Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, oṣù Kẹ́rin ọdún 2015
Àwọn Ìwà ti Jésù Krístì: Láìsí Àrékérekè tàbí Àgàbàgebè
Fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí o sì ṣe àwákiri lati mọ ohun ti õ ṣe àbápín. Báwo ni níní òye ìgbésí ayé ati ojúṣe Olùgbàlà yíò ṣe mú kí ìgbàgbọ́ yin nínú Rẹ̀ pọ̀ si, ti yíò sí bùkún awọn wọnnì tí ẹ̀yin ńbójútó nípa ìbẹniwò kíkọ́ni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Níní òye pé Jésù Krístì wà láìsí àrekérekè àti àgàbàgebè yíò ràn wá lọ́wọ́ bí a ṣe ńtiraka lótítọ́ láti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀. Alàgbà Joseph B. Wirthlin (1917–2008) ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ pé: “Láti ṣẹ̀tàn ni láti tànjẹ tàbí ṣì lọ́nà . … Ẹnì tí kò ní ìtànjẹ ni ẹni àìlẹ́bi, elérò òtítọ́, àti awọn èrò mímọ́, ẹnití ìgbé ayé rẹ̀ nṣe àfihàn ìrọ̀rùn ṣíṣe awọn ìṣe rẹ̀ ojojúmọ́ bí ọkùnrin [tàbí arábìnrin] ní ìbámu pẹ̀lú awọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìwà òtítọ́ … Mo ní ìgbàgbọ́ pé jíjẹ́ kòṣeémání fún àwọn ọmọ Ìjọ láti wà láìní ìtànjẹ lè jẹ́ kánjúkánjú síi báyìí ju ní àwọn àsìkò míràn nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ayé kò ní òye gbangban ti pàtàkì ìwà rere yí.”1
Nípa àgàbàgebè, Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, sọ pé: “Kò sí ìkankan lára wa tí ó dàbíi Krístì gan an bí a ti mọ̀ pé a nilati jẹ́. Ṣùgbọ́n a ńfi ìtara nífẹ́ láti borí àwọn ẹ̀bi wa àti ìdarísí láti dá ẹ̀ṣẹ̀. Pẹ̀lú ọkàn wa àti iyè inú à ńpòngbẹ láti di dídára sĩ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ètùtù ti Jésù Krístì”.2
A mọ̀ “a ó gba ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ìṣe wa, àwọn ìfẹ́ ti ọkàn wa, àti irú ènìyàn tì a ti dà.”3 Síbẹ̀síbẹ̀ bí a ṣe ńtiraka láti ronúpìwàdà, a ó di mímọ́ síi—àti pé “alábùkún fún ní ọlọ́kàn mímọ́: nítorí wọn yíò rí Ọlọ́run” (Matthew 5:8).
Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ́
Láti inú Àwọn Ìwé Mímọ́
Àwọn ọmọdé wà láìsí àrékérekè. Jésù Krístì sọ pé: “Ẹ jẹ́kí awọn ọmọ kékeré kí ó wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorítí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. … Ósì gbé wọn[àwọn ọmọdé] sí apá rẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, ó sì súre fún wọn” (Mark 10:14, 16).
Krístì bákannáà ṣe ìṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí àwọn ọmọdé ní Àmẹ́ríkàs lẹ́hìn Ìjìyà Rẹ̀. Ó pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn mú àwọn ọmọ wọn kéèkèké wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ó sì “gbé wọn kalẹ̀ yíká rẹ, Jésù sì dìde dúró ní àárín wọn; …
“…[Àti pé] ó sọkún, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn náà sì jẹ́rí sii, ó sì gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ó sì súre fún wọn, ó sì gbàdúrà sí Bàbá fún wọn. …
“Bí wọ́n sì ti wò láti kíyèsí wọ́n gbé ojú wọn sókè sí ọ̀run, wọ́n sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọ́n ńsọ̀kalẹ̀ jáde láti ọ̀run bí èyítí iná yí wọn ká; wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ wọ́n sì yí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ nnì ká,… àwọn ángẹ́lì náà sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn” (3 Nephi 17:12, 21, 24).
© 2015 Látọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/14. Àṣẹ ìtumọ̀: 6/14. Ìtumọ̀ ti Visiting Teaching Message, April 2015. Yoruba. 12584 779