Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́wá Ọdún 2015.
Iṣẹ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì: Kún fún Ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́ àti Ìfẹ́
Fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ohun èlò yí kí o sì ṣe àwárí láti mọ ohun tí òó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye ìṣe àtọ̀runwá Olùgbàlà yíò ṣe mú kí ìgbàgbọ́ Rẹ nínú Rẹ̀ pọ̀ síi àti láti bùkún àwọn wọnnì tí ò ńbojútó nípa ìbẹniwò kíkọ́ni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Ìtọ́sọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́ náà túmọ̀ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ bíi “irú ìfẹ́ gíga jùlọ, ọlọ́lá jùlọ, líle jùlọ” (“Ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́”). Ó jẹ́ ìfẹ́ àìléèrí ti Jésù Krístì. Gẹ́gẹ́bí a ṣe ńkọ́ nípa Jésù Krístì tí a sì ńtiraka láti dà bíi Rẹ̀, a ó bẹ̀rẹ̀ sí nní ìmọ̀ara ìfẹ́ àìléèrí Rẹ̀ nínú ayé wa, a ó sì gba ìṣílétí láti nífẹ̀ẹ́ àti láti sin àwọn ẹlòmíràn bí Òun yíó ti ṣe. “Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni níní sùúrù pẹ̀lú ẹnìkan tí ó ti já wa kulẹ̀,” ni Ààrẹ Thomas S. Monson sọ. “Ó jẹ́ dída ojú ìjà kọ ìfẹ́-inú láti máa tètè bínú. Ó jẹ́ gbígba àwọn àìlera àti àwọn ìkùnà. Ó jẹ́ gbígba àwọn ènìyàn bí wọ́n ṣe rí nítòótọ́. Ó jẹ́ wíwò kọjá àwọn ìrí ara sí àwọn ìhùwàsí tí kò ní ṣókùnkùn nínú líla àsìkò kọjá. Ó jẹ́ dída ojú ìjà kọ ìfẹ́-inú láti máa ya awọn ẹlòmíràn sí ẹgbẹ́-ẹgbẹ́.”1
Nínú Ìwé ti Mọ́rmọ́nì, a kọ́ òtítọ́ ńlá náà pé a “gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo agbára tí ọkàn, pé kí [a] lè kún fún ìfẹ́ yí, èyítí ó ti fi jíìnkí gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé nítõtọ́ ti Ọmọ rẹ̀, Jésù Krístì; pé kí [a] lè di ọmọkùnrin [àti ọmọbìnrin] Ọlọ́run; pé nígbàtí ó bá fi ara hàn, nítorí àwa ó ri bí ó ṣe wà; kí àwa ó lè ní ìrètí; kí àwa lè di mímọ́ àní bí òun ti mọ́” (Mórónì 7:48).
Àfikún Ìwé Mímọ́
Jòhánù 13:34–35; 1 Àwọn Ará Kọ́ríntì13:1–13; 1 Nífáì 11:21–23; Étérì 12:33–34
Láti inú Ìwé Ìtàn Wa
Arábìnrin kan ẹnití ó di opó láìpẹ́ fi ìmoore hàn fún àwọn olùkọ́ ìbẹniwò tí wọ́n ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì tùú nínú. Ó kọ pé: ‘Mo wà ní ìtara àìní ẹnìkan tí mo lè nawọ́ jáde sí; ẹnìkan tí yíò fetísílẹ̀ sí mi. … Wọ́n sì fetísílẹ̀. Wọ́n tù mí nínú. Wọ́n sọkún pẹ̀lú mi. Wọ́n sì dì mọ́ mi …[àti pé] wọ́n ràn mí lọ́wọ́ kúrò nínú àìnírètí ti ó jinlẹ̀ àti ìdorí kodò àwọn oṣù àkọ́kọ́ ti ìdánìkanwà.’
“Obìnrin míràn ṣe àròpọ̀ ìmọ̀ara rẹ̀ nígbàtí ó gba òtítọ́ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ láti ọ̀dọ̀ olùkọ́ ìbẹniwò kan: ‘Mo mọ̀ pé mo kàn ju nọ́mbà kan lọ lórí àwọn ìwé àkọsílẹ̀ fún ìbẹ̀wò rẹ̀ ni. Mo mọ̀ pé ó ńṣè ìtọ́jú mi.’”2
Gẹ́gẹ́bí àwọn arábìnrin wọ̀nyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn káàkiri àgbáyé lè jẹ́rí sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ sísọ yí láti ọwọ́ Ààrẹ Boyd K. Packer (1924–2015), Ààrẹ ti Iyejú Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: “Báwo ni ó ṣe tuni nínú tó láti mọ̀ pé ibi yówù kí [ẹbí kan lè] lọ, Ẹbí Ìjọ kan ndúró dè wọ́n. Láti ọjọ́ tí wọ́n ti dé, ọkùnrin yíò wà ní iyejú ti oyè àlufáà kan àti pé obìnrin yíò wà ní Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́.”3
© 2015 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/15. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/15. Ìyírọ̀padà ti Visiting Teaching Message, October 2015. Yoruba. 12590 779