Ọ̀dọ́
Fi Epo Sí Ògùṣọ̀ Rẹ: Àdánwò Ọgbọ̀n Ọjọ́ Náà
Fún àwọn ọ̀dọ́ nínú Ìjọ pẹ̀lú ìgbé ayé aápọn, ó lè rọrùn láti há sínú ẹrẹ̀ ṣíṣé irú ìṣẹ́ kannáà, nípàtàkì pẹ̀lú àwọn ohun ti ẹ̀mí. A ńka àwọn ìwé mímọ́ wa, ńgbàdúrà, a sì njọ́sìn ní ọ̀nà kannáà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ojojúmọ́ àti pé nígbà náà ó máa ńyanilẹ́nu ìdí tí ó ṣe dàbíi pé à nṣubú níti ẹ̀mí.
Ìkan lára àwọn ọ̀nà tí ó dára jù láti pa ògùṣọ̀ ti ẹ̀mí rẹ mọ́ ní jíjó gere-gere ni láti ríi dájú pé ò nní àwọn ìrírí ti ẹ̀mí tí ó ní ìtumọ̀. Ṣùgbọ́n èyĩnì rọrùn ní sísọ ju ṣíṣe lọ, nítorínáà àbá kan nìyí tí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ lati ní ìlọ́síwájú síi nípa ti ẹ̀mí: Ro ti àwọn eré tí ó bá ìhìnrere tan tí ìwọ kò ṣe rí láéláé (tàbí ti o fẹ́rẹ̀ má ṣe rí) kí o sì tẹramọ́ láti ṣeé lójojúmọ́ fún oṣù kan. Ó lè bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ nítorí ìwọ yíò ri pé ó rọrùn láti yí ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ padà sí èyí tí yíò pẹ́ títí. Ṣíṣe àwọn ohun tí yíò mú wa jáde ní ibi ìtura wa ní ti ẹ̀mí lè gba ìgbàgbọ́ púpọ̀ síi àti ìgbìyànjú ní àpá ọ̀dọ̀ tiwa, ṣùgbọ́n nígbàtí a bá ṣe wọ́n, à npe Ẹ̀mí Mímọ́ láti wà pẹ̀lú wa, a sì nfi ìgbàgbọ́ títóbi ju hàn nínú Bàbá Ọ̀run àti ìfẹ́-inú láti túbọ̀ súnmọ́ Ọ síi. Àwọn èrò díẹ̀ nìyí láti mu ọ bẹ̀rẹ̀: