Ọ̀dọ́
Sarah ti Ẹni Míràn
Olùkọ̀wé náà ńgbé ní Utah, USA
Ó máa ńṣòro fún mi láti lo ìgbágbọ́ mi bí ìdáhùn sí ìbèèrè tí ó rọrùn gẹ́gẹ́bí “Kíni ìdí tí o kò fi ńmu kọfí?” Ní àtẹhìnwá mo wá pẹ̀lú àwáwí bíí pé “Ó ti korò jù” tàbí “Èmi kò fẹ́ràn ìtọ́wò rẹ̀.”
Kíni ìdí tí mò fi ńní ójútì Kíni ìdí tí ẹ̀rù ṣe ńbà mí bẹ́ẹ̀ láti dúró fún ohun tí mo gbàgbọ́? Ní wíwo ẹ̀hìn báyìí, èmi kò ní óye pàtó ohun tí mò ńbẹ̀rù. Ṣùgbọ́n mo rántí ní pàtó ìgbàtí mo dáwọ́-dúró ní sísápamọ́ sí ẹ̀hìn àwọn àwáwí.
Ní ọjọ́ kan ní ilé ìwé gíga mi ní kílãsì èdè òyìnbó, olùkọ́ náà kéde pé a ó máà wo ìran ti amóhùnmáwòrán kan tí mo mọ̀ pé kò yẹ kí ńwò. Nígbàtí àwọn akẹ́kọ́ míràn rẹ́rín nínú ayọ̀, akẹgbẹ́ mi ní kílãsì Sarah gbé ọwọ́ rẹ sókè ó sì bèèrè bí ó bá lè kúrò.
Nígbàtí olúkọ́ náà bèèrè ìdí, Sarah dáhùn ní ọ̀ràn òdodo, “Nítorí mo jẹ́ Mọ́rmọ́nì àti pé èmi kìí wo awọn eré tí kò ní ọ̀wọ̀.”
Ìgboyà rẹ̀ láti dúró ní iwájú yàrá ìkàwé jẹ́ ìyanu. Ọpẹ́ fún Sarah, emi náà dìde sókè mo sì dúró sítà pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ fún eré náà láti parí.
Mo ní ìyípadà títí láé Mo bẹ̀rẹ̀ sí ńṣe àlàyé ìgbàgbọ́ mi dípò yíyẹra fún àkórí ọ̀rọ̀ náà. Àti pé gẹ́gẹ́bí abájáde kan, mo rí ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara mi mo sì kópa síi àní nínú Ìjọ àti àwọn eré ṣíṣe ní ilé ìwé.
Èmi kò sọ fún Sarah láéláé bí àpẹrẹ rẹ̀ ṣe ní ìtumọ̀ tó sí mi, ṣùgbọ́n mo tiraka láti tẹ̀lé àpẹrẹ ti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. Bàyìí mo ti mọ̀ pé jíjẹ́ ọmọ ìjọ ìyanu, mimọ́ ti Ọlọ́run kìí ṣe ohun tí ó ńtini lójú rárá. Mo ní ìrètí pé mo lè, nípa àpẹrẹ mi, jẹ́ Sarah ti ẹlòmíràn.