Ogún Àìníye Kan ti Ìrètí
Nígbàtí ẹ bá yàn bóyá láti dá tàbí pa májẹ̀mú kan mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹ yàn bóyá ẹ ó fi ohun ìní kan ti ìrètí sílẹ̀ fún àwọn wọnnì tí wọ́n lè tẹ̀lé àpẹrẹ yín.
Ẹ̀yin arábìnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, díẹ lára yín gba ìpè sí ìpàdé yí nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà ìkẹhìn. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere náà lè ti pè yín láti yan dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
Àwọn míràn lára yín ńfetísílẹ̀ nítorí ẹ gba ìpè ti òbí kan, ìyàwó kan, tàbí boyá ọmọ kan, tí wọ́n nàwọ́ síi yín ní ìrètí pé ẹ̀yin yíò yàn láti mú májẹ̀mú tí ẹ ti ṣe tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run padà sínú ãrin gbùngbùn ayé yín. Díẹ̀ lára yín tí ó ńfetísílẹ̀ ti yàn tẹ́lẹ̀ láti padà láti tẹ̀lé Olùgbàlà ẹ sì ńní ìmọ̀lọ́kàn ti ayọ̀ ìkíni kú àbọ̀ Rẹ̀ lóní.
Ẹnikẹ́ni tí ó báà jẹ́ àti ibikíbi tí ó lè wà, ó mú ìdùnnú àwọn ènìyàn púpọ̀ dání ní ọwọ́ rẹ ju bí o ti lérò lọ. Ojojúmọ́ àti wákàtíwákàtí ẹ lè yàn láti dá tàbí pa májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́.
Ibikíbi tí ẹ lè wà ní ọ̀nà láti jogún ẹ̀bùn ti ìyè ayérayé, ẹ ní ànfàní láti fi ọ̀nà tí ó lọ sí ìdùnnú títóbi jùlọ hàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Nígbàtí ẹ bá yàn bóyá láti dá tàbí pa májẹ̀mú kan mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹ yàn bóyá ẹ̀yin yíò fi ohun ìní kan ti ìrètí sílẹ̀ fún àwọn wọnnì tí ó lè tẹ̀lé àpẹrẹ yín.
A ti bùkún Ìwọ àti èmi pẹ̀lú ìlérí ti irú ohun ìní kan bẹ̃. Mo jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè ti ìdùnnú mi ní ayé sí ọkùnrin kan tí èmi kò pàdé rí láéláé ní ayé ikú. Ó jẹ́ ọmọ òrukàn tí ó di ọ̀kan lára àwọn òbí mi àgbà jùlọ. Ó fi ogun àìníye ti ìrètí kan sílẹ̀ fún mi Ẹ Jẹ́ kí ńsọ díẹ̀ fún yín lára awọn ipá tí ó kó ní ṣíṣe ohun ìní nã fún mi.
Orúkọ rẹ̀ ni Heinrich Eyring A bi sínú ọlá ńlá Bàbá rẹ̀, Edward, ní ohun ìní ńlá ní Coburg, nínu èyí tí ó njẹ́ Germany nísisìyí. Ìyá rẹ̀ ni Viscountess Charlotte Von Blomberg. Bàbá rẹ̀ ni olùpamọ́ àwọn ilẹ̀ ọba ti Prussia.
Heinrich ni ọmọkùnrin àkọ́kọ́ Charlotte àti Edward. Charlotte kú ni ọjọ́ orí ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n, lẹ́hìn bíbí ọmọ rẹ̀ kẹ́ta. Edward kú láìpẹ́ lẹ́hìnnáà, nigbatí ó ti sọ gbogbo àwọn ohun ìní rẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀ nù nínú ìdókòwò tí ó kùnà. Ó jẹ́ ẹni ọjọ́ orí ogójì ọdún péré. Ó fi àwọn ọmọ òrukàn mẹ́ta sílẹ̀.
Heinrich, Bàbá Bàbá mi àgbà, ti pàdánù àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì àti ogún ìní nlá ti ayé. Kò ní owó kankan rárá. Ó kọ àkọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn rẹ̀ pé ó ní ìmọ̀lọ́kàn pé ìrètí rẹ̀ tí ó dára jùlọ wà ní lílọ sí Amẹ́ríkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ẹ̀bí tàbí ọ̀rẹ̀ rárá níbẹ̀, ó ní ìmọ̀lọ́kàn ti ìrètí nípa lílọ̀ sí Amẹ́ríkà. Ó kọ́kọ́ lọ sí Ìlú Ńlá New York. Lẹ́hìnnáà ó lọ sí St. Louis, Míssouri.
Ní St. Louis ọkan lára àwọn olùbáṣiṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ Ènìyàn Mímọ́ ọjọ́ Ìkẹhìn. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó gba ẹ̀dà ti ìwé kékeré tí a kọ nípasẹ̀ Alàgbà Parley P. Pratt. Ó kàá ó sì ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí ó lè gbà nípa àwọn Ènìyàn Mímọ́ ọjọ́ Ìkẹhìn. Ó gbàdúrà láti mọ̀ bóyá àwọn áńgẹ́lì wà nítòótọ́ tí ó ńfarahàn sí àwọn ènìyàn, bóyá wòlíì alààyè kan wà, àti pé bóyá ó ti rí èsìn òtítọ́ kan ti a fi hàn.
Lẹ́hìn oṣù méjì ti fífi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣe àṣàrò àti àdúrà, Heinrich lá àlá kan nínú èyí tí a ti sọ fun pé òun yíò ṣe ìrìbọmi. Ọkùnrin kan orúkọ àti oyè àlùfáà ẹnití mo dìmú ní ìrántí mímọ́, Alàgbà William Brown, ni ó níláti ṣe ìlànà náà. Heinrich ṣe ìrìbọmi nínú adágún omi òjò kan ní oṣù kẹ́ta ọjọ́ kọkànlá, ọdún 1855, ní aago méje àbọ̀ ní àárọ̀.
Mo gbàgbọ́ pé Heinrich Eyring mọ̀ nígbà náà pé ohun tí mò ńkọ́ yín lóní jẹ́ òtítọ́. Ó mọ̀ pé ìdùnnú ti iyè ayérayé ńwá nípa àwọn ìsopọ̀ ẹbí èyítí ó ńtẹ̀síwájú títí láé. Àní nígbàtí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ètò ti ìdùnnú Olúwa, ó mọ̀ pé ìrètí rẹ̀ fún àyọ̀ ayérayé gbáralé àwọn àṣàyàn àtinúwá ti àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀lé àpẹrẹ rẹ̀. Ìrètí ayọ̀ ayérayé rẹ̀ gbáralé àwọn ènìyàn tí a kò tíì bí
Gẹ́gẹ́bí apákan ti ogún ìrètí ẹbí wa, ó fi ìtàn kan sílẹ̀ fún àwọn àtẹ̀lé rẹ̀.
Nínú ìtàn náà mo lè ní ìmọ̀lọ́kàn ìfẹ́ rẹ̀ fún àwa wọnnì tí yíò tẹ̀lé e. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mo ní ìmọ̀lọ́kàn ìrètí rẹ̀ pé àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ lè yàn láti tẹ̀lé e ní ipa ọ̀nà náà láti padà sí ilé wa ọ̀run. Ó mọ̀ pé kò ní jẹ́ àṣàyàn ńlá kan ni láti yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn àṣàyàn kékèèké. Mo ṣe àtúnsọ láti inú ìtàn rẹ̀:
“Láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ gbọ́ tí Alàgbà Andrus sọ̀rọ̀ … mo ti ńfi ìgbà gbogbo wá sí ìpàdé ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ọjọ́ Ìkẹhìn àti pé àwọn àkókò náà ṣọ̀wọ́n gidigidi nítòótọ́, tí mo [ti] ní ìjákulẹ̀ láti lọ sí ìpàdé, èyítí ó jẹ́ ojúṣe mi láti ṣe bẹ́ẹ̀ bákannáà.
“Mo kọ orúkọ̀ yí nínú ìwé ìtàn mi kí àwọn ọmọ mi lè ṣe àfarawé àpẹrẹ mi kí wọ́n má sì ṣe fi ojúṣe pàtàkì yí … sílẹ̀ láéláé [láti kórajọ] pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́.”1
Heinrich mọ̀ pé ní àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa a lè ṣe àtúnṣe ìlérí wa láti rántí Olùgbàlà nígbà gbogbo àti pé kí a le ní Ẹ̀mí Rẹ̀ pẹ̀lú wa.
Ẹ̀mí náà ni ó mú u dúró ní míṣọ̀n náà èyí tí a pèé sí ní àwọn oṣù díẹ̀ lẹ́hìn tí ó ti gba májẹ̀mú ìrìbọmi. Ó fi ogún rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ rẹ̀ ní dídúró nítòótọ́ sí míṣọ̀n rẹ̀ fún ọdún mẹ́fà ní ibi tí wọ́n ńpè ní agbègbè ilẹ̀ Indian nígbà náà. Láti gba ìdásílẹ̀ rẹ̀ kúrò ní míṣọ̀n rẹ̀, ó rìn láti Oklahoma lọ sí Ìlú Ńlá Salt Lake, ọ̀nà jíjìn kan tí ó súnmọ́ ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́ọ̀rún máìlì (1,770 kilómítà).
Láìpẹ́ lẹ́hìn náà wòlíì Ọlọ́run pèé kí ó lọ̀ sí apá àríwá Utah. Láti ibẹ̀ ó dáhùn ìpè míràn láti sin ní míṣọ̀n kan ní ilẹ̀ àbínibí rẹ̀ Germany. Nígbànáà ó gba ìfipè ti Àpọ́stélì Olúwa Jésù Krístì láti ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn ìlú àwọn ènìyàn mímọ́ tí a tẹ̀dó sí gúsù Mexico. Láti ibẹ̀ wọ́n pè é sí Ìlú Ńlá Mexico gẹ́gẹ́bíi oníṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ìgbà kíkún kan lẹ́ẹ̀kansíi. Ó bu ìyìn fún àwọn ìpè wọ̀nyì Ó sùn ní sísin sí ibojì kékeré kan ní Colonia Juarez, Chihuahua, Mexico.
Mo fòye ka àwọn òtítọ́ wọ̀nyí kìí ṣe láti gba ipò ńlá fún un tàbí fún ohun tí ó ṣe tàbí fún àwọn àtẹ̀lé rẹ̀. Mo fòye ka àwọn òtítọ́ wọnnì láti bu ìyìn fún un fún àpẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìrètí tí ó wà nínú ọkàn rẹ.
Ó gba àwọn ìpè wọnnì nítorí ti ìgbàgbọ́ rẹ̀ pé Krístì àjíìnde àti Bàbá wa Ọ̀run ti farahàn sí Joseph Smith nínú aginjù igi ní ìpínlẹ̀ ti New York. Ó gbà wọ́n nítorí ó ní ìgbàgbọ́ pé àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà ní ìjọ Olúwa ti padàbọ̀sípò pẹ̀lú agbára láti di àwọn ẹbí papọ̀ títí láé, tí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ tí ó tó nìkan láti pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́.
Bíiti Heinrich Eyring, bàbáńlá mi, o lè jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ẹbí rẹ láti darí ọ̀nà náà sí ìyè ayérayé ní ẹ̀gbẹ́ ipa ọ̀nà àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí a dá tí a sì pamọ́ pẹ̀lú aápọn àti ìgbàgbọ́. Ìkọ̀ọ̀kan májẹ̀mú ńmú àwọn ìlérí àti ojúṣe wá pẹ̀lú rẹ̀. Fún gbogbo wa, bí wọ́n ti wà fún Heinrich, àwọn ojúṣe náà nígbàmíràn máà ńrọrùn ṣùgbọ́n wọ́n máa ńṣòro nígbàkugbà. Ṣùgbọ́n rántí, àwọn ojúṣe náà gbọ́dọ̀ ṣòro nígbàmíràn nítorí èrò wọn ni láti gbé wa lọ ní ipa ọ̀nà láti gbé títíláé pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run àti Ọmọkùnrin Àyànfẹ́ Rẹ̀, Jésù Krístì, nínú àwọn ẹbí.
Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ láti inú ìwé ti Ábráhámù:
“Àti pé ọ̀kan dúró láárín wọn tí ó dàbí Ọlọ́run, ó sì sọ fún àwọn wọnnì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: A ó lọ sí ìsàlẹ̀, nítorí àyè wà níbẹ̀, a ó sì mú nínú àwọn ohun èlò wọ̀nyí, a ó sì ṣe ayé kan níbití àwọn wọ̀nyí lè gbé;
“A ó sì dán wọn wò ní báyí,” láti ríi bóyá wọn yíó ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíó paláṣẹ fún wọn.”
“Àti pé àwọn tí ó bá pa ohun ìní wọn àkọ́kọ́ mọ́ yíò ní àfikún lórí wọn; àwọn tí kò bá sì pa ohun ìní wọn àkọ́kọ́ wọn mọ́ kì yíò ní ògo nínú ìjọba kannáà pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ó pa ohun ìní àkọ́kọ́ wọn mọ́; àti pé àwọn tí ó pa ohun ìní wọn kejì mọ́ yíò ní àfikún ògo lórí wọn títíláé àti láéláé.”2
Pípa ohun ìní wa kejì mọ́ dá lórí dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti fífi ìgbàgbọ́ ṣe àwọn ojúṣe tí wọ́n fẹ́ lati ọ́dọ̀ wa. Ó gba ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà wa láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ fún gbogbo ọjọ́ ayé.
Nítorípé Ádámù àti Éfà ṣubú, a ní àdánwò, ìpọ́njú, àti ikú gẹ́gẹ́bí ogún gbogbo wa. Bí ó ti lẹ̀ rí bẹ̃, Bàbá wa Ọ̀run onífẹ̃ fún wa ní ẹ̀bùn ti Ọmọkùnrin Àyànfẹ́ rẹ̀, Jésù Krístì, gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà wa. Ẹ̀bùn ńlá náà àti ìbùkún ti Ètùtù ti Jésù Krístì ńṣe àmúwá ogún ìní gbogbo ènìyàn: ìlérí ti Àjíìnde náà àti ṣíṣeéṣé ti ìyè ayérayé sí gbogbo àwọn tí a bí.
Èyí tí ó tóbi jùlọ ninu gbogbo àwọn ìbùkún Ọlọ́run, ìyè ayérayé, yíò wá fún wá sí ọ̀dọ̀ wa nikan bí a bá ṣe ndá àwọn májẹ̀mú tí a filélẹ̀ ní ìjọ ti Jésù Krístì tòótọ́ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí a fún ní àṣẹ. Nítorí ti ìṣubú, gbogbo wa nílò ìwẹ̀nùmọ́ àwọn èrè ti ìrìbọmi àti gbígbé ọwọ́ lérí láti gba ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn ìlànà wọ́nyí ni a gbọ́dọ̀ ṣe nípasẹ̀ àwọn tí ó ní àṣẹ oyè àlùfáà dáradára. Nígbànáà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìmọ́lẹ̀ ti Krístì àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, a lè pa gbogbo àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, ní pàtàkì àwọn tí a fi lélẹ̀ nínú àwọn tẹ́mpìlì Rẹ̀. Ọ̀nà náà nìkan, àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ náà, ni ẹnikẹ́ni ṣe lè gba ẹ̀tọ́ ogún rẹ̀ gẹ́gẹ́bí arákùnrin tàbí arábìnrin ọmọ ti Ọlọ́run nínú ẹbí kan títí láé.
Sí díẹ̀ nínú àwọn tí wọ́n ńfi etí sílẹ̀ sí mi, tí ó lè dàbí àlá kan tí kò ní ìrètí.
Ẹ ti rĩ tí àwọn onígbàgbọ́ òbí tí wọ́n ní ìbànújẹ́ lórí àwọn ọmọ tí ó kọ̀ tàbí yàn láti já àwọn májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n àwọn òbí wọnnì lè dá ọkàn le kí wọ́n sì ní ìrètí láti inú àwọn ìrírí òbí míràn.
Ọmọkùnrin Álmà àti àwọn ọmọkùnrin Ọba Mòsíàh padà kúrò nínú ìṣọ̀tẹ̀ líle ní ìlòdì sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn òfin ti Ọlọ́run. Álmà Kékeré náà rí tí ọmọkùnrin rẹ̀ Kọ́ríántọ́nù yípadà kúrò nínú gbogbo ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́. Bakannã, Ìwé ti Mọ́rmọ́nì ṣe àkọsílẹ̀ ìyanu ti àwọn Lámánáítì tí wọ́n gbé àwọn àṣà kíkórira òdodo sí ẹ̀gbẹ́ kan ti wọ́n sì dá májẹ̀mú láti kú láti di àláfíà mú.
A rán ángẹ́lì kan sí Álmà kékeré àti àwọn ọmọkùnrin Mòsíàh. Ángẹ́lì nã wá nítorí ìgbàgbọ́ àti àwọn àdúrà ti àwọn bàbá wọn àti ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Láti inú àwọn àpẹrẹ wọ̃nnì ti agbára Ètùtù tí ó ńṣiṣẹ́ nínú àwọn ọkàn ẹ̀dá, ẹ lè gba ìgboyà àti ìtùnú.
Olúwa ti fún gbogbo wa ní gbogbo orísun ìrètí bí a ṣe ńgbìyànjú láti ran àwọn tí a fẹ́ràn lọ́wọ́ láti gba ogún ayérayé wọn. Ó ti ṣe àwọn ìlérí fún wa bí a ṣe ńgbìyànjú síi láti kó àwọn ènìyàn jọ sí ọ́dọ̀ Rẹ̀, àní nígbàtí wọ́n kọ ìpè Rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìtakò wọn ńbà Á nínújẹ́, ṣùgbọ́n Òun kò fi sílẹ̀, àwa náà kò gbọ́dọ̀ fi sílẹ̀. Ó ṣe àgbékalẹ̀ àpẹrẹ pípé fún wa pẹ̀lú ìforítì ìfẹ́ Rẹ̀: “Àti pé lẹ́ẹ̀kan síi, nígbàkugbà báwo ni èmí ìbá ti kó o yín jọ gẹ́gẹ́bí àdìyẹ ṣe ńkó àwọn òròmọ rẹ̀ jọ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, Áà ẹ̀yin ènìyàn ti ilé Ísráẹ́lì, tí o ti ṣubú lulẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, Áà ẹ̀yin ènìyàn ti ilé Ísráẹ́lì, ẹ̀yin tí ẹ̀ ńgbé ní Jérúsálẹ́mù, bí ẹ ṣe ṣubú lulẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, nígbàkugbà báwo ni èmí ìbá ti kó o yín jọ gẹ́gẹ́bí àdìyẹ ṣe ńkó àwọn òròmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, tí ẹ̀yin kò jẹ́.”3
A lè gbé ọ́kàn lé ìfẹ́ Olùgbàlà tí kò ní ikùnà láti mú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Bàbá Ọ̀run padà sí ilé wọn pẹ̀lúu Rẹ̀. Gbogbo onígbàgbọ́ òbí, òbí àgbà, àti òbĩ-òbí àgbà ṣe àbápín nínú ìwuni nã. Bàbá Ọ̀run àti Olùgbàlà jẹ́ àpẹrẹ pípé ti ohun ti a lè àti ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe. Wọ́n kò fi ipá mú òdodo láéláé nítorípé a gbọ́dọ̀ yàn òdodo ni. Wọ́n mú wa mọ ìyàtọ̀ òdodo, wọ́n sì jẹ́ kí a ríi pé èso rẹ̀ jẹ́ aládùn.
Gbogbo ẹ̀ni tí a bí sínú ayé gba Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì, èyí tí ó ńràn wá lọ́wọ́ láti rí àti láti ní ìmọ̀lọ́kàn ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó jẹ́ àṣìṣe. Ọlọ́run ti rán àwọn ìrànṣẹ́ ti ara ikú tí ó lè, nípa Ẹ̀mí Mímọ́, ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Òun yíò fẹ́ kí á ṣe àti ohun tí Òun kà léèwọ̀. Ọlọ́run ńmu wuni láti yan tí ó tọ́ nípa jíjẹ́ kí a ní ìmọ̀lọ́kàn àwọn èrè ti àwọn àṣàyàn wa. Bí a bá yan èyí tí ó tọ́, a ó rí ìdùnnú —ní àsìkò. Bí a bá yan ibi, ìbànújẹ́ àti àbámọ̀ ńwá—ní àsìkò. Àwọn èrè wọnnì dájú Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n máa ń ní ìdádúró léraléra fún ìdí kan Bí àwọn ìbùkún bá wà lọ́gán, yíyan òtítọ́ kò ní mú ìgbàgbọ́ dàgbà. Àti nítorípé ìbànújẹ́ bákannáà nígbàmíràn máa ńní ìdádúró ńlá, ó ń gba ìgbàgbọ́ láti ní ìmọ̀lọ́kàn nínílò láti wá ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ dípò ìgbẹ̀hìn lẹ́hìn tí a ti ní ìmọ̀lọ́kàn èrè bíbanújẹ́ àti àwọn ìrora rẹ̀.
Bàbá Léhì banújẹ́ lórí àwọn àṣàyàn tí díẹ̀ lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe àti àwọn ẹbí wọn. Ó jẹ́ ẹni ńlá àti ẹni dáradára ni—wòlíì Ọlọ́run kan. Ó máa ńfi ìgbà gbogbo ṣe ìjẹ́rĩ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, sí wọn. Ó jẹ́ àpẹrẹ ti ìgbọ́ran kan àti iṣẹ́ ìsìn nígbàtí Olúwa pèé láti fi gbogbo ohun ìní ayé sílẹ̀ láti gba ẹbí rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ìparun. Ní ìparí ìgbé ayé rẹ̀ gangan, ó ṣì ńjẹ́rí sí àwọn ọmọ rẹ̀. Bíi ti Olùgbàlà — àti pé ní kíka agbára rẹ̀ láti mọ̀ ọkàn wọn yàtọ̀ sí àti láti rí ìkorò àti ìyanu ọjọ́ iwájú — Léhì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti fa àwọn ẹbí rẹ̀ mọ́ra síhá ìgbàlà.
Lóní ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn àtẹ̀lé Bàbá Léhì ńṣe ìdáláre ìrètí rẹ̀ fún wọ́n.
Kíni ẹyin àti èmi lè ṣe láti múlò nínú àpẹrẹ ti Léhì? A lè ṣe ìmúlò nínú àpẹrẹ rẹ̀ nípa ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ́ tàdúràtàdúrà àti nípa àfojúsí.
Mo dábá pé kí ẹ mú ìwò méjèèjì kúkurú àti gígùn bí ẹ ṣe ńgbìyànjú láti fi ogún ìrètí fún ẹbí rẹ. Ní àkókò kúkurú, wàhálà yíò wà àti pé Sátánì yíò bú ramúramù. Àwọn ohun tí a níláti dúró fún pẹ̀lú sùúrù wà, nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé Ọlúwa ńṣiṣẹ́ ní àsìkò ti ara Rẹ̀ àti ní ọ̀nà ti ara Rẹ̀.
Àwọn ohun tí ẹ lè tètè ṣe wà, nígbàtí àwọn tí ẹ nífẹ́ ṣì wà ní ọ̀dọ́. Ẹ rántí pé àdúrà ẹbí ojojúmọ́, àṣàrò ìwé mímọ́ ẹbí, àti àbápín ẹ̀rí wa nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa mã ńrọ̀rùn síi ó sì nmúna doko síi nígbàtí àwọn ọmọ bá wà ní ọ̀dọ́. Àwọn ọ̀dọ́mọdé máa ńfìgbàpúpọ̀ ní ìfura sí Ẹ̀mí ju bí a ṣe mọ̀.
Nígbàtí wọ́n bá dàgbà, wọn yíò rántí àwọn orin mímọ́ tí wọ́n kọ pẹ̀lú yin. Àní ju rírántí orin lọ, wọn yíò ránti àwọn ọ̀rọ̀ ti ìwé mímọ́ àti ẹ̀rí. Ẹ̀mí Mímọ́ náà lè mú gbogbo ohun wá sí ìrántí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ àti àwọn ọrin yíò dúró pẹ́ títí. Àwọn ìrántí wọnnì yíò mú agbára tí ó lè mú wọn padà wá nígbàtí wọ́n bá ṣáko lọ fún àsìkò kan, ó ṣeéṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kúrò ní ojú ọnà ilé sí ìyè ayérayé.
A ó nílò ìwò gígùn nígbàtí àwọn tí a nífẹ́ bá ní ìmọ̀lọ́kàn ònfà ti ayé àti pé tí ìkuùkù iyèméjì dàbíi pé ó bo ìgbàgbọ́ wọn mọ́lẹ̀. Àwa ní ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ láti darí wa àti láti fún wọn lókun.
Mo ti ríi pé gẹ́gẹ́bí olùdámọ̀ràn kan sí àwọn wòlíì alààyè méjì ti Ọlọ́run. Wọ́n jẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àṣàyàn irú ènìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀ ó dàbíí pé wọ́n ńṣe àbápín ìdúró ìgbàgbọ́ ohun gbogbo fún rere. Nígbàtí ẹnìkan bá gbé ìdágìrì sókè nípa ohun kan nínú Ìjọ, àwọn ìdáhùn wọn lemọ́lemọ́ jù ni “Áà, àwọn nkan yíò ṣeéṣe.” Lákópọ̀ wọ́n mọ̀ púpọ̀ nípa wàhálà náà ju awọn ènìyàn tí wọ́n ńṣe ìró ìdágìrì lọ.
Bákannáà wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa, wọ́n sì ńfì ìgbà gbogbo ní ìrètí nípa ìjọba Rẹ̀. Wọ́n mọ pé Òun wà ní orí rẹ̀. Òun ni gbogbo agbára Ó sì ńṣè ìtọ́jú. Bí o bá jẹ́ kí Ó jẹ́ olórí ẹbí rẹ, àwọn nkan yíò ṣeéṣe.
Díẹ̀ lára àwọn àtẹ̀lé Heinrich Eyring ti dàbí pé wọ́n ṣáko lọ. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ rẹ̀ lọ sí àwọn tẹ́mpìlì ti Ọlọ́run ní aago mẹ́fà àárọ̀ láti ṣe àwọn ìlànà fún àwọn bàbá ńlá tí wọn kò rí rí láéláé. Wọ́n lọ jáde kúrò nínú ìjogún ti ìrètí tí ó fi sílẹ̀. Ó fi ogún kan sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ńgbàmọ́ra.
Lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe nínú ìgbàgbọ́, Olúwa yíò fi àwọn ìbùkún tí ó pọ̀ jù bí a ṣe lérò lọ fún àwọn ẹbí wa nípa ìrètí wa. Ó ńfẹ́ ohun tí ó dára jùlọ fún wọn àti fún wa, gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ Rẹ̀
Gbogbo wa ni ọmọ Ọlọ́run alààyè kan. Jésù ti Násárẹ́tì ní Olólùfẹ́ Ọmọkùnrin Rẹ̀ àti Olùgbàlà wa tí ó jíìnde. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Nínú rẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ti oyè àlùfáà wa, àti pé nítorínáà àwọn ẹbí lè wà títí láéláé Èyí ní ìjogún àìdíyelé ti ìrètí wa. Mo jẹ́rí pé ó jẹ́ òtítọ́ ní orúkọ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.
© 2014 Nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. Printed in USA. English approval: 6/13. Translation approval: 6/13. Ìtumọ̀ ti Visiting Teaching Message, May 2014. Yoruba. 10865 779