Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2016
Dá ní Àwòrán Ọlọ́run
Fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí o sì lépa lati mọ ohun ti o nílati ṣe àbápín rẹ. Báwo ni níní óye “Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo Ayé yíò ṣe mú kí ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ tó àti láti bùkún àwọn wọnnì tí ọ nṣe ìṣọ́ lé lórí nípa ìbẹniwò kíkọ́ni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Ọlọ́run sọ pé Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán, ara wa. …
“Nítorínáà Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ní ó dá a; ọkùnrin àti obìnrin ni ó dá wọn” (Genesis 1:26–27).
Ọlọ́run ni Bàbá wa Ọ̀run, Òun sì dá wa ní àwòràn ara Rẹ̀. Nípa òtítọ́ yí ni, Ààrẹ Thomas S. Monson sọ pé: “Ọlọ́run Bàbá wa ní etí pẹ̀lú èyí tí Ó fi ngbọ́ àdúra wa. Ó ní ojú pẹ̀lú èyí tí Ó fi nrí àwọn ìṣe wa. Ó ní ẹnu pẹ̀lú èyí tí Ó fi nsọ̀rọ̀ sí wa. Ó ní ọkàn pẹ̀lú èyí tí Ó fi ńní ìmọ̀ara ìyọ́nú àti ìfẹ́ Ó wà nítòótọ́ Ó wà láàyè. Àwa ni ọmọ rẹ̀ tí a dá ní àwòrán rẹ̀. A fi ojú jọ ọ́ òun náà sì fi ojú jọ wá.”1
“Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn rí gbogbo ènìyàn bí ọmọ Ọlọ́run ní kíkún àti pípé ọgbọ́n; wọ́n ka olúkúlùkù sí ti ọ̀run ní àtètèkọ́ṣe, ní àdánidá, àti ní agbára-ìleṣe.”2 Ìkọ̀ọ̀kan jẹ́ olùfẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ẹ̀mí ti àwọn òbí ọ̀run.”3
“[Wòlíì náà] Joseph Smith bákannáà kọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn mọ Rẹ̀ gba irú wíwà ìgbéga kannáà nínú èyítí Òun ti se àbápín.”4 Bí Ọlọ́run ti sọ pé, Nítorínáà kíyèsíi, èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé àwọn ènìyàn wá sí ìmúṣẹ (Moses 1:39).
Àfikún Ìwé Mímọ́
Genesis 1:26–27; 1 Corinthians 3:17; Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 130:1
Látinú Àwọn Ìwé Mímọ
Arákùnrin Járẹ́dì nínú Ìwé ti Mọ́rmọ́nì wá ọ̀nà láti tànmọ́lẹ̀ sí ọkọ̀ ìgbàjà mẹ́jọ tí wọ́n ṣe láti gbé àwọn ará Járẹ́dì sọdá àwọn omi sí ilẹ̀ ìlérí. Ó sì yọ àwọn òkúta kékèèké mẹ́rìndínlógún láti ara òkúta nlá kan ó sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ó fi ọwọ́ kan àwọn òkúta wọ̀nyí pẹ̀lú ìka Rẹ̀ pé kí wọ́n lè tànmọ́lẹ̀ jade nínú òkùnkùn. Ọlọ́run sì nà ọwọ́ rẹ̀ jade ó sì fi ọwọ́ kan àwọn òkúta náà ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. A mú ìbòjú náà kúrò ní ojú arákùnrin Járẹ́dì, ó rí ìka Olúwa; ó sì dàbí ika ti ènìyàn. …
“Olúwa sì wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gba àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí èmi yíò sọ gbọ́?
“Òun sì dáhùn pé: Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa”
Àti “pé Olúwa fi ara rẹ̀ hàn sí [arákùnrin Járẹ́dì] ó sì sọ pé, Sé ìwọ ri pé ni àwòrán ara mi ni a dá ọ? Bẹ́ẹ̀ni, àní gbogbo ènìyàn ni a dá ní àtètèkọṣe ní àwòrán ara mi. (Wo Ether 3:1–17.)
© 2016 by Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì 6/15. Àṣẹ Àyípadà Èdè: 6/15. Àyípadà èdè ti Visiting Teaching Message, March 2016. Yoruba 12863 779