Àwọn Ọmọdé
Mú Ògùṣọ̀ Rẹ Mọ́lẹ̀ Síi
Ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn ní Greece, eré ìje kan wà níbi tí àwọn olùsáré ti di àwọn ògùṣọ̀ títàn mú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá gbogbo eré ìje náà pẹ̀lú ògùṣọ̀ tí ó ṣì tàn síbẹ̀ ni olùborí. Ààrẹ Uchtdorf sọ pé ìgbé ayé dàbí eré ìje náà. Ògùṣọ̀ náà tí a dìmú ni Ìmọ́lẹ̀ Krístì. Nigbàtí a bá tiraka láti dàbíi Jésù Krístì, à nmú àwọn ògùṣọ̀ wa jó gere-gere síi.
Kíni àwọn ohun tí o lè ṣe láti dàbíi Jésù kí o sì mú ògùṣọ̀ rẹ tàn gere-gere síi? Yàn láti inú àwọn tí a tò sísàlẹ̀ yìí:
-
Rẹ́rín tàbí ṣe ìkíni sí ẹnìkàn tí ó dàbí pé ó nìkan wà
-
Dúró ní ìbínú sí ẹnìkan
-
Tọ́jú àgọ́ ara rẹ
-
Fi arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣe yẹ̀yẹ́
-
Gbọ́ran sí wòlíì
-
Dáwọ́ ìgbìyànjú dúró nígbàtí ó bá ṣe àṣìṣe
-
Ran ẹnìkan lọ́wọ́