2016
Kọ́ Nípa Mi
OṢù Ẹrẹ̀nà 2016


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2016

“Kọ́ Nípa Mi”

Ní Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, gbogbo wa jẹ́ olùkọ́ni gbogbo wa sì jẹ́ akẹ́kọ́. Sí gbogbo ènìyàn ni ìpé jẹ́jẹ́ yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé: “Ẹ kọ́ nípa mi … ẹ̀yin yíò si rí ìsinmi sí ẹ̀mí yín.”1

Mo pe gbogbo Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti jíròrò lórí ìgbìyànjú wọn láti kọ́ni àti láti kẹ́kọ̀ọ́ àti láti wo Olùgbàlà gẹ́gẹ́bí Atọ́nà wa ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. A mọ̀ pé olùkọ́ni yí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”2 ju olùkọ́ni kan lásán lọ. Ẹni ná tí ó kọ́ wa láti nífẹ̀ẹ́ Olúwa Ọlọ́run wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, gbogbo ẹ̀mí wa, gbogbo okun wa, àti gbogbo iyè wa, àti láti nífẹ̀ẹ́ aládúgbò wa gẹ́gẹ́bí ara wa, jẹ́ Ọ̀gá Olùkọ́ni àti Alápẹrẹ ti ìgbé ayé pipe.

Òun ni ẹni tí ó kéde “Wá, tẹ̀lé mi.”3 “Mo ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún ọ.”4

Àyàfi tí Ẹ bá ní Ìyípadà Ọkàn

Jésù kọ́ni ní ohun ìrọ̀rùn kan ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ìjìnlẹ̀ òtítọ́ gẹ́gẹ́bí a ti kọọ́ sílẹ̀ ní Máttéù. Lẹ́hìn tí Òun àti àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ ti sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè ti Ìpapòdà, wọ́n dáradúró díẹ̀ ní Gálílì àti pé nígbànáà wọ́n lọ sí Cápérńáùm. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ẹ̀hìn wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n nbeerè:

Tani ó tóbi jùlọ nínú ìjọba ọ̀run?

Jésù sì pe ọmọdé kán sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó sì gbe e sí àárín wọn,

“Ó sì wipe, Lõtọ́ , ni mo wí fún un yín, Bíkòṣepé ẹ bá ní ìyípadà ọkàn, kí ẹ sì dàbí ọmọ kékeré, ẹ̀yin kì yío wọ ìjọba ọ̀run5

Nínú Ìjọ, ìfojúsíi ìhìnrere kíkọ́ni kìí ṣe láti tú ìwífúnni sí inú àwọn ọmọ Ọlọ́run, bóyá ní ilé, ní yàrá ìkàwé, tàbí ní papa iṣẹ́ ìránṣẹ́. Kìí ṣe láti fihàn bí òbí náà, olùkọ́, tàbí ìránṣẹ́ ìhìnrere ṣe mọ̀ tó. Tàbí kí ó jẹ́ láti pọ̀ síi nínú ìmọ̀ nípa Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀.

Kókó ìfojúsí ti ìkọ́ni ni láti ran àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ti Bàbá Ọ̀run lọ́wọ́ láti padà sí ọ́dọ̀ Rẹ̀ àti láti gbádùn ìye ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀. Láti ṣe èyí, ìhìnrere kíkọ́ni gbọ́dọ̀ gbà wọ́n níyànjú ní ipá ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn lójojúmọ́ àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ Ohun ìfojúsí náà ni láti mísí ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ronú nípa, ní ìmọ̀ara nípa, àti nígbà náà ṣe ohun kan nípa gbígbé ìgbé ayé ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere. Ìfojúsí náà ni láti mú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì dàgbà àti láti ní ìyípada ọkàn sí ìhìnrere Rẹ̀.

Ìkọ́ni èyí tí ó ńbùkúnfúnni tí ó sì ńyíni lọ́kan padà tí ó sì ngbànilà ni ìkọ́ni èyí tí ó nfi ara wé àpẹrẹ ti Olùgbàlà. Àwọn olùkọ́ tí wọ́n nfi ara wé àpẹrẹ ìfẹ́ ti Olùgbàlà tí wọ́n sì nsìn àwọn wọnnì tí wọ́n nkọ́. Wọ́n nmísí àwọn olùgbọ́ ọ̀rọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ayérayé ti òtítọ́ àtọ̀runwá. Wọ́n ngbé ìgbé ayé tí ó yẹ́ ní àfiwé

Ẹ ní Ìfẹ́ kí ẹ sì Sìn

Gbogbo iṣẹ́ ìrànṣẹ́ Olùgbàlà fi àpẹrẹ ìfẹ́ ti aládúgbò hàn. Nítòótọ́, ìfẹ́ àti iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀ máa nfi ìgbàkugbà jẹ́ ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Ní irú ọ̀nà yí kannáà, àwọn olùkọ́ tí mo rantí jùlọ ni àwọn olùkọ́ tí wọ́n mọ̀, nífẹ́, tí wọ́n sì nṣìkẹ́ àwọn akẹ́kọ́ wọn. Wọ́n wá àgùtàn tí ó sọnù. Wọ́n kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ ìgbé ayé èyí tí èmi yíò máa rantí nígbàgbogbo.

Ìkan lára irú àwọn olùkọ́ náà ni Lucy Gertsch. Ó mọ ìkọ̀ọ̀kan lara àwọn akẹ́kọ́ rẹ̀. Kò kùnà láti pe àwọn wọnnì tí wọ́n pa ọjọ́ ìsinmi kan jẹ tàbí tí wọn kò wá rárá. A mọ̀ pé ó nṣìkẹ́ nípa wa. Kò sí ẹnikẹ́ni lára wa tí ó gbàgbé rẹ̀ láé tàbí àwọn ẹ̀kọ́ tí ó kọ́ni.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́hìn náà, nígbàtí Lucy nsúnmọ́ òpin ayé rẹ̀, mo ṣe àbẹ̀wò pẹ̀lú rẹ̀. A ṣe ìrántí nípa àwọn ọjọ́ wọnnì tí ó t ipẹ́ ṣíwájú nígbàtí òun ti jẹ́ olùkọ́ wa. A sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ yàrá ìkàwé wa a sì fọ̀rọ̀wérọ̀ ohun tí ìkọ̀ọ̀kan wọn nṣe báyìí. Ìfẹ́ rẹ̀ àti ṣíṣe ìkẹ́ wà tàn kárí ìgbé ayé.

Mo nífẹ́ ìyànjú Olúwa tí a rí nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú:

“Mo fún un yín ní òfin kan pé kí ẹ kọ́ ara yín ní ẹ̀kọ́ ti ìjọba.

“Ẹ kọ́ni taratara oore ọ̀fẹ́ mi yíò sì wà fún yín.”6

Lucy Gertsch fi taratara kọ́ni nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ láìṣàárẹ̀.

Ẹ Fi Ìrètí àti Òtítọ́ Fúnni

Àpọ́stélì Pétérù gbani nímọ̀ràn pé, Ẹ múra tan nígbàgbogbo láti dá olukúlùkù lóhùn tí nbèrè ìrètí tí ó wà nínú yín.”7

Bóyá ìrètí tí ó ga jùlọ tí olùkọ́ kan lè fúnni ni ìrètí tí a rí nínú àwọn òtítọ́ ti ìhìnrere Jésù Krístì.

Kí sì ni ẹ̀yin yíò ní ìrètí fún? Mọ́rmọ́nì beerè. Ẹ́ kíyèsĩ mo wí fún yín pe ẹ̀yin yio ní ìrètí nípasẹ̀ ètùtù Krístì àti agbára àjínde rẹ̀, kí a gbé yín dìde sí ìyè tí kò nípẹ̀kun, èyítí ó sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ yín nínú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀.8

Ẹ̀yin Olùkọ́, ẹ gbé ohùn yín sókè kí ẹ sì jẹ́ ẹ̀rí sí òtítọ́ àdánidá ti Olórí ọ̀run. Ẹ kéde ẹ̀rí yín nípa Ìwé ti Mọ́rmọ́nì. Gbé àwọn òtítọ́ ológo àti ẹlẹ́wà tí ó wà nínú ètò ti ìgbàlà kiri. Ẹ lo àwọn ohun èlò ti Ìjọ fi àṣẹ sí, nípàtàkì àwọn ìwé mímọ́, láti kọ́ni ní àwọn òtítọ́ ti ìhìnrere ti Jésù Krístì tí a mú padà bọ̀sípò ní mímọ́ àti ìrọ̀rùn wọn. Ẹ rántí ìyànjú ti Olùgbàlà láti wá inú àwọn ìwé mímọ́; nítorí nínú wọn ní ẹ̀yin rò pé ẹ ní ìyè ayérayé: àwọn sì ni ìwọ̀nyí tí ó jẹ́ ẹ̀rí mi.”9

Ran àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí ó jẹ́ àìṣẹ̀tàn àti pàtàkì nínú ayé yí. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbèrú si nínú okun láti yan àwọn ipá ọ̀nà tí yíò pa wọ́n mọ́ ní àìléwú ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè ayérayé.

Ẹ kọ́ni ní òtítọ́, àti pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wà pẹ̀lú àwọn ìgbìyànjú yín.

“Kọ́ Nípa Mi”

Nítorípé Jésù Krístì jẹ́ olùgbọrànní pípé àti olùtẹríba sí Bàbá Rẹ̀, Ó pọ̀ “si nínú ọgbọ́n àti dídàgbà, àti ní ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyán.”10 Njẹ́ a ní ìpinnu láti ṣe bákannáà? Gẹ́gẹ́bí Jésù ṣe “gba oore ọ̀fẹ́ fún oore ọ̀fẹ́,”11 a gbọ́dọ̀ fi nínísùúrù àti títẹramọ́ ìlépa ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn ìgbìyànjú wa láti kẹ́kọ̀ọ́ ìhìnrere.

Ìfetísílẹ̀ jẹ́ abala pàtàkì nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́. Nigbàtí a bá nmúrasílẹ̀ láti gba ẹ̀kọ́, a nfi tàdúrà-tàdúrà lépa ìmísí àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. À njíròrò, à ngbàdúrà, à nlo àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere, à sì nwá ìfẹ́ ti Bàbá fún wa rí.12

Jésù “kọ́ni ní … ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan nípa òwe,”13 èyítí ó nílò etí láti gbọ́ran, ojú láti ríran, àti ọkàn láti ní òye. Bí a ṣe ngbé ìgbé ayé yíyẹ, a lè túbọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ dáradára síi, èyí tí “ó lè kọ́ [wa] ni ohun gbogbo, tí yíò sì mú ohun gbogbo wá sí ìrántí [wa].”14

Nígbàtí a bá fèsì sí ìfipè jẹ́jẹ́ Olúwa pé, Kọ́ nípa Mí, a di alábápín ti agbára ọ̀run Rẹ̀. Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú nínú ẹ̀mí ìgbọ́ran, ní títẹ̀lé Alápẹrẹ wa nípa kíkọ́ni bí Òun yíò ṣe fẹ́ kí a kọ́ni kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ bí Òun yíò ṣe fẹ́ kí a kọ́.

Ìkọ́ni láti inú ọ̀rọ yìí

Ààrẹ Monson pè wá láti jíròrò àwọn “ìgbìyànjú [wa] láti kọ́ni àti láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti lati wo Olùgbàlà gẹ́gẹ́bí Atọ́nà wa ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀.” Ẹ lè gbèrò láti ṣe wíwá inú àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ẹ nbẹ̀wò láti wá òye inú sí àwọn ọ̀nà tí Jésù Krístì ti kọ́ni àti tí Ó ti kẹ́kọ̀ọ́. Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn ìwé mímọ́ ti Ààrẹ Monson tọ́ka sí, bí ìrúu Matteu 11:29, Jòhánù 5:30, àti Makù 4:2. Ẹ lè jọ sọ̀rọ̀ bí ohun tí ẹ ti kọ́ nípa Krístì ti lè ràn yín lọ́wọ́ láti di alábápín ti agbára ọ̀run Rẹ̀.”

Tẹ̀