2017
Ìránṣẹ́ Ìhìnrere láìsí ìdánimọ̀
June 2017


Ọ̀dọ̀

Ìránṣẹ́ Ìhìnrere láìsí ìdánimọ̀

Ní ilé-ìwé mo ní olùkọ́ kan tí ó jẹ́ irú ẹni tí ó lè banilẹ́rù kúrò ní ṣíṣe àbápín èrò tí ó tako tirẹ̀ lórí àkòrí kan. Ní ọjọ́ kan a dé orí àkórí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Mo mọ̀ pé mo lè dáhùn àwọn ìbèèrè rẹ̀, ṣùgbọ́n mo ní ìmọ̀lára pé èmi kò gbọ́dọ̀ ṣeé. Nítorínáà mo sọ díẹ̀ tó láti tẹ́ẹ lọ́rùn fún ìgbà kan ná.

Fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí ó tẹ̀le èmi kò lè dáwọ́ ìrònú dúró nípa àwọnn ọ̀rọ tí a sọ. Ní ìgbẹ̀hìn, èrò kan wá sími lọ́kàn pé kí èmi fún un ní Ìwé ti Mọ́rmọ́nì pẹ̀lú àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ìdámọ̀ sí nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Èrò náà dẹ́rù bà mí, ṣùgbọ́n o tẹ̀síwájú. Mo mọ̀ pé ìṣílétí kan tí mo níláti tẹ̀lé ni.

Ní bí oṣù méjì lẹ́hìn náà, mo ní Ìwé Mọ́mọ́nì náà sílẹ̀. Ní gbogbo ọjọ́ náà mo ní ìmọ̀lára bíi pé ìwé náà njó ihò kan nínú àpò ẹ̀hìn mi. Ìṣẹ́jú àáyá mẹ́ta tí ó gbà mí láti mú fun un bí mo ti kúrò lọ fún ìsinmi ìgba òtútù jẹ́ àkokò tí ó banilérù jù ní ìgbé ayé mi.

Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ sẹ́hìn, mo gba yàrá ìkàwé rẹ̀ kọjá ṣùgbọ́n ẹ̀rù nbà mí láti wọlé. Ní ìgbà náà mo gbọ́ tí ó pè mí, ó sì fún mi ní káàdì kan. Mo kàá ni ọ̀nà yàrá nlá. Ó kọ pé òun ti ṣe àṣàrò “gidigidi” àwọn ẹsẹ tí mo ti fi àmì sí, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ láti rí àwọn ìdí tí ó wà lẹ́hìn ìgbàgbọ́ mi.

Mo ni inú dídùn ní ṣíṣe àbápín ìhìnrere náà nísisìnyí, àní inú mi dùn síi láti sin Bàbá mi Ọ̀run ní míṣọ̀n láìpẹ́.

Tẹ̀