Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́wá Ọdún 2015
Parí Pẹ̀lú Ògùṣọ̀ Rẹ̀ ní Títàn Síbẹ̀
Ní Greece àtijọ́, àwọn olùsáré máa ńdíje nínú eré ìje àságbagi kan tí à ńpè ni lampadẹdírómíà.1 Nínú eré ìje náà, àwọn olùsáré máa ńdi ògùṣọ̀ mú ní ọwọ́ wọn, wọ́n a sì múu fún olùsáré tí ó kàn títí tí ọmọ ẹgbẹ́ tí ó gbẹ̀hìn yíó fi sọdá ilà ìparí.
Ọrẹ ìyìn kò ń jẹ́ gbígbé fún àwọn ẹgbẹ́ tí ó yára sáré jùlọ—wọn a máa fún ẹgbẹ́ kínní tí ó kọ́kọ́ dé ilà ìparí pẹ̀lú ògùṣọ̀ rẹ̀ ní títàn síbẹ̀.
Ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ kan wà níbí, ọ̀kan tí a kọ́ni lati ọwọ́ àwọn wòlíì àtijọ́ àti ti òde òní: nígbàtí ó ṣe pàtàkì láti bẹ̀rẹ̀ eré ìje, àní ó ṣe pàtàkì síi pé kí a parí pẹ̀lú ògùṣọ̀ wa ní títàn síbẹ̀.
Sólómọ́nì Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ìlera
Ọba ńlá Sólómọ́nì jẹ́ àpẹrẹ ti ẹnìkan tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìlera. Nígbàtí ó wà ní ọ̀dọ́, ó “ní ìfẹ́ Olúwa, ní rírìn nínú àwọn àṣẹ Dáfídì bàbá rẹ̀” (1 Àwọn Ọba 3:3). Ọlọ́run ní inú dídùn pẹ̀lú rẹ̀ ó sì wípé, “Bèèrè ohun tí èmi ó fi fún ọ” (1 Àwọn Ọba 3:5).
Dípò bíbèèrè fún ọrọ̀ tàbí ẹ̀mí gígùn, Sólómọ́nì bèèrè fún “ọkàn ìmòye láti ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ, láti mọ ìyàtọ̀ rere àti búburú” (1 Àwọn Ọba 3:9).
Èyí mú inú Olúwa dùn púpọ̀ gan an débi pé Ó bùkún Sólómọ́nì kìí ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọrọ̀ tí ó kọja òsùnwọ̀n àti ẹ̀mí gígùn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì jẹ́ ọlọ́gbọ́n gidi nítòótọ́ tí ó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ńlá, kò parí pẹ̀lú ìlera. Pẹ̀lú ìbànújẹ́, ní ìkẹhìn ìgbésí ayé rẹ̀, “Sólómọ́nì ṣe búburú níwájú Olúwa, kò sì tọ Olúwa lẹ́hìn ní pípé” (1 Àwọn Ọba 11:6).
Píparí Eré Ìje Tiwa
Ìgbà méló ni a ti bẹ̀rẹ̀ ohun kan tí a kò sì parí? Àwọn oúnjẹ afúnnilókun? Àwọn ètò ìdárayá? Ìtẹramọ láti ka àwọn ìwé mímọ́ lójojúmọ́? Àwọn ìpinnu láti di ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì dídára síi?
Báwo ni a ṣe ńfì ìgbàkugbà ṣe ìpinnu nínú oṣù kínní tí a sì ńlépa wọn pẹ̀lú okun tí ó gbóná janjan fún àwọn ọjọ́ díẹ̀, ọ̀sẹ̀ díẹ̀, tàbí ọṣù díẹ̀ nìkan kí a tó ri pé ní oṣù kẹ́wá, ọ̀wọ́ iná ìtẹramọ́ wa ti fi díẹ ju eérú tútù lọ?
Ní ọjọ́ kan mo rí àwòrán apanilẹ́rĩn ti ajá kan tí ó dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìrépé ìwé kan tí ó ti fàya kékèèké. Ó kà pé, “Ìwé-ẹ̀rí ti Ìdánilẹ́kọ́ Ìgbọ́ran-Ajá.”
A dàbí èyí ní àwọn ìgbà míràn.
A ní àwọn èrò rere; a bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìlera; a fẹ́ lati jẹ́ dídára jùlọ ti ara wa. Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀hìn a fi àwọn ìpinnú wa sílẹ̀ ní yíya kékèèké, ní kíkọ̀ sílẹ̀, àti ní gbígbàgbé.
Ó jẹ́ ìwà ẹlẹ́ran ara láti kọsẹ̀, kùnà, àti ní àwọn ìgbà míràn lati fẹ́ fà sẹ́hìn kúrò nínú eré ìje. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì, kìí ṣe pé a ti tẹramọ́ láti bẹ̀rẹ̀ eré ìje nìkan ṣùgbọ́n láti parí rẹ̀ bákannáà—àti láti parí rẹ̀ pẹ̀lú ògùṣọ̀ wa ní títàn gere-gere síbẹ̀. Olùgbàlà ṣe ìlérí fún àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀, “Ẹni tí ó bá forítì i títí dé òpin, òun náà ni a ó gbàlà” (Máttéù 24:13).
Jẹ́ kí ń ṣe àtúnsọ ohun tí Olùgbàlà ti ṣe ìlérí ní ọjọ́ wa: Bí a bá pa àwọn òfin mọ́ tí a sì parí pẹ̀lú ògùṣò wa ní títàn síbẹ̀, a ó ní ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí ó ga jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 14:7; bákannáà wo 2 Nífáì 31:20).
Ìmọ́lẹ̀ Tí Kìí Kú Láéláé
Ní àwọn ìgbà míràn lẹ́hìn ìkọsẹ̀, ìkùnà, tàbí jíjuwọ́ sílẹ́ pàápàá, a máa nní ìrẹ̀wẹ̀sì à sì máa nní ìgbàgbọ́ pé ìmọ́lẹ̀ wa ti kú àti pé eré ìje wa ti sọnù. Ṣùgbọ́n mo jẹ́rí pé Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì kò lè ṣeé pa. Ó ndán nínú alẹ́ tí ó ṣókùnkùn jùlọ àti pé yíò tún ìmọ́lẹ̀ tàn sínú ọkàn wa ṣe bí a bá lè darí ọkàn wa sí Òun (wo 1 Àwọn Ọba 8:58).
Bí ó ti wù kí iye ìgbà ìṣubú wa pọ̀ tó tàbí kí ó ṣe gùn tó, Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì njó gere-gere láé. Àti pé àní nínú alẹ́ tí ó jinlẹ̀ jùlọ, ṣùgbọ́n bí a bá gbésẹ̀ sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ yíò jẹ àwọn òjiji náà run yíò sì tún ṣána sí iyè inú wa.
Eré ìje ti ọmọlẹ́hìn yí kìí ṣe ti ìṣẹ́jú akàn; ó jẹ́ ti àìdúró tí ó gùn púpọ̀. Àti pé ìyàtọ̀ díẹ̀ ni ó wà bí ó ti wù kí á yára sí. Lódodo, ọ̀nà kanṣoṣo tí a fi lè pàdánù eré ìje wa ni nípa gbígbà lati kùnà tàbí dídáwọ́ ìtiraka dúró pátápátá.
Níwọ̀n ìgbà tí a bá tẹ̀síwájú lati jí gìrì tí a sì gbé ìgbésẹ̀ sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa, a ó borí eré ìje pẹ̀lú àwọn ògùṣọ̀ wa ní jíjó gere-gere.
Nítorí ògùṣọ̀ náà kìí ṣe nípa wa tàbí nípa ohun tí a ṣe.
Ó jẹ́ nípa Olùgbàlà aráyé.
Àti pé èyĩnì ni Ìmọ́lẹ̀ kan tí kò lè ṣókùnkùn láéláé. Ó jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ kan tó ngbé òkùnkùn mì, tí ó ńwo ọgbẹ́ wa sàn, tí ó sì ntàn àní ní àárín ìbànújẹ́ tí ó jinlẹ̀ jùlọ àti òkùnkùn tí kò ní òsùnwọ̀n.
Ó jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ kan tí ó kọjá òye.
Njẹ́ kí ìkọ̀ọ̀kan lára wa le parí ipá ọ̀nà tí a ti bẹ̀rẹ̀. Àti pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, a ó parí tayọ̀tayọ̀ àti pẹ̀lú àwọn ògùṣọ̀ wa ní títàn síbẹ̀.
© 2015 látọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/15. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/15. Ìyírọ̀padà ti First Presidency Message, October 2015. Yoruba. 12590 779