpeni nã ju ninu awọn tẹ́mpìli Ijọ lọ. Níbẹ̀ Oluwa le ṣe àfifún awọn ètò ti ìgbàlà fún awọn baba nla wa tí bàbá ńlá wa tí wọn kò lè gbà nínú ayé ninu ayé. Wọn ń bojúwò yin nísàlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ati ìrètí. Oluwa ti ṣe ìlérí pé wọn yío ní ànfãní lati wá sínú ìjọba Rẹ̀ (rí D&C 137:7–8), Ó sì ti gbin ìfẹ́ kan fun wọn sínú ọ ̀kàn yin.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yin ni ẹ ti ní ìmọ̀lára ayọ̀ ninu ṣíṣe awọn ètò ti tẹmpìlì fun awọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́bí ẹ ti ṣe nigbati ẹ fi awọn orúkọ awọn eniyan fún awọn ìránṣẹ́ Ọl.ọrun lati bá ṣe ìpàdé. Ẹ tilẹ̀ ti ní ìmọ̀lára ayọ̀ tí ó ga jùlọ ní ṣíṣe awọn ètò fún awọn baba nla yin. A fi hàn sí Wòlĩ Joseph Smith pé bí a bá fi ọ̀nà sí ìbùkún náà lọ awọn baba nla wa nipasẹ̀ awọn ètò kedere inu tẹmpìlì nikan ni ìdùnnú ayérayé wa ṣẽṣe (wo D&C 128:18).

Ìgbà Kérésìmesì mã nyí awọn ọkàn wa sí Olugbala ati sí ayọ̀ tí ìhìnrere Rẹ̀ mú wá fún wa. A ń fi ìmoore wa hàn sí I dárajùlọ bí a ti ń fi ìdùnnú nã lọ fun awọn ẹlòmíràn. Ìmoore ń yí sí ayọ̀ bí a ti ń fi awọn orúkọ fun awọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ati bí a ṣe ń mú awọn orúkọ awọn baba nlá wa lọ sí tẹ́mpìlì. Ìjẹ́rĩsí ìmoore wa náà le ṣe àmúwá awọn ọ̀rẹ́ ati awọn ìdílé ti wọn yío wà títí ayé.

Ìdánilẹ́kọ́ láti Iṣẹ́ Yìí

Olùdarí Eyring ṣe àlàyé pé a lè fi ìmoore wa hàn fun Olugbàlà nipa ṣíṣe àbápín ìhìnrere pẹlú awọn ẹlòmíràn. Ẹ le jíròrò pẹlú awọn tí ẹ ń kọ́ bí ẹ̀bùn ti ìhìnrere náà ti ṣe bùkún ìgbé ayé wọn. Ẹ rò nipa pípè wọ́n lati fi tàdúrà tàdúrà ṣe àwárí awọn wọ̃nnì pẹ̀lú ẹnití yío wù wọn lati ṣe àbápín ẹ̀bùn ti ìhìnrere náà ati bawo ni wọn ti lè ṣeé.

Tẹ̀