Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kọkànlá 2017
Máṣe Bẹ̀rù Láti Ṣe Rere
Olúwa sọ fún wa pé nígbàtí a bá dúró pẹ̀lú ìgbàgbọ́ lórí àpáta Rẹ̀, ìyèméjì àti ẹ̀rù ndínkù; ìfẹ́ láti ṣe rere npọ̀ si.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà pé kí Ẹ̀mí Olúwa ó wà pẹ̀lú wa bí mo ṣe nsọ̀rọ̀ loni. Ọkàn mi kún fún ìmoore sí Olúwa, ẹnití Ìjọ yí jẹ́ tirẹ̀, fun ìmísí tí a ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ nínú àdúra kíkan, àwọn ìwàásù ìmísí, àti orin kíkọ bíi ti àwọn ángẹ́lì nínú ìpàdé àpapọ̀ yí.
Ní Oṣù Kẹrin tí ó kọjá, Ààrẹ̀ Thomas S. Monson fún wa ní ọ̀rọ̀ kan tí ó wọni lọ́kàn káàkiri gbogbo àgbáyé, pẹ̀lú èmi náà. Ó sọ̀rọ̀ nípa agbára Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó rọ̀ wá láti ṣe àṣàrò, jíròrò, kí a sì lo àwọn ìkọ́ni rẹ̀. O ṣe ìlérí pé tí a bá fi ìgbà kan sílẹ̀ fún ṣíṣe àṣàrò ní ojoojúmọ́ kí a sì jíròrò kí a sì pa àwọn òfin tí ó wà nínú Ìwé Mọ́mọ́nì mọ́, a ó ní ẹ̀rí tó ṣe pàtàkì nípa òtítọ́ rẹ̀, àti pé àbájáde ẹ̀rí Krístì alààyè yíò mú wa lọ nínú ààbò ní àwọn ìgbà ewu. (Wo “Agbára ti Ìwé Mọ́mọ́nì,” Liahona, May 2017, 86–87.)
Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín, mo gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì bí ohùn Olúwa sí mi. Àti pé, bákannáà bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín, mo pinnu láti gbọ́ràn sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̃nnì. Nísisìnyí, láti ìgbà tí mo ti wà ní ọ̀dọ́mọkùnrin, mo ti ní ìmọ̀lára ẹ̀rí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pé Bàbá àti Ọmọ fi ara hàn, wọn sì bá Josẹ́fù Smith sọ̀rọ̀, àti pé àwọn àpọ́stélì àtijọ́ wá sí ọ̀dọ̀ Wòlíì Josẹ́fù láti mú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà padàbọ̀ sípò sí Ìjọ Olúwa.
Pẹ̀lú ẹ̀rí náà, mo ti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ojoojúmọ́ fún àádọ́ta ọdún ó lé. Nítorínáà bóyá mo lè ti fi ọgbọ́n rò pé àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ̀ Monson wà fún ẹlòmíràn. Síbẹ̀síbẹ̀, bíi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín, mo ní ìmọ̀lára ìgbani níyànjú ti wòlíì àti pé ìlérí rẹ̀ pè mí láti túbọ̀ tiraka síi. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín ti ṣe ohun tí mo ṣe: gbàdúrà pẹ̀lú èrò inú púpọ̀ síi, jíròrò ìwé mímọ́ dáradára síi, kí ẹ sì gbìyànjú síi gidi láti sin Olúwa àti àwọn ẹlòmíràn fún Un.
Àbájádé ìdùnnú fún mi, àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín, ti jẹ́ ohun tí wòlíì ṣe ìlérí. Àwọn wọnnì lára wa tí wọ́n gba ìmọ̀ràn ìmísí rẹ̀ sí ọkàn ti gbọ́ ohùn Ẹ̀mí dáradára. A ti rí agbára títóbi síi láti ta àdánwò dànù tí a sì ti ní ìmọ̀lára ìgbàgbọ́ títóbi jù nínú Jésù Krístì tí ó jíìnde, nínú ìhìnrere Rẹ̀, àti nínú Ìjọ alààyè Rẹ.
Ní àsìkò kan tí ìrúkèrúdò npọ̀ síi nínú ayé, àwọn àlékún ẹ̀rí wọnnì ti lé iyèméjì àti ẹ̀rù jáde ó sì ti mú ìmọ̀lára àláfíà wá fún wa. Gbígbọ́ ìmọ̀ràn Ààrẹ Monson ti ní àwọn àyọrísí ìyanu méjì mĩràn fún mi: Àkọ́kọ́, Ẹ̀mí tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ ti mú ọgbọ́n níní ìrètí jáde nípa ohun tí ó nbọ̀ níwájú, àní bí ìdàrúpàpọ̀ inú ayé ṣe dàbí pé ó npọ̀ si. Àti pé, èkejì, Olúwa ti fún mi—àti ẹ̀yin—ní ìmọ̀lára kan àní tí ó ga jùlọ nípa ìfẹ́ Rẹ̀ fún àwọn wọnnì nínú ìdàmú. A ti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ púpọ̀ síi láti lọ fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn. Ìfẹ́ náà ti wà ní kókó àárín iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ìkọ́ni ti Ààrẹ Monson.
Olúwa ṣe ìlérí ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn àti ìgboyà sí Wòlíì Josẹ́fù Smith àti Oliver Cowdery nígbàtí àwọn iṣẹ́ tí ó wà níwájú wọn dàbí ìbonimọ́lẹ̀. Olúwa sọ pé ìgboyà tí wọ́n nílò yíò wá láti inú ìgbàgbọ́ wọn nínú Rẹ̀ bí àpáta ìfẹ̀hìntì wọn:
“Ẹ máṣe bẹ̀rù láti ṣe rere, ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí ohunkóhun tí ẹ bá gbìn, ni ẹ̀yin yío ká pẹ̀lú; nítorínáà, bí ẹ̀yin bá fúrúgbìn rere ẹ̀yin yíó ká rere fún èrè yín.
“Nítorínáà, ẹ máṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin agbo kékeré; ẹ ṣe rere; jẹ́ kí ayé àti ọ̀run jùmọ̀ takò yín, nítorí bí ẹ̀yin bá jẹ́ kíkọ́ lé orí àpáta mi, wọn kì yíò lè borí.
“Kíyèsi, èmi kò dáa yín lẹ́bi; ẹ lọ ní ọ̀nà yín kí ẹ má sì ṣe dá ẹ̀ṣẹ̀ mọ́; ẹ ṣe iṣẹ́ ti mo paláṣẹ fún yín pẹ̀lú ọ̀wọ̀.
Ẹ wò mi nínú gbogbo èrò yín, ẹ máṣe ṣiyèméjì, ẹ máṣe bẹ̀rù.
“Ẹ kíyèsí àwọn àpá èyí tí ó wọ̀ ẹ̀gbẹ́ mi, àti pé bákannáà àwọn ojú ìṣó tí ó wà ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi; ẹ jẹ́ olõtọ́, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin ó sì jogún ìjọba ọ̀run” (D&C 6:33–37).
Olúwa sọ fún àwọn olórí Rẹ̀ nípa Ímúpadàbọ̀sípò, Ó sì sọ fún wa, pé nígbàtí a bá dúró pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ní orí àpáta Rẹ, iyèméjì àti ẹ̀rù ndínkù; ìfẹ́ láti ṣe rere yío pọ̀ síi. Bí a ṣe gba ìpè Ààrẹ Monson láti gbìn ẹ̀rí Jésù Krístì sí inú ọkàn wa, a njèrè agbára, ìfẹ́ inú, àti ìgboyà láti lọ sí ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn láìṣe àníyàn fún àwọn aìní ti ara wa.
Mo ti rí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nígbàtí onígbàgbọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ti dojúkọ àwọn àdánwò bíbani-lẹ́rù. Fún àpẹrẹ, mo wà ní Idaho nígbàtí Omi Adágún Teton ya ní Ọjọ́ Karũn, Oṣù Kẹfà 1976. Ògiri omi nlá wá sílẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún sa kúrò ní ilé wọn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ilé àti okùn-òwò parun. Pẹ̀lú ìyanu, iye àwọn ènìyàn tí ó pa kò tó márùndínlógún.
Ohun tí mo rí níbẹ̀, mo ti ríi nígbàkugbà tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bá dúró ṣinṣin ní orí àpáta ẹ̀rí ti Jésù Krísti. Nítorí wọn kò ní iyèméjì pé Ó nṣe àbójútó lórí wọn, wọn di aláìbẹ̀rù. Wọ́n pa àwọn àdánwò ti ara wọn tì láti lọ ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìfẹ́ fún Olúwa, láì bèèrè èrè.
Fún àpẹrẹ, nígbàtí Omi Adágún Teton ya, tọkọ-tayà Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kan nrin ìrìnàjò, ní ọ̀pọ̀ máìlì kúrò ní ilé wọn. Ní áìpẹ́ bí wọ́n ṣe gbọ́ ìròhìn náà ní orí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì, wọn yára padà sí Rexburg. Dípò kí wọ́n lọ sí ilé wọn láti ríi bóyá ó bàjẹ́, wọ́n lọ nwá Bíṣọ́ọ̀pù wọn. Ó wà ní ilé kan tí wọ́n nlò fún gbàgede ìmúpadà. Ó nṣe ìrànwọ́ láti darí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùrànlọ́wọ́ tí wọ́n ndé nínu àwọn ọkọ̀ ilé-ìwé aláwọ̀ yẹ́lò.
Tọkọ-tayà náà rìn lọ bá bíṣọ́ọ̀pù wọ́n sì sọ pé, “A ṣẹ̀ṣẹ̀ padà dé ni. Bíṣọ́ọ̀pù, níbo ni a ti lè lọ láti ṣe ìrànwọ́?” Ó fún wọn ní àwọn orúkọ ẹbí kan. Tọkọ-tayà yí dúró wọ́n nkó ẹrọ̀fọ̀ àti omi jáde nínú ilé kan lẹ́hìn òmíràn. Wọ́n ṣiṣẹ́ láti ìdájí di alẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Ní ikẹhìn wọn gba ìsinmi díẹ̀ láti lọ wo ilé ti ara wọn. Ó ti lọ nínú ìkún omi náà, láì fi ohunkóhun sílẹ̀ láti túnṣe. Nítorínáà wọ́n yípadà kíákíá láti tún lọ bá bíṣọ́ọ̀pù wọn. Wọ́n bèèrè, “Bíṣọ́ọ̀pù, Njẹ́ ẹ ní ẹnìkan fún wa láti ràn lọ́wọ́?”
Ìyanu ti ìgboyà jẹ́jẹ́ àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ náà—ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì—tún ti ṣẹlẹ̀ léraléra ní ààrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún jákèjádò gbogbo àgbáyé. Ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ burúkú ti inúnibíni àti àwọn àdánwò ní ìgbà Wòlíì Josẹ́fù Smith ní Missouri. Ó ṣẹlẹ̀ bí Brigham Young ṣe darí àwọn àkólọ láti Nauvoo àti pé lẹ́hìnnáà tí ó pè àwọn ènìyàn mímọ́ lọ sí àwọn ibi aṣálẹ̀ ní gbogbo ìwọ̀-oòrùn United States, láti ran ara wọn lọ́wọ́ láti dá Síónì sílẹ̀ fún Olúwa.
Tí ẹ bá ka àkọsílẹ̀ ìwé-ìròhìn ti àwọn olùlànà wọnnì, ẹ ó ri ìyanu ìgbàgbọ́ tí ó nlé iyèméjì àti ẹ̀rù jáde. Ẹ ó sì ka nípa àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n nfi ìfẹ́ inú ti ara wọn sílẹ̀ láti ran àwọn ẹlòmìràn lọ́wọ́ fún Olúwa, kí wọn to padà sí ọ̀dọ̀ àgùtàn tiwọn tàbí sí oko tiwọn tí ó wà ní àìro.
Mo rí irú ìyanu kannáà ní ọjọ́ kúkúrú díẹ̀ sẹ́hìn ní àsẹ́hìnbọ̀ ìsẹ́lẹ̀ ìjì olóró ní Puerto Rico, Saint Thomas, àti Florida, níbití àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ti parapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọ míràn, ẹgbẹ́ ìletò ìbílẹ̀, àti àwọn ìṣètò gbogbogbò láti bẹ̀rẹ̀ ìtiraka àtúnṣe.
Bíi ti àwọn ọ̀rẹ́ mi ní Rexburg, tọkọ-tayà kan tí kìí ṣe ọmọ ìjọ ní Florida dojúkọ ríran ìletò lọ́wọ́ ju ṣíṣe iṣẹ́ lórí ohun-iní ti ara wọn. Nígbàtí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn kan ṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú igi méjì tí ó dí ojú ọ̀nà mọ́tò, lọ́kọ-láyà náà ṣe àlàyé pé wọ́n ní ìbomọ́lẹ̀ dé bi pé wọ́n yípadà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, níní ìgbàgbọ́ pé Olúwa yíò pèsè ìrànwọ́ tí wọ́n nílò nínú ilé ti ara wọn. Lẹ́hìnnáà ọkọ rẹ̀ ṣe àbápín pé kí àwọn ọmọ Ìjọ tó dé pẹ̀lú àtìlẹhìn, lọ́kọ-lọ́yà náà ti ngbàdúrà. Wọ́n ti gba ìdáhùn pé ìrànlọ́wọ́ yíò wá. Ó wá ní àárín wákàtí díẹ̀ ti ìdánilójú náà.
Mo ti gbọ́ ìròhìn pé áwọn kan ti npe àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí wọ́n nwọ ẹ̀wù Àwọn Ọwọ́ Ìrànlọ́wọ́ ní “Àwọn Ángẹ́lì Yẹ́lò.” Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ikẹ̀hìn kan gbé mọ́tò rẹ̀ lọ́ fún àtúnṣe, àti pé ọkùnrin tí ó nba ṣe ṣe ìjúwe “ìrírí ti ẹ̀mí” tí òun ní nígbàtí àwọn ènìyàn nínú ẹ̀wù yẹ́lò gbé àwọn igi kúrò nínú àgbàlá rẹ̀ àti pé ní gbà náà, ó sọ pé, wọ́n “kọ orin kan fún mi nipa jíjẹ́ ọmọ Ọlọ́run.”
Olùgbé Florida míràn—bákannáà tí kìí ṣe ti ìgbàgbọ́ wa—sọ pé àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn wá sí ilé òun nígbàtí òun nṣiṣẹ́ nínú ọgbà òun tó ṣòfo àti pé òun ní ìbòmọ́lẹ̀, ìgbónà ju, òun sì fẹ́rẹ̀ máa ké. Àwọn abániṣiṣẹ́-ọ̀fẹ́ náà dásílẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “iṣẹ́ ìyanu mímọ̀ kan.” Wọ́n sìn kìí ṣe pẹ̀lú akíkanjú nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀rín àti ọ̀yàyà, láì gba ohunkóhun padà.
Mo rí akínkanjú mo sì gbọ́ ẹ̀rín náà nígbàtí, mo bẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ní Florida wò ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé kan. Wọ́n wọ aṣọ yẹ́lò pẹ̀lú àmì “Ọwọ́ Ìrànlọ́wọ́.” Àwọn abániṣiṣẹ́-ọ̀fẹ́ náà dáwọ́ iṣẹ́ wọn dúró tó láti jẹ́ kí nbọ̀ àwọn kan lọ́wọ́. Wọ́n sọ pé ọgọ́ta àwọn ọmọ ìjọ láti èèkàn wọn ní Georgia ti dá ètò sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ̀ ìgbanilà ní Florida ní alẹ́ tó ṣíwájú.
Wọ́n fi Georgia sílẹ̀ ní aago mẹrin ìdájí, wọn wakọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí, wọn ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́ àti títí di alẹ́, wọ́n sì ṣètò láti ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kansi ní ọjọ́ kejì.
Wọ́n ṣe àpèjúwe gbogbo rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rín àti àwàdà dáadáa. Wàhálà kanṣoṣo tí mo fura sí ni pé wọ́n fẹ́ dáwọ́ dídúpẹ́ lọ́wọ́ wọn dúró kí wọ́n lè padà sí ẹnu iṣẹ́. Ààrẹ èèkàn náà ti tún bẹ̀rẹ̀ sí lo agégi rẹ̀ ó sì nṣiṣẹ́ lórí igi kan tí ó ṣubú lulẹ̀ tí bíṣọ́ọ̀pù kan sì nyí apá igi náà bí a ṣe dé inú ọkọ̀ láti lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ikọ̀ agbanilà tí ó tẹ̀le.
Ṣíwájú ní ọjọ náà, bí a ṣe jáde kúrò ní ibi tí ó tẹ̀le náà, ọkùnrin kan rìn wá sí ibi ọkọ̀, ó ṣí ate rẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wa fún àwọn abániṣiṣẹ́-ọ̀fẹ́ náà. Ó sọ pé, “Èmi kìí ṣe ọmọ ìjọ yín. Èmi kò le gbàgbọ́ ohun tí ẹ ti ṣe fún wa. Ọlọ́run yío bùkún yín.” Abániṣiṣẹ́-ọ̀fẹ́ LDS tí ó dúró nítòsí rẹ̀ rẹrĩn ó sì gbọn àwọn èjìká rẹ̀ bíì pé oríyìn kankan kò tọ́ sí wọn.
Nígbàtí àwọn abániṣiṣẹ́-ọ̀fẹ́ láti Georgia ti dé láti ran ọkùnrin yí lọ́wọ́ ẹni tí kó lè gbà á gbọ́, ọgọọgọ́rũn àwọn Èníyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti ihà ibití ó ní ìdààmú gidi ní Florida ti lọ sí ibòmíràn bí ọgọọgọ́rũn máìlì nínú Florida níbití wọ́n gbọ́ pé àwọn ènìyàn ti ní ìpalára jùlọ.
Ní ọjọ́ náà mo rántí mo si ní òye dáradára sí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì ti Wòlíì Josẹ́fù Smith: “Ẹnití ó bá kún fún ìfẹ́ Ọlọ́run, kìí ní ìtẹ́lọ́rún pẹ̀lú bíbùkún ẹbí tirẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n onirúurú káàkiri gbogbo àgbáyé, ní ìtara láti bùkún gbogbo ìran ènìyàn” (Teachings of Presidents of the Church: Joseph Smith [2007], 426).
A rí irú ìfẹ́ báyìí nínú ayé àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn níbi gbogbo. Ní gbogbo ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ àjàlù bá wà níbikíbi ní àgbáyé, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ndáwó wọ́n sì nṣe iṣẹ́-ọ̀fẹ́ sí ìtiraka ti Ìjọ ní ṣíṣe àmójútó. A kìí sáàbà nílò ẹ̀bẹ̀ kankan. Lódodo, ní àwọn ìgbà míràn, a ní láti sọ fún àwọn wọnnì tí ó fẹ́ ṣe iṣẹ́-ọ̀fẹ́ láti dúró ní rírin ìrìnàjò lọ sí ibi ìmúpadà títí tí àwọn tí wọ́n nṣe ìdarí iṣẹ́ náà yíò fi ṣetán láti gbà wọ́n.
Ìfẹ́ inú náà láti bùkúnni jẹ́ èso àwọn ènìyàn tí wọ́n njèrè ẹ̀rí Jésù Krístì, ìhìnrere Rẹ̀, Ìjọ Rẹ̀ tí a mú padàbọ̀ sípò, àti wòlíì Rẹ̀. Èyí ni ìdí tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run kìí fi ṣiyèméjì tàbí bẹ̀rù. Èyí ni ìdí tí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere fi nṣe ìṣẹ́-ọ̀fẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn ní gbogbo igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé. Èyí ni ìdí tí àwọn òbí fi ngbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Èyí ni ìdí tí àwọn olórí fi npe àwọn ọ̀dọ́ wọn níjà láti gba ìbéèrè Ààrẹ Monson láti ri ara wọn sínú Ìwé Mọ́rmọ́nì sí ọkàn. Èso nwá kìí ṣe nípa rírọni àwọn olórí ṣùgbọ́n nípa kí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìṣe lórí ìgbàgbọ́. Ìgbàgbọ́ náà—tí a bá fi sí ìṣe—èyí tí ó nbéèrè fún ẹbọ àìmọ-ti-araẹni nìkan—nmú ìyípadà ọkàn wá tí yíò fi àyè gbà wọ́n láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ọkàn wa, síbẹ̀, njẹ́ yíyípadà bí a ṣe ntẹ̀síwájú láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wòlíì. Bí a bá dáwọ́ ìgbìyànjú dúró lẹ́hìn ìtiraka líle kan, àyípadà náà yíò parẹ́.
Àwọn olódodo Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti mú ìgbàgbọ́ wọn nínú Olúwa Jésù Krístì pọ̀ síi, nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nínú ìmúpadàbọ̀sípò àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà nínú Ìjọ otítọ́ Rẹ̀. Ẹ̀rí tí ó npọ̀ síi náà ti fún wa ní ìgboyà títóbi síi àti àníyàn fún àwọn ọmọ Ọlọ́run míràn. Ṣùgbọ́n àwọn ìpènijà àti àwọn ànfàní ìwájú yíò fẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ.
A kò lè rí àwọn àsọyé tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n a mọ àwòràn nlá náà. A mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, ayé yíò wà nínú ìdàmú. A mọ̀ pé ní àárín èyíkéyìí wàhálà tí ó bá wá, Olúwa yíò ṣíwájú àwọn olódodo Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti gbé ìhìnrere Jésù Krístì lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátàn, èdè, àti àwọn ènìyàn. A sì mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ti Olúwa yíò jẹ́ yíyẹ àti mímúrasílẹ̀ láti gbà Á nígbàtí Ó bá dé lẹ́ẹ̀kansi. A kó níláti bẹ̀rù.
Nítorínáà, bí a ṣe ti mú ìgbàgbọ́ àti ìgboyà dàgbà nínú ọkàn wa tẹ́lẹ̀rí, Olúwa nfẹ́ púpọ síi láti ọ́wọ́ wa—àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ìran lẹ́hìn wa. Wọn yíò nílò láti ní agbára jù àti ní ìgboyà jù nítorí wọn yíò ṣe àwọn ohun tí ó tóbi jù àti èyí tí ó le jù bí àwa ti ṣe. Wọn yíò sì dojúkọ àtakò tí ó pọ̀ síi láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá ẹ̀mí wa.
Ọnà sí níní ìrètí bí a se ntẹ̀síwájú ni a nfi fúnni láti ọwọ́ Olúwa: “Ẹ wò mí nínú gbogbo èrò; ẹ má ṣe iyèméjì, ẹ máṣe bẹ̀rù ” (D&C 6:36). Ààrẹ Monson sọ fún wa bí a ó ti ṣe èyíinì. A ní láti jíròrò kí a sì lo Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì. Gbàdúrà nígbà gbogbo. Jẹ́ onígbàgbọ́. Sin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn, okun, àti agbára wa. A níláti gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo agbára ọkàn wa fún ẹ̀bùn ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì (wo Moroni 7:47–48). Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a níláti dúró láìyẹsẹ̀ kí a sì ní ìtẹramọ́ ní títẹ̀lé ìmọ̀ràn ti wòlíì.
Nígbàtí ọ̀nà náà bá ṣòro, a lè gbáralé ìlérí Olúwa— ìlérí tí Ààrẹ Monson ti rán wá létí rẹ̀ nígbàtí ó máa nfi ìgbàkũgbà ṣe àtúnsọ àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà wọ̀nyí: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà yín, níbẹ̀ ni èmí ó wà bákannáà, nítorí Èmi ó lọ níwájú yín. “Èmi yíó wà ní ọwọ́ ọ̀tún yín àti ní ọwọ́ òsì, àti Ẹ̀mí mi yíó wà nínú àwọn ọkàn yín, àti àwọn ángẹ́lì mi rọ̀gbà yí i yín ká, láti gbé e yín sókè” (Ẹkọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:88
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Olúwa nlọ níwájú yín nígbàkũgbà tí ẹ̀ bá nṣe iṣẹ́ Rẹ̀. Nígbàmíràn ẹ ó jẹ́ ángẹ́lì tí Olúwa rán láti gbé àwọn míràn sókè. Nígbàmíràn ẹ ó jẹ́ ẹnikan tí àwọn ángẹ́lì nyíká láti gbé sókè. Ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà ẹ ó ní Ẹ̀mí Rẹ̀ láti wà nínú ọkàn yín, bí ẹ ṣe ngba ílérí ní gbogbo ìsìn oúnjẹ Olúwa. Ẹ níláti pà àwọn òfin Rẹ mọ nìkan ni.
Àwọn ọjọ́ dídára jùlọ wà níwájú fún ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Àtakò yíò fún ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì ní okun síi, bí ó ṣe wà láti àwọn ọjọ́ Wòlíì Josẹ́fù Smith. Ìgbàgbọ́ nṣẹ́gun ẹ̀rù nígbà gbogbo. Dídúró papọ̀ nmú ìrẹ́pọ̀ jáde wá. Àti pé àwọn àdúrà yín fún àwọn aláìní ni Ọlọ́run olùfẹ́ni kan ngbọ́ tí Ó sì ndáhùn. Òun kìí sùn bẹ́ẹ̀ni kìí tògbé.
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run Bàbá wà láàyè Ó sì nfẹ́ kí ẹ wá sílé lọ́dọ̀ Rẹ̀. Èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì tòtítọ́. O mọ̀ yín, Ó ní ìfẹ́ yín, Ó sì nṣe àmójútó yín. Ó ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bàbá Ọ̀run. Títẹ̀lé E nínú ayé yín àti nínú iṣẹ́ ìsìn yín sí àwọn ẹlòmíràn ni ọ̀nà kanṣoṣo sí iyè àìnípẹ̀kun.
Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ mo sì fi ìbùkún mi àti ìfẹ́ mi sílẹ̀ pẹ̀lú yín. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín
© 2017 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/17 Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/17 Àyípadà ti First Presidency Message, November 2017. Yoruba. 97929 779