Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́sãn 2017.
Ti Ọkàn Kan
Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?
“Olúwa sì pè àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Síónì, nitorí wọ́n wà ní ọkàn kan àti inú kan, wọ́n sì gbé nínú òdodo; kò sì sí òtòṣì kankan ní àárín wọn”(Moses 7:18). Báwo ni a ṣe lè di ọ̀kan?
Alàgbà M. Russell Ballard ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá wí pé: “Ní ọkàn ọ̀rọ̀ èdè òyìnbó ètùtù ni ọ̀rọ̀ náà oókan. Tí gbogbo ènìyàn bá ní òye èyí, kò ní sí ẹnìkẹ́ni tí a kò ní máa ṣe àníyàn nípa rẹ̀, láìṣe ìkàsí ọjọ orí , ẹ̀yà, lákọ-lábo, ẹ̀sìn, tàbí ìbákẹ́gbẹ́ tàbí ìdúró ọrọ̀ ajé. A ó làkàkà láti tẹ̀lé Olùgbàlà kí a máṣe jẹ́ ẹni ibi, aláìláànú, àìlọ́wọ́, tàbí àìkọbiara sí àwọn ẹlòmíràn.”1
Ààrẹ Henry B. Eyring, olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, kọ́ni pé: “Níbi tí àwọn ènìyàn bá ní Ẹ̀mí [náà] pẹ̀lú wọn, [wọ́n] lè ní ìretí ìrẹ́pọ̀ pípé. … Ẹ̀mí Ọlọ́run kìí mú ìjà jade (wo 3 Nífáì 11:29). … Ó ndarí sí àláfíà araẹni àti ìmọ̀lára ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”2
Ní sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpenijà inú ẹbí, Carol M. Stephens, ẹni tí ó sìn bíi Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, sọ pé: “Èmi kò tíì ní láti gbé nínú ìkọ̀sílẹ̀, ìrora àti àìní ààbò tí ó nwá láti inú ìpatì, tàbí ojúṣe tí ó rọ̀mọ́ jíjẹ́ ìyá-àdánìkanwà. Èmi kò ní ìrírí ikú ọmọ kan rí, àìbímọ, tàbí ìfẹ́kúfẹ́ ìbálò-arakannáà. Èmi kò tíì ní láti fi ara da ìlòkulò, àìsàn líle, tàbí bárakú. Ìwọ́nyí kìí ṣe àwọn ànfani gbígbòòrò fún mi.
“… Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àwọn ìdánwò araẹni mi àti àwọn àdànwò … mo ti di olùbárẹ́ pẹ̀lú Ẹni náà tí ó ní òye. … Àti pé ní àfikún, mo ti ní ìrírí gbogbo àwọn àdánwò ayé ikú tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dárúkọ nípa jígí ìwòran ti ọmọbìnrin , ìyá, ìyá-àgbà, arábìnrin, ẹ̀gbọ́n, àti ọ̀rẹ́ kan.
“Ànfàní wa gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run olùpamọ́-majẹ́mú kìí ṣe láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àwọn ìpènijà wa lásán; ó jẹ́ láti fún wa ní ìrẹ́pọ̀ nínú àánú àti ìyọ́nú bí a ṣe nti àwọn ọmọ ẹbí Ọlọ́run míràn lẹ́hìn nínú ìtiraka wọn”3
Àfikún àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni
John 17:20–23; Ephesians 4:15; Mosiah 18:21–22; 4 Nephi 1:15
© 2017 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/17 Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/17 Àyípadà èdè ti Visiting Teaching Message, September 2017. Yoruba 97929 779