2017
Àwọn Wolìí láti Tọ́Wa Sọ́nà
September 2017


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́sãn 2017

Àwọn Wolìí láti Tọ́Wa Sọ́nà

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, mo jókòó nínú yàrá Tẹ́mpìlì Salt Lake níbi tí àwọn Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ti npàdé ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ . Mo wòkè ní ara ògiri èyí tí ó dojúkọ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní , níbẹ̀ ni mo sì se àkíyèsí àwọn àwòrán ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ààrẹ ti Ìjọ.

Bí mo se nwò wọ́n, àwọn aṣíwájú mi—Láti orí Wòlíì Joseph Smith (1805–44) sí Ààrẹ Gordon B. Hinckley (1910–2008)—Mo ronú pé, “Báwo ní ìmoore mi ti tó fún ìtọ́nisọ́nà ọkọ̀ọ̀kan wọn”.

Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn ènìyàn nlá ti wọn kò mikàn, tí wọn kò yẹsẹ̀, tí wọn kò kùnà láéláé. Àwọn wọ̀nyí ni ènìyàn Ọlọ́run. Bí mo ṣe nronú nípa àwọn wòlì ọjọ́-òní tí mo ti mọ̀ tí mo sì fẹ́ràn, mo rántí ìgbé ayé wọn, ìhùwàsí wọn, àti àwọn ìkọ́ni pẹ̀lú ìmísí wọn.

Ààrẹ Heber J. Grant (1856–1945) ni Ààrẹ Ìjọ nígbatí a bí mi. Bí mo ṣe nro ìgbé ayé àti àwọn ìkọ́ni rẹ̀, mo gbàgbọ́ pé ìwà kan tí Ààrẹ Grant máa nfi ìgbàgbogbo ṣe àpẹrẹ rẹ̀ ni ìtẹramọ́—ìtẹramọ́ nínú àwọn ohun wọnnì èyí tí ó dára tí ó sì ní ọlá.

Ààrẹ George Albert Smith (1870–1951) ni Ààrẹ Ìjọ ní àkókò ti mo sìn gẹ́gẹ́bí bíṣọ́ọ̀pù ní wọ́ọ̀dù mi ní Ìlú Nlá Salt Lake. Ó ṣe àkíyèsí pé ìjà-líle nlá kan nlọ ní àárín Olúwa àti ọ̀tá. ”Tí ẹ bá dúró ní ẹ̀gbẹ́ ìlà ti Olúwa,” ni o kọ́ni, “ẹyin yíò wà ní abẹ́ agbára rẹ̀ àti pé ẹ kò ní ní ìfẹ́ láti ṣìṣe.”1

A pè mí láti sìn gẹ́gẹ́bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ní 1963 láti ọwọ́ Ààrẹ David O. Mckay (1873–1970) Ó kọ́ni láti máa gba ti àwọn ẹlòmíràn rò nípa ọ̀nà tí ó fi gbé ìgbé ayé rẹ̀. “Jíjẹ́ Krístẹ́nì Tòótọ́ ,” ó sọ pé, “ó jẹ́ ìfẹ́ nínú ìṣe”2

Ààrẹ Joseph Fielding Smith (1876–1972), ọ̀kan lára àwọn ògbóntarìgì akọ̀wé jùlọ nínú Ìjọ , ní jíjẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ihìnrere gẹ́gẹ́bíi ẹ̀kọ́ ìtọ́nisọ́nà ní ìgbé ayé rẹ. Ó ka àwọn ìwé mímọ́ láìsimi àti pé ó ní ìbárẹ́ pẹ̀lú àwọn ìkọ́ni àti ẹkọ́ tí a rí nínú àwọn ojú ewé wọn ju ẹnikẹ́ni tí mo ti mọ̀ ri.

Ààre Harold B. Lee (1899–1973) sìn gẹ́gẹ́bí ààrẹ èèkàn mi nígbà tí mo wà ní ọmọdékùnrin. Ààyò àyọsọ kan tí ó jẹ́ tirẹ̀ ni “ẹ dúró ní àwọn ibi mímọ́, kí ẹ má sì ṣe yẹsẹ̀.”3 Ó gbà àwọn ènìyàn mímọ́ níyànjú láti wà ní ìbámu pẹ̀lú, kí wọ́n ó sì kọ ibi ara sí, àwọn ìṣínilétí Ẹmí Mímọ́.

Mo gbàgbọ́ pé ìtọ́nisọ́nà ẹ̀kọ́ kan nínú ìgbé ayé Ààrẹ Spencer W. Kimball (1895–1985) yíò jẹ́ ìfọkànsìn. Ó fọkànsin Olúwa taratara, láìṣiyèméjì. Ó ní ìfọkànsìn bákannáà sí ìgbé aye ìhìnrere.

Nígbàtí Ààrẹ Ezra Taft Benson (1899–1994) di Ààrẹ Ìjọ, ó pè mí láti sìn gẹ́gẹ́bí Olùdámọ̀ràn rẹ̀ Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní. Ìfẹ́ ni ìtọ́nisọ́nà ẹ̀kọ́ rẹ̀, èyí tí ó papọ̀ sínú ààyò àyọsọ rẹ̀ , tí a ti ẹnu Olùgbàlà sọ: Irú ènìyàn wo ló yẹ kí ẹ̀yin jẹ́? Lõtọ́ ni mo wí fún yín, àní gẹ́gẹ́bí èmí ti rí.”4

Ààrẹ Howard W. Hunter (1907–95) ni ẹni tí ó má nfi ìgbàgbogbo wo ohun tí ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlòmíràn. Títí láé ni ó máa ntẹríba; títí láé ni ó ní ìrẹ̀lẹ̀. Ó jẹ ànfàní fún mi láti sìn gẹ́gẹ́bí Olùdámọ̀ràn rẹ̀ Kejì.

Ààrẹ Gordon B. Hinckley kọ́ wa láti sa ipá wa. O jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára nípa Olùgbàlà àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. Ó kọ́ wa pẹ̀lú ìfẹ́. Sísìn gẹ́gẹ́bí Olùdámọ̀ràn rẹ̀ Ìkínní jẹ́ iyì àti ìbúkún kan fún mi.

Olùgbàlà rán àwọn wòlíì nítorí Ó ní ìfẹ́ wa. Nínú ìpàdé gbogbogbò Oṣù Kẹwã yí, àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò Ìjọ yíò ní ànfàní lẹ́ẹ̀kansi láti ṣe àbápín ọ̀rọ̀ Rẹ̀. À nṣe ojúṣe yí pẹ̀lú ọ̀wọ̀ nlá àti ìrẹ̀lẹ̀.

Bi a ti jẹ́ alábùkún tó pé ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ti Jésù Krístì wà lórí ilẹ̀ ayé àti pé a kọ́ Ìjọ náà sí orí àpáta ìfihàn. Èyí ni àkojá ìhìnrere ti Jésù Krístì.

Njẹ́ kí a lè múrasílẹ̀ láti gba ìfihàn araẹni tí ó nwá lọ́pọ̀lọpọ̀ ní àsìkò ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Njẹ́ kí ọkàn wa lè kún fún ìpinnu tí ó jinlẹ̀ bí a ti ngbé ọwọ́ wa sókè láti ṣe ìmúdúró àwọn wòlíì alààyè àti àwọn àpọ́stélì. Njẹ́ kí a lè di olóye , di gbígbéga, di títunínínú, àti ìfúnnilókun bí a ṣe nfi etí sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ wọn. Àti pé kí a lè ṣetán láti tún ìfarasìn wa sí Olúwa Jésù Krístì ṣe—sí ìhìnrere Rẹ̀ àti iṣẹ́ Rẹ—àti láti gbé ìgbé ayé pẹ̀lú àtúnṣe ìpinnu ní pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ àti ṣíṣe ìfẹ́ Rẹ̀.