2017
Ìpè sí Iṣẹ́ náà
June 2017


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹfà ọdún 2017

Ìpè sí Iṣẹ́ náà

Àwòrán
Ààrẹ Thomas S. Monson

Nígbàtí Ààrẹ Joseph Smith pe Alàgbà Heber C. Kimball (1801-68) láti ṣí ìlẹ̀kùn ìgbàlà gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere sí England, Alàgbà Kimball gba ìgbámú nípasẹ̀ àwọn ìmọ̀lára àìpé.

Ah, Olúwa, ó kọ , èmi jẹ́ ọkùnrin aláhọ́n ìkálóló, àti pé ní àpapọ̀ mo jẹ́ àìyẹ fún irú iṣẹ́ náà.

Alàgbà Kimball gba ìpè náà bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní fífikún pé: “Àwọn àgbéyẹ́wò wọ̀nyí kò dá mi dúró ní ipá ọ̀nà ojúṣe; ní kété tí mo ní òye ìfẹ́ Bàbá mi Ọ̀run, mo ní ìmọ̀lára ìpinnu kan láti lọ nínú gbogbo wàhálà, nínú ìgbàgbọ́ pé Òun yíò tì mí lẹ́hìn nípa agbára títóbi Rẹ̀, yíò sì fún mi ní gbogbo ìyege tí mo nílò.”1

Ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi tí a pè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ íhínrere ní kíkún, a pè yín sí iṣẹ́ náà nítorípé ẹ̀yin, gẹ́gẹ́bí Alàgbà Kimball, ní ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 4:3) àti pé nítorípé ẹ ṣetán ẹ sì yẹ.

Ẹ̀yin tọkọ-taya àgbà, a pè yín sí iṣẹ́ náà fún ìdí kannáà. Ẹ̀yin, síbẹ̀, kò mú ìfẹ́ láti sìn wá nìkan ṣùgbọ́n ọgbọ́n bákannáà tí a jèrè láti inú àwọn àkókò ti ìrúbọ, ìfẹ́, àti ìrírí tí Bàbá yín ní Ọ̀run lè lò láti fi sí ọkàn àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀ tí wọ́n nwá òtítọ́. Láìsí iyéméjì ẹ ti kọ́ pé a kò lè fẹ́ràn Olúwa nítòótọ́ láéláé bí kò ṣe pé a bá sìn Ín nípa sínsin àwọn ẹlòmíràn.

Sí ìfẹ́ yín láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìhìnrere, ẹ ó fikún ìgbàgbọ́ àti ìforítì, ìgboyà àti ìgbẹ́kẹ̀lé, ìyanjú àti àìdúró, ìpinnu àti ìfarasìn. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n ní ìfarasìn lè mú ìyanu wá ní pápá iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Ààrẹ John Taylor (1808–87) ṣe àròpọ̀ àwọn agbára pàtàkì ti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní ọ̀nà yí: “Irú àwọn ọkùnrin [àti àwọn obìnrin àti àwọn tọkọ-taya] tí a fẹ́ gẹ́gẹ́bí olùgbé ọ̀rọ̀ ìhìnrere yí ni àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn wọn; àwọn ọkùnrin tí wọ́n nbu ọlá fún oyè-àlùfáà wọn; àwọn ọ̀kunrin nínú ẹnití … Ọlọ́run ní ìgbẹ́kẹ̀lé. … A nfẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run[,] … àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ọlá, iyì, ìwà rere àti jíjẹ́ mímọ́.”2

Olúwa ti kéde pé:

Nítorí kíyèsi oko ti funfun tán nísisìnyí fún ìkórè; sì wòó, ẹni tí ó bá fi dọ̀jé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, òun náà ni ó kórè sínú àká kí òun má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó mú ìgbàlà wá fún ẹ̀mí rẹ̀;

“Àti pé ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ àti ìfẹ́, pẹ̀lú fífi ojú sí ògò Ọlọ́run nìkan, mú u yẹ fún iṣẹ́ náà” (D&C 4:4–5).

Ìpè yín wá nípasẹ̀ ìmísí. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ẹni tí Ọlọ́run pè ni ó nmú yẹ. Ẹ ó gba ìranlọ́wọ́ ti ọ̀run bí ẹ ṣe nfi tàdúrà-tàdúrà ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà Olúwa.

Ìlérí dídára tí Olúwa fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ìṣaájú ní àkokò yí, bí ó ti wà nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, yíò jẹ́ tiyín: Èmi yíò lọ ní iwájú yín. “Èmi yíó wà ní ọwọ́ ọ̀tún yín àti ní ọwọ́ òsì, àti Ẹ̀mí mi yíó wà nínú àwọn ọkàn yín, àti àwọn ángẹ́lì mi rọ̀gbà yí i yín ká, láti gbé e yín sókè” (Ẹkọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:88).

Bí ẹ ṣe nsìn, ẹ ó gbé àwọn ìrántí àti ìbáraṣọ̀rẹ́ ayérayé ga. Èmi kò mọ pápá oko kankan èyí tí ó nmú ìkórè ìdùnnú púpọ́ jáde ju pápá iṣẹ́ ìránṣẹ́ lọ.

Nísisìnyí, ọ̀rọ̀ kan fún àwọn alàgbà, arábìnrin, àti àwọn tọkọ-taya, nítorí ìdí yìówù , lè ṣàì parí ìgbà tí a fún wọn ní pápá iṣẹ́ ìránṣẹ́ : Olúwa fẹ́ràn yín. Ó mọyì ìrúbọ yín. Ó mọ nípa ìjákulẹ̀ yín. Ẹ mọ̀ pé Òun ṣì ní iṣẹ́ kan fún un yín láti ṣe. Ẹ máṣe jẹ́ kí Eṣù sọ nkan míran fún un yín. Ẹ máṣe rẹ̀wẹ̀sì; ẹ máṣe ní ìjákulẹ̀; ẹ máṣe sọ ìrètí nù.

Gẹ́gẹ́bí mo ti ṣe àkíyèsí nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ní kété lẹ́hìn tí a pè mí láti darí Ìjọ: Ẹ máṣe bẹ̀rù. Ẹ tújúka. Ọjọ́ ọ̀la jẹ́ mímọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìgbágbọ́ yín.”3 Ìlérí náà ṣì jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀ fún un yín. Nítorínáà ẹ máṣe sọ ìgbàgbọ́ yín nù, nítorí Olúwa kò tíì sọ ìgbàgbọ́ nù nínú yín. Ẹ pa àwọn májẹ̀mú yín mọ́ kí ẹ sì tẹ̀síwájú.

Gbogbo ayé nílò ìhìrere Jésù Krístì. Njẹ́ kí Olúwa bùkún gbogbo àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀—láìka ibi tí a ti sìn sí—pẹ̀lú ọkàn ìránṣẹ ìhìnrere kan.

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Heber C. Kimball, ní Orson F. Whitney, Ìgbé ayé Heber C. Kimball,3rd ed. (1967), 104.

  2. Ìkọ́ni ti ǎwọn Ààrẹ Ìjọ: John Taylor (2001), 73.

  3. Thomas S. Monson, “Ẹ Tújú Ka,” Ensign tàbí Liahona, Oṣù Karun 2009, 92.

Tẹ̀