Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, oṣù kẹ́rin ọdún 2015
Ààrẹ Monson Pè fún Ìgboyà
Wákàtí kan kò lè kọjá ni, Ààrẹ Thomas S. Monson ti ṣe àkíyèsí, ṣùgbọ́n ohun tí a gba ìpè fún láti ṣe àwọn àṣàyàn irú kan tàbí òmíràn.
Láti ṣe àwọn àṣàyàn ọgbọ́n, ó gbà wá nímọ̀ràn pé, a nílò ìgboyà—“ìgbóyà láti sọ pé rárá, ìgboyà láti sọ pé bẹ́ẹ̀ni. Àwọn Ìgbèrò máa ńpinnu àyànmọ́ ìpìn.”1
Nínú àwọn àyọkúrò tí ó tẹ̀le yí, Ààrẹ Monson rán àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn létí pé wọ́n nílò ìgboyà láti dúró fún òtítọ́ àti òdodo, láti gbèjà ohun tí wọ́n gbàgbọ́, àti láti dojúkọ ayé kan tí ó ńkọ àwọn iyì ayérayé àti àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ sílẹ̀.
“Ìpe fún ìgboyà ńwá lemọ́lemọ́ sí ìkọ̀ọ̀kan lára wa,” ni ó sọ. Ó ti máa nrí bẹ́ẹ̀ sẹ́hìn, àti pé bẹ́ẹ̀ ni yíò rí láé.”2
Ìgboyà Ńmú Àṣẹ ti Ọlọ́run wa
“Gbogbo wa yíò dojúkọ ìbẹ̀rù, ní ìrírí ẹ̀gàn, àti pàdé àtakò. Ẹ jẹ́ kí—gbogbo wa—ní ìgboyà láti lòdì sí òfin ayé, ìgboyà láti dúró fún ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́. Ìgboyà, láì ṣe ìbárẹ́, ńmú ẹ̀rín àṣẹ ti Ọlọ́run wá. Ìgboyà ńdi ìgbé ayé kan àti ìwà tí ó fanimọ́ra nígbàtí a bá kàá sí áìṣe jíjọ̀wọ́ ara ẹni sílẹ̀ lati kú tìgboyà-tìgboyà nìkan ṣùgbọ́n bákannáà gẹ́gẹ́bí ìpinnu láti gbé ìgbé ayé tí ó tọ́. Bí a ṣe ńrìn síwájú, ní títiraka láti gbé bí ó tí yẹ, dájúdájú a ó gba ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa a sì le rí ìtùnú nínú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀.”3
Kíkọjúsí pẹ̀lú Ìgboyà
“Kíni ó túmọ̀ sí láti faradà? Mo fẹ́ràn ìtumọ̀ yí: Láti kọjúsí pẹ̀lú ìgboyà. Igboyà lè jẹ́ ohun kòṣeémánĩ fún ọ láti gbàgbọ́; yíò jẹ́ ohun kòṣeémánĩ fún ọ nígbà míràn bí o ṣe ńní ìgbọ́ràn. Ní dídájú jùlọ yíò jẹ́ ohun nínílò bí ó ṣe ńfaradà títí di ọjọ́ náà nígbàtí ìwọ yíò fi ayé ikú yí sílẹ̀.”4
Ní Ìgboyà láti Dúró fún Òtítọ́
“[Njẹ́] kí ẹ ní ìgboyà láti dúró ṣinṣin fún òtítọ́ àti òdodo. Nítorí àwọn ohun ìṣẹ̀lẹ̀ ní àyíká òde òní jìnnà sí àwọn iyì àti ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tí Olúwa ti fún wa, dájúdájú ó lè jẹ́ pé wọn ó pè ọ́ láti gbèjà ohun èyí tí ó gbàgbọ́. Àyafi tí àwọn gbòngbò ẹ̀rí rẹ bá rinlẹ̀ gbọingbọin, yíò ṣòro fún ọ láti lè kọjúsí ẹ̀gàn àwọn tí ó ńpe ìgbàgbọ́ rẹ̀ níjà. Nígbàtí o bá gbìn ín rinlẹ̀ dáadáa, ẹ̀rí rẹ nípa ìhìnrere, nípa Olùgbàlà, àti nípa Bàbá wa Ọ̀run yíò fún gbogbo ohun tí ò ńṣe lókun ní gbogbo ayé rẹ.”5
A Nilò Ìgboyà ní ti Ẹ̀mí àti Ìwà-títọ́
“Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ńfihàn lórí amóhùn-máwòrán, nínú àwọn eré, àti ní àwọn ohun ìròhìn míràn [lóní] ńfì ìgbà gbogbo wà ní àtakò tààrà sí èyítí à ńfẹ́ kí àwọn ọmọ wa rọ̀mọ́ kí wọ́n sì dìímú dáadáa. Ó jẹ́ ojúṣe wa kìí ṣe láti kọ́ wọn nìkan láti dáńgájíá nínú ẹ̀mí àti ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n bákannáà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró ní ọ̀nà náà, láìka àwọn ipá ìta tí wọ́n lè bá padé. Èyí yíò gbà wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsìkò àti ìgbìyànjú—àti ní ètò láti ran àwọn míràn lọ́wọ́, àwa fúnra wa nílò ìgboyà ní ti ẹ̀mí àti ìwà-títọ́ láti le kọjúsí ibi tí à ńrí ní ọ̀nà gbogbo.”6
Njẹ́ Kí A Le Ní Ìgboyà Títí Láé
“Bí a ṣe ńlọ nípa ìgbé ayé láti ọjọ́ sí ọjọ́, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun tí kò lè ṣàì ṣẹlẹ̀ pé ìgbàgbọ́ wa yíò ní ìpèníjà. Nígbà míràn a lè rí kí àwọn míràn yí wa ká síbẹ̀síbẹ̀ kí à máa dúró láàrin èyí tí ó kéré jù tàbí pàápàá dídá dúró nípa ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà àti èyí tí kò rí bẹ́ẹ̀. …
“Njẹ́ kí a lè ní ìgboyà títí láé kí a sì múrasílẹ̀ láti dúró fún ohun tí a gbàgbọ́, àti pé tí a bá níláti dá dúró nínú ètò náà, njẹ́ kí a le ṣe bẹ́ẹ̀ tìgboyà-tìgboyà, kí á ní okun nípa ìmọ̀ pé ní òdodo a kò dá wà nígbàtí a bá dúró pẹ̀lú Bàbá wa ní Ọ̀run.”7
© 2015 Látọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/14. Àṣẹ ìtumọ̀: 6/14. Ìtumọ̀ ti First Presidency Message, April 2015. Yoruba. 12584 779