Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù Kẹfà 2017
Agbára Oyè-àlùfáà nípasẹ̀ Pípa àwọn Májẹ̀mú Mọ́
Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?
“Ọ̀rọ̀ mi sí … gbogbo ènìyàn ni pé a lè gbé ní gbogbo wákàtí ‘ní bíbùkún nípasẹ okun ti agbára oyè-àlùfáà,’ ní ipòkípò tí a lè wà,” ni Alàgbà Neil L. Andersen ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ.
“… Bí ẹ ṣe nkópa ní yíyẹ nínú àwọn ìlànà ti oye-àlùfáà, Olúwa yíò fún un yín ní okun, àláfíà, àti ìwò ayérayé tí ó ga jù. Ipòkípò tí ẹ lè wà, ‘a ó bùkún ilé yín nípa okun agbára oye-àlùfáà.’”1
Báwo ni a ó ṣe pe agbára oyè-àlùfáà sínú ayé wa? Alàgbà M. Russell Ballard ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá rán wa létí pé “àwọn wọnnì tí wọ́n ti wọ inú omi ìrìbọmi tí wọ́n sì gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì wọn nínú ilé Olúwa lẹ́hìnnáà yege fún àwọn ìbùkún tí ó jẹ́ ọrọ̀ ati ìyanu. Ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ní ọ̀rọ̀ míràn jẹ́ ẹ̀bùn agbára kan … [àti pe] Bàbá wa ní Ọ̀run jé onínurere pẹ̀lú agbára Rẹ̀.” Ó rán wa létí pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin “méjèèj. ní a fún nièbùn agbára kannáà” nínú tẹ́mpíl., “èyi tíí ṣe, nípa ìtúmọ̀, agbára oyè-àlùfáà.”2
Linda K. Burton, Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, sọ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí agbára oyè-àlùfáà jẹ́ ohun kan tí gbogbo wa fẹ́ nínú ẹbí àti ilé wa, Kíni a nílò láti ṣe láti pè agbára náà sínú ayé wa? Òdodo ara-ẹni ṣe pàtàkì sí níní agbára oyè-àlùfáà.”3
“Tí a bá gbé ara wa sílẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ níwájú Olúwa tí a sì bèère lọ́wọ́ Rẹ̀ láti kọ́ wa, Òun yíò fi hàn wá bí á ó ṣe mú níní àyè wa sí Agbára Rẹ̀ pọ̀ si,” ni Ààrẹ Russell M. Nelson, Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ.4
Àfikún àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni
1 Nífáì 14:14; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:36; 132:20; reliefsociety.lds.org
© 2017 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc.All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/16. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/16 Àyípadà Èdè ti Visiting Teaching Message, June 2017. Yoruba 97926 779