Ìfẹ́—Ni Àkójá Ìhìnrere
A kò lè fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́ bí a kò bá fẹ́ràn àwọn arìnrìnàjò ẹlẹgbẹ́ wa nínú ìrìnàjò ayé ikú yí.
Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàtí Olùgbàlà ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láárín àwọn ènìyàn, agbẹjọ́rò olùbèèrè náà bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀, “Olùkọ́ni, èwo ni àṣẹ ńlá nínú òfin?”
Máttéù ṣe àkọsílẹ̀ pé Jésù dáhùn:
“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
“Èyí ni èkínní àti òfin ńlá.
“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ yíò fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”1
Márkù parí ìròhìn náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ti Olùgbàlà: “kò sí òfin míràn tí ó ga ju èyí.”2
A kò lè fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́ bí a kò bá fẹ́ràn àwọn arìnrìnajo ẹlẹgbẹ́ wa nínu ayé ikú yí. Bákannáà, a kò lè fẹ́ràn àwọn ọmọnìkejì wa ní kíkún bí a kò bá fẹ́ràn Ọlọ́run, Bàbá gbogbo wa. Àpọ́stélì Jòhánù sọ fún wa pé, “Òfin yí ni àwa ní lati ọwọ́ rẹ̀ wá, Pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọ́run kí ó fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.”3 Gbogbo wa jẹ́ ọmọ ẹ̀mí ti Bàbá wa Ọ̀run àti pé, nítorí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin ara wa. Bí a ṣe ńpa òtítọ́ yí mọ́ nínú wa, fífẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run yíò rọrùn sĩ.
Nítòótọ́, ìfẹ́ gan ni àkója ìhìnrere, àti pé Jésù Krístì ni Alápẹrẹ wa. Ìgbésí ayé Rẹ̀ jẹ́ ogún ti ìfẹ́. Ó wo aláìsàn sàn, Ó gbé ẹni tí a tẹ̀mọ́lẹ̀ sókè, Ó gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Ní ìparí, àgbájọ awọn ènìyàn tí wọ́n ńbínú gba ẹ̀mí Rẹ̀. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ńdún láti òkè Gọ́lgọ́tà: “Bàbá, dáríjì wọ́n; nítorítí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ńṣe”4— ìsọ̀rọ̀ tí ó dé ohun gbogbo ní adé ní ayé ti ikú àánú àti ìfẹ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ní ó wà èyí tí ó jẹ́ àwọn ìfarahàn ti ìfẹ́, bí irú ìwà rere, sũrù, àìmọtaraẹni nìkan, níní òye, àti ìdáríjì. Nínú gbogbo ìbálòpọ̀ wa, ìwọ̀nyí àti awọn ìwà míràn bíi wọn yíò ṣèrànwọ́ láti fi ìfẹ́ hàn ní ọkàn wa.
Bíi ti àtẹ̀hìnwá ìfẹ́ wa yíò farahàn nínú àwọn ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ara wa ní ojojúmọ́. Pàtàkì jùlọ ni ipá wa láti kíyèsí àìní ẹnìkan ati lẹ́hìnnã kí a sì ṣe ohun tó yẹ. Mo ti fìgbà gbogbo ṣìkẹ́ ti dídájọ́ ìsọ̀rọ̀ nínú ewì kúkurú náà:
Mo ti sọkún lálẹ́
Fún ti kúkúrú ìran rírí náà
Pé sí àìní ẹnìkan ó mú mi fọ́jú
Ṣùgbọ́n èmi kò tíì ní
Ìmọ̀lára àbámọ̀ tíntín
Fún jíjẹ́ onínú rere díẹ̀ jù.5
Láìpẹ́ yĩ mo gbọ́ nípa àpẹrẹ tí ó mú ni lọ́kàn nípa ìfẹ́ inúrere — ọ̀kan tí ó ní àbájáde àìlèrí. Ọdún náà ni 1933, nígbàtí ó jẹ́ pé nítorí Ìyàn Ńlá, ànfàní ìgbanisíṣẹ́ ṣọ̀wọ́n gidigidi. Ibùdó náà ni apá ìwọ̀ oòrùn ní United States. Arlene Biesecker ṣẹ̀ṣẹ̀ gboyè kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga. Lẹ́hìn ìwáṣẹ́ kiri pípẹ́, nígbẹ̀hìn ó wá rí iṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ aṣọ ṣíṣe gẹ́gẹ́bí aránṣọ. Wọ́n ńsanwó fún àwọn òṣìṣẹ́ náà fún ìkọ̀ọ̀kan ìrépé aṣọ tí wọ́n rán papọ̀ tán dáradára lójojúmọ́. Bí àwọn ìrépé tí wọ́n ṣe bá ṣe pọ̀ sí, ni owó tí wọ́n ńgbà.
Ní ọjọ́ kan ní kété lẹ́hìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ibi iṣẹ́ náà, Arlene ní ìdojukọ pẹ̀lú ìṣẹ̀tò kan tí ó dàá nínú rú tí ó sì ní ìbàjẹ́ ọkàn. Ó jókó ti ẹ̀rọ ìránṣọ rẹ̀ ó ńgbìyànjú láti yọ òwú ìrépé aṣọ èyí tí ó ńṣiṣẹ́ lé lórí tí kò lè ṣetán. Ó dàbíi pé kò sí ẹni tí ó lè ràn án lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn aránṣọ míràn ńyára láti parí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrépé tí wọ́n bá lè ṣe. Arlene ní ìmọ̀lọkan àìnírànlọ́wọ́ àti àìnírètí. Ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ńsọkún.
Ní òdìkejì ibi tí Arlene jókó sí ni Bernice Rock wà. Ó dàgbà jù ú ó sì ní ìrírí jù ú gẹ́gẹ́bí obìnrin aránṣọ. Ó ṣe àkíyèsí ìbànújẹ́ Arlene, Benice fi iṣẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀ ó sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ Arlene, ó ńfi inúrere fún un ní àṣẹ àti ìrànlọ́wọ́. Ó dúró títí Arlene fi ní ìgboyà tí ó sì le ṣe iṣẹ́ ìrépé náà parí. Nígbànáà Bernice padà lọ sí ibi ẹ̀rọ iṣẹ́ tirẹ̀, nígbàtí ó jẹ́ wípé ó ti sọ ànfàní láti parí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrépé tí òun ìbá lè parí nù, bí òun kò bá lọ ràn án lọ́wọ́.
Pẹ̀lú ṣíṣe ìfẹ́ inúrere kan yí, Bernice àti Arlene di ọ̀rẹ́ títí ayé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe ìgbéyàwó nígbẹ̀hìn wọ́n sì ní àwọn ọmọ. Nígbà kan ní àwọn ọdún 1950, Bernice, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Ìjọ, fún Arlene àti ẹbí rẹ̀ ní ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan. Ní ọdún 1960, Arlene àti ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ di ọmọ Ìjọ́ náà ti a ṣe ìrìbọmi fún. Lẹ́hìnnáà a so wọ́n pọ̀ ní tẹ́mpìlì mímọ́ ti Ọlọ́run.
Gẹ́gẹ́bí àbájáde àánú tí Bernice fihàn bí ó ti ni ara rẹ̀ lára láti ran ẹnìkan tí kò mọ̀ rí lọ́wọ́ ṣùgbọ́n ẹnití ó wà nínú ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó sì nílò àtìlẹhìn, àìmọye àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn alààyè àti òkú pẹ̀lú, ni wọ́n ńgbádùn àwọn ìlànà ìgbàlà ti ìhìnrere nísisìyí.
Ní ojojúmọ́ ìgbésí ayé wa a fún wa ní awọn ànfàní láti fi ìfẹ́ àti inúrere hàn sí àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa. Alákóso Spencer W. Kimball sọ pé: “A gbọ́dọ̀ rántí pé àwọn ẹlẹ́ran ara tí à ńpadé ní ibi ìgbé ọkọ̀ sí, ilé iṣẹ́, ẹ̀rọ ìgbénisókè, àti ibòmíràn jẹ́ apákan àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run fún wa láti fẹ́ràn àti láti sìn. Yíò ṣe wá ní rere díẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ́ arákùnrin gbogbogbò ti àwọn ènìyàn bí a kò bá kà àwọn wọnnì tí ó wà ní àyíká wa sí bí arákùnrin àti arábìnrin wa.6
Nígbàkugbà àwọn ànfàní wa mã ńwá láìròtẹ́lẹ̀ láti fi ìfẹ́ wa hàn. Àpẹrẹ kan ti irú ànfàní náà jáde nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìròhìn ní oṣù kẹ́wá ọdún 1981. Mo ní ìtẹ̀mọ́ra gidi pẹ̀lú ìfẹ́ àti àánú tí ó báramu níbẹ̀ tí mo sì ti fi àwọn ìròhìn náà pamọ́ nínú àwọn àpò ìwé mi fún ọgbọ̀n ọdún ó lé.
Àtẹ̀jáde náà sọ nipa ọkọ̀ òfúrufú kan tí ó jẹ́ ti ilé iṣẹ́ Alaska Airlines tí kĩ dúró láti inú ìdákọ̀ró ní Anchorage, Alaska sí Seattle, Washington — ọkọ̀ òfúrufú tí ó ńgbé igba ó dín àádọ́ta èrò — ló yà bàrà sí ìlú kan ní Alaska tí ó jìnnà láti lè gbé ọmọde kan tí ó ṣèṣe púpọ̀. Ọmọdékùnrin ẹni ọdún méjì nã ti já iṣan ẹ̀jẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ nígbàtí ó ṣubú lórí èérún àwo nígbàtí ó ńṣeré nítosí ilé rẹ̀. Ìlú náà jẹ́ máìlì ọgọ́rún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (725 kilómítà) ní gũsù Anchorage tí kò sì sí ní ipa ọ̀nà ọkọ̀ òfúrufú náà dájúdájú. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn oníṣègùn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti rán ìwọ̀nwọnra ìbèèrè jáde fún ìrànlọ́wọ́, nítorínáà ọkọ̀ òfúrufú nã yà bàrà lọ láti gbé ọmọ náà sókè àti láti gbe lọ sí Seattle kí ó lè gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn.
Nígbàtí ọkọ̀ òfúrufú nã balẹ̀ nítòsí ìlú jijìnna náà, àwọn oníṣègùn sọ fún atúkọ̀ pé ọmọdékùnrin náà ńṣẹ̀jẹ̀ burúkúburúkú kò sì lè yè nínú ọkọ̀ òfúrufú náà dé Seattle. Wọ́n ṣe ìpinnu kan láti fo fún igba máìlì (320 kilómítà) kúrò lọ́nà wọn lọ sí Juneau, Alaska, ìlú ńlá tí ó súnmọ́ jùlọ tí ó ní ilé ìwòsàn.
Lẹ́hìn tí wọ́n ti gbé ọmọdékùnrin náà lọ sí Juneau, ọkọ̀ òfúrufú fi orí lé Seattle, nisisìyí lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tí ó ti yẹ kí wọ́n dé ibẹ̀. Kò sí èrò kankan tí ó ráhùn, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ jù lára wọn yíò pàdánù ìpàdé tí wọ́n ní àti àwọn ìsopọ̀ ọkọ̀ òfúrufú. Nítòótọ́, bí àwọn ìṣẹ́jú àti wákàtí ṣe ńlọ, wọ́n gba owó, wọ́n sì kó owó tí ó pọ̀ jọ fún ọmọdékùnrin náà àti ẹbí rẹ̀.
Bí ọkọ̀ òfúrufú náà ṣe fẹ́ balẹ̀ ní Seattle àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ńdunnú nígbàtí atúkọ̀ kéde pé òun ti gba ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì pé ọmọdékùnrin náà yíó rũ là.7
Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé mímọ́ wá sí ọkàn mi: “Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni ìfẹ́ Krístì tí kò ní àbàwọ́n, …ẹnìkẹ́ni tí a bá sì rí tí ó níi ní ọjọ́ ìkẹhìn, yíò dára fún un”8
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, díẹ̀ lára àwọn ànfàní wa tí ó tóbi jùlọ láti fi ìfẹ́ wa hàn yío jẹ́ lãrin ògiri ínú ilé ara wa. Ìfẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkàn ti ìgbésí ayé ẹbí gan an, àti pé nígbà míràn kìí rí bẹ́ẹ̀. Àìní sùúrù púpọ̀jù lè wà, àríyànjiyàn púpọ̀ jù, ìjà púpọ̀ jù, omijé púpọ̀ jù. Alákóso Gordon B. Hinkley pohùnréré: Kíni ìdí tí àwọn [wọnnì] tí a ní ìfẹ́ sí [jù lọ] fi máa ńjẹ́ àwọn ti ndojú àwọn ọ̀rọ̀ líle wa kọ? Kíni ìdí tí a fi máa ńfì ìgbà míràn sọ̀rọ̀ bíì pé a ńsọọ́ pẹ̀lú ọ̀bẹ tí ó lè gé nkan kíákíá?”9 àwọn ìdáhùn sí ìbèèrè wọ̀nyí lè yàtọ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa, àti pé síbẹ̀síbẹ̀ òkodoro rẹ̀ ní pé àwọn ìdí náà kò jẹ́ nkan. Bí awa ó bá pa òfin láti fẹ́ràn ara wa mọ́, a gbọ́dọ̀ tọ́jú ara wa pẹ̀lú inúrere ati ìtẹríba.
Dájúdájú àwọn ìgbà míràn yíò wà nígbàtí a nílati lo ìbáwí. Bí o tilẹ̀ rí bẹ̃, ẹ jẹ́ kí a rántí, ìmọ̀ràn tí a rí nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú — tí a dárúkọ, pé nígbàtí ó bá ṣe dandan kí a bá ara wa wí, lẹ́hìn ìgbà náà a gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ tí ó pọ̀ síi hàn.10
Èmi yíó retí pé a ó tiraka nígbàgbogbo láti bọ̀wọ̀ fún àti láti ronú nípa èrò àti ìmọ̀lára àti ipò àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa. Ẹ máṣe jẹ́ kí a tàbùkù tàbí tẹ́mbẹ́lú. Dípò bẹ̃, kí a jẹ́ aláánú àti olùgbaniníyànjú. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a máṣe pa ìgbẹ́kẹ̀lé ẹlòmíràn run nípa àwọn ọ̀rọ̀ asán tàbí ìṣe.
Ìdáríjì gbọ́dọ̀ lọ rẹ́gírẹ́gí pẹ̀lú ìfẹ́. Nínú àwọn ẹbí wa, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa bákannáà, ìmọ̀lára ìpalára àti èdèàìyédè lè wà. Lẹ́ẹ̀kansi, kò jẹ́ nkankan rárá bí ohun náà ṣe kéré tó. Kò lè ṣe àti pé a kò gbọ́dọ̀ fisílẹ̀ láti kẹ̀, láti bàjẹ́, àti láti parun nígbẹ̀hìn. Ìdálẹ́bi kì npa ojú ọgbẹ́ mọ́. Ìdáríjì nìkan ni ó ńwò sàn.
Olólùfẹ́ obinrin kan tí ó ti kú tipẹ́ sẹ́hìn ṣe àbẹ̀wò sí mi ní ọjọ́ kan àti pé láìròtẹ́lẹ̀ ó ṣe àtúnrò àwọn àbámọ̀ kan. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣíwájú tí ó wémọ́ àgbẹ̀ aládúgbò kan, tí ó fìgbàkan jẹ́ ọ̀rẹ́ dáradára ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹnití òun àti ọkọ òun ti jà ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Ní ọjọ́ kan àgbẹ̀ náà bèèrè bí òun bá lè gba ọnà àbùjá lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti kọjá lọ sí orí ilẹ̀ ti òun. Ní àmì yí ó dáwọ́ dúró nínú ìròhìn rẹ̀ sími, pẹ̀lú ìwárìrì nínú ohùn rẹ̀, ó sọ pé, “Arákùnrin Monson, èmi kò jẹ́ kí ó gba orí ilẹ̀ wa nígbànáà tàbí láéláé ṣùgbọ́n mo mú kí ó lọ gba ọ̀nà tí ó jìn ní àyíká pẹ̀lú ẹsẹ̀ láti dé orí ilẹ̀ rẹ̀. Mo ṣìṣe, mo sì kábámọ̀. Ó ti lọ nísisìyí ṣùgbọ́n ah; ó wùmí pé mo lè sọ fun pé “mo káánú” Bawo ni ó ṣe wùmí tó pé mo lè ní ànfàní ẹ̀ẹ̀kejì láti jẹ́ onínũre.”
Bí mo ṣe ńfetísílẹ̀ sí i, ohun kan tí ó wá sí ọkàn mi ni awọn àkíyèsí ìbànújẹ́ ti John Greenleaf Whittier: “Ní gbogbo ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ ti ahọ́n tàbí kálámù, àwọn tí ó bàni nínújẹ́ jùlọ nìwọ̀nyí: ó lè ti jẹ́ bẹ́ẹ̀!”11 Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ṣe ńtọ́jú àwọn míràn pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìgbèrò inúrere, a ó yẹra fún irú àbámọ̀ bẹ́ẹ̀.
A mã ń sọ̀rọ̀ ìfẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí a lè dámọ̀: ẹ̀rín, ìjuwọ́, sísọ̀rọ̀ rere, ìyìn. Àwọn ìsọ̀rọ̀ míràn lè jẹ́ pẹ̀lú ọgbọ́n, gẹ́gẹ́bí fífi ẹwù hàn nínú íṣe ẹlòmíràn, kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan pẹ̀lú inúrere àti sùúrù, bíbẹ ẹnìtí ara rẹ̀ kò dá tàbí tí kò le jáde nílé wò. Àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọ̀nyí, àti ọ̀pọ̀ àwọn míràn, lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́.
Olókìkí onkọ̀wé àti olùkọ́ni Dale Carnegie, ní ìgbàgbọ́ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ní nínú ará rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin agbára láti mú àròpọ̀ ìdùnnú ayé [náà] pọ̀ sĩ “nípa fífún ẹnìkan tí ó ńdágbé tàbí tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ní àwọn ọ̀rọ̀ ìmoore òótọ́ díẹ̀.” Ó sọ pé, “Bóyá ìwọ yíò gbàgbé ní ọ̀la àwọn ọ̀rọ̀ rere tí o sọ lóní, ṣùgbọ́n ẹnití ó gbàá lè ṣìkẹ́ wọn fún gbogbo ayé rẹ̀”12
Njẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ nísisìyí, ní ọjọ́ òní gan an, láti fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run, bóyá wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ́bí wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn ojúgba lásán, tàbí àwọn àjèjì pátápátá. Bí a ṣe ńjí lójojúmọ́, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti dáhùn pẹ̀lú ìfẹ́ àti inú rere sí ohunkóhun tí ó lè wá sí ọ́nà wa.
Kọjá ìmọ̀, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, ni ìfẹ́ ti Ọlọ́run ní fún wa. Nítorí ìfẹ́ yí, Ó rán Ọmọkùnrin Rẹ̀, tí ó fẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ láti fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, kí a lè ní ìyè ayérayé. Bí a ṣe wá ní òye ẹ̀bùn àìláfiwé yí, ọkàn wa yíò kún pẹ̀lú ìfẹ́ fún Bàbá wa Ayéráyé, fún Olùgbàlà wa, àti fún gbogbo ènìyàn. Kí irú èyí lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àdúrà ìfọkànsìn mi ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.
© 2014 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. Printed in USA. English approval: 6/13. Translation approval: 6/13. Ìtumọ̀ ti First Presidency Message, May 2014. Yoruba. 10865 779