Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kọkànlá Ọdún 2017
Àwọn Arábìnrin Mẹ́ta
À ni ojúṣe ipò ọmọẹ̀hìn fún ara wa, àti pé ó ní ohun díẹ̀—tí ó bá wà rárá—láti ṣe pẹ̀lú ọ̀nà tí àwọn míràn fi nṣe sí wa.
Ẹ̀yin arábìnrin ọ̀wọ́n, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, láti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò pẹ̀lú abala àwọn obìnrin káàkiri àgbáyé ṣe pàtàkì ó sì jẹ́ ìyanu. Ẹ ròó pe: àwọn arábìnrin gbogbo ọjọ́ orí, ti àtilẹ̀wá, àwọn orílẹ̀-èdè, àti àwọn èdè nínú ìrẹ́pọ̀ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ fún Olúwa Jésù Krístì.
Bí a ti pàdé olólùfẹ́ wolíì, Ààrẹ Thomas S. Monson láìpẹ́, ó fihàn sí wá bí òun ṣe ní ìfẹ́ Olúwa tó. Mo sì mọ̀ pé Ààrẹ Monson fi ìmoore hàn fún ìfẹ́ yín, àdúrà yín, àti ìfọkànsìn yín sí Olúwa.
Ní ìgba kan tipẹ́tipẹ́ sẹ́hìn ní ilẹ̀ jìnjìn ni ẹbí àwọn aràbìnrin mẹ́ta kan ngbé.
Arábìnrin àkọ́kọ́ ní ìbànújẹ́. Ohun gbogbo láti imú rẹ̀ dé àgbọ̀n àti láti awọ ara rẹ̀ dé èékán dàbíi pé kò dára lójú rẹ̀ rárá. Nígbàtí ó bá sọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbàmíràn njáde wá ní ọ̀nà-òdì, àwọn ènìyàn sì máa nrẹrin. Ńigbàtí wọ́n bá kẹ́gàn rẹ̀ tàbí “gbàgbé” láti pè é fún ohunkan, ó máa nbojújẹ́, yíò sì rìn kúrò, yíò sì wá ibi ìkọ̀kọ̀ kan níbití ó ti lè fi àmìn inúbíbàjẹ́ hàn kí ó sì ròó pé kíni ìdí tí ayé fi di àìnírètí àti àìlójútùú.
Arábìnrin kejì ni o nbínú. Ó rí ararẹ̀ bí ẹni to jáfáfá gidi, ṣùgbọ́n ẹlòmíràn máa nwà nígbàgbogbo tí ó ngba jùú lọ nínú àwọn ìdánwò ní ilé-ìwé. Ó rò ararẹ̀ bí aláwàdà, dídára, ológe, àti afanimọ́ra. Ṣùgbọ́n nígbagbogbo, o dàbíi pé ẹnìkan wà tó láwàdà jùlọ, dára jùlọ, loge jùlọ, tàbí fanimọ́ra jùlọ.
Òun kò ṣe àkọ́kọ́ rí nínú ohunkóhun, àti pé òun kò lè farada èyí. Ko yẹ̀ kí ìgbé ayé rí báyìí!
Ní ìgbà míràn ó nbínú sí àwọn míràn ó sì ndàbíi pé òun nfi ìgbàgbogbo ní ìmí kan kúró ní ìbínú nípasẹ̀ ohun kan tàbí òmíràn.
Bẹ́ẹ̀ni, èyí kò mu lẹ́ran ìfẹ́ lára tàbí lókìkí. Ìgbà míràn ó nwayínkeke, ó ndi ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀ pọ̀ si, ní ìronú pé, “Ilé ayé kò dáa!”
Lẹ́hìnnáà ni arábìnrin kẹ́ta wà Yàtọ̀ sí arábìnrin rẹ oníbànújẹ́ àti olùbínú, ara tirẹ̀—ya gágá, Kìí ṣe torí pé ó gbọ́n pépé tàbí ó lẹ́wà si tàbí ó lágbára ju àwọn arábìnrin rẹ̀ lọ̀. Rárá, àwọn ènìyàn nígbà míràn nké mọ́ bákannáà. Wọ́n nfi ìgbà míràn fi ohun tí ọ́ wọ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí ohun tí ó nsọ. Àwọn ènìyàn nígbàmíràn nsọ àwọn ohun àbùkù nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí eyikeyi rẹ dun òun jù o dunnú Kìí ṣe torí pé ó gbọ́n pépé tàbí ó lẹ́wà si tàbí ó lágbára ju àwọn arábìnrin rẹ̀ lọ̀. Rárá, àwọn ènìyàn nígbà míràn nké mọ́ bákannáà. Wọ́n nfi ìgbà míràn fi ohun tí ọ́ wọ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí ohun tí ó nsọ. Àwọn ènìyàn nígbàmíràn nsọ àwọn ohun àbùkù nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí eyikeyi rẹ dun òun jù.
Arábìnrin yí fẹ́ràn láti kọrin. Kò ní ohùn òkè, àti pé àwọn ènìyàn nrẹrin nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí kò da dúró. Òun yíò sọ pé, èmi kò ní jẹ́ kí àwọn ènìyàn míràn àti èrò wọn dá mi dúró ní kíkọrin!”
Òdodo ìbẹ̀ gan an pé ó tẹra mọ́ kíkọrin mú kí arábìnrin rẹ̀ àkọ́kọ́ banújẹ́ àti pé arábìnrin kejì bínú.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kọjá, nígbẹ̀hìn arábìnrin kọ̀ọ̀kan dé òpin àsìkò wọn lórí ilẹ̀ ayé.
Arábìnrin àkọ́kọ́, tí ó ri lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansi pé kò sí àdínkù àwọn ìjákulẹ̀ ní ìgbé ayé, kú nígbẹ̀hìn nínú ìbànújẹ́.
Èkeji náà, ẹni tí ó nfi ojoojúmọ́ rí ohun titun kan láti kóríra, kú nínú ìbínú
Àti pé arábìnrin kẹta tí ó lo ìgbé ayé rẹ̀ ni kíkọ orin rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ àti ẹ̀rín tó dájú ní ojú rẹ̀, kú tayọ̀tayọ̀.
Bẹ́ẹ̀ni, ìgbẹ́ ayé kò rọrùn bẹ́ẹ̀ rárá, àti pé àwọn ènìyàn ko wà ní ọ̀nà-kanṣoṣo gẹ́gẹ́bí àwọn arábìnrin mẹta inú ìtàn yí. Ṣùgbọ́n àní àwọn àpẹrẹ tó kọjá àlà bíi ti ìwọ̀nyí lè kọ́ wa ní ohun kan nípa ara wa. Tí ẹ bá jẹ́ bí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa, ẹ lè ti dá apákan ní ara yín mọ̀ ní ọ̀kan, ẹ̀jì, tàbí bóyá gbogbo awọn arábìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí a wo ọ̀kọ̀ọ̀kan dáadáa. Ẹ jẹ́ kí a wo ọ̀kọ̀ọ̀kan dáadáa.
Olùjìyà náà
Arábìnrin ákọ́kọ́ rí ara rẹ̀ bí olùjìyà kan—gẹ́gẹ́bí ẹnìkan tí wọ́n ṣiṣẹ́ lé lórí.1 Ó dàbí ẹni pé ohunkan lẹ́hìn òmíràn nṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ tí ó nmu banújẹ́. Pẹ̀lú ìrìnsí ayé yí, ó nfún àwọn míràn ní agbára lórí bí òun ṣe nní ìmọ̀lára sí àti ìhùwàsí. Nígbàtí a bá ṣe èyí, wọ́n ndarí wa kiri nípa gbogbo ìjì ìmọ̀—àti pé ní ọjọ́ ìgbékalẹ̀ ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn tó wà yí, ìjì wọnnì njà ní agbára líle.
Ẹ̀yin arábìnrin ọ̀wọ́n, kíni ìdí tí ẹ fi gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ ìdùnnú yín fún ẹnìkan, tàbí àkopọ̀ àwọn ẹnì tì kò ní aájò bíótiwù kó mọ nípa yín tàbí ìdùnnú yín?
Tí ẹ bá nṣèyọnu nípa ohun tí àwọn ènìyàn míràn bá sọ nípa yín, njẹ́ kí ndá àbá aporó yí: ẹ rántí ẹni tí ẹ jẹ́. Ẹ rántí pé ẹ̀yin ni ilé-ọba ti ìjọba Ọlọ́run, àwọn ọmọbìnrin Òbí Ọ̀run, ẹnití ó jọba jákèjádò gbogbo ayé.
Ẹ ni ìdánimọ̀ ti ẹ̀mí Ọlọ́run. Ẹ ní àwọn ẹ̀bùn tó tayọ tí ó wá látilẹ̀ nínú ìṣẹ̀dá ti ẹ̀mí yín àti èyí tí ó ngbèrú ní ìgbà yíyára ti ìṣíwájú ayé. Ẹ̀yin ni ọmọ aláàánú wa àti Bàbá ayérayé ní Ọ̀run, Olúwa ọmọ ogun, Ẹni tí ó dá gbogbo ayé, tẹ́rẹrẹ ìràwọ̀ yíká gbogbo àyè, tí ó sì fi ìràwọ̀ tó yí ọ̀run ká sí ibi tí a yàn fún wọn.
Ọwọ́ Rẹ̀ ni ẹ wà.
Ọwọ́ tó dára jùlọ
Ọwọ́ ìfẹ́ni.
Ọwọ́ tó ntọ́jú.
Kò sí ohunkóhun ti ẹnikẹ́ni lè sọ nípa yín tí o lè yí èyí padà. Ọ̀rọ̀ wọn kò nítumọ̀ ní ìfiwé sí ohun ti Ọlọ́run ti sọ nípa yín.
Ojúlówó Ọmọ Rẹ̀ ni yín.
Ó fẹ́ràn yín.
Àní nígbàtí ẹ bá kọsẹ̀, àní nígbàtí ẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ràn yín. Tí ẹ bá ní ìmọ̀lára àdánù, ìpatì, tàbí ìgbàgbé—ẹ máṣe bẹ̀rù. Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, láti ọwọ́ Greg K. Olsen Òun yíò gbée yín lé èjìká Rẹ̀. Òun yíò gbé yín lọ Sílé.2
Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ wọ̀nyí wọ inú ọkàn yín jinlẹjinlẹ. Ẹ̀yin ó sì ri pé ìdí púpọ̀ wà tí kò fi yẹ kí a ni ìbànújẹ́, nítorí ẹ ní àyànmọ́ ayérayé láti mú ṣẹ.
Àyànfẹ́ Olùgbàlà àgbáyé fi ẹ̀mí Rẹ̀ fún yín kí ẹ lè yàn láti mú àyànmọ́ náà jẹ́ òtítọ́. Ẹ lè ti gbé orúkọ Rẹ̀ lé orí ara yín; ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ ni ẹ jẹ́. Àti pé nítorí Rẹ̀, ẹ lè wọ ara yín láṣọ ògo ayérayé.
Olùkóríra náà
Arábìnrin kejì bínú sí ayé. Bíi ti arábìnrin rẹ̀ tó banújẹ́, òun ní ìmọ̀lára pé gbogbo àwọn wàhálà inú ayé rẹ̀ ni ó ti ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn wá. Ó dá ẹbí rẹ̀ lẹ́bi, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ọ̀gá rẹ̀ àti ẹlẹgbẹ́ ibi iṣẹ́, ọlọpa, aláàdúgbò, olórí Ìjọ, ohun ọ̀ṣọ́ ìgbàlódé, agbára iná òòrùn, àti àìní oríre tó tẹ́ pẹpẹ. Ó sì fi mọ́ gbogbo wọn.
Kò ronú nípa ara rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ẹni burúkú. Dípò èyí, ó ní ìmọ̀lára pé òun ndúró fún ara òun nìkan ni. Gbogbo àwọn míràn, ni ó gbàgbọ́ pé, wọ́n ní ìwà àdánìkanjẹ, àrakàn, àti ìkoríra. Òun, ní ọ̀nà míràn, ní ìwurí nípa èrò rere—ìdáláre, ìṣòtítọ́, àti ìfẹ́.
Ó dunni pé, ọ̀nà ìronú arábìnrin tó nbínú yí ti wọ́pọ̀ jù. A ṣe àkíyèsí yi ní ìwáàdí àìpẹ́ tí ó fi ìjà ní àárín àwọn ẹgbẹ́ olórogún hàn. Gẹ́gẹbí apákan ìwáàdí, àwọn olùwáàdí ṣe ìwánilẹ́nuwò fún àwọn ará Palẹ́stínà àti Ísáẹ́lì ní Míddle East àti ará Republic àti Democrat ní United States. Wọ́n ṣàwárí pé “ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn rò pé ẹgbẹ́ tiwọn ni ó [ní] ìwúrí nípasẹ̀ ìfẹ́ ju ìkoríra, ṣùgbọ́n nígbàtí wọ́n bèèrè ìdí tí ẹgbẹ́ orogún wọn fi [wà] nínú ìjà, [wọ́n] nawọ́ sí ìkóríra bíi kókó ìwúrí àwọn ẹgbẹ́ [míràn] .”3
Ní ọ̀nà míràn, ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹgbẹ́ rònú nípa ara wọn bí “ẹni rere” —dídára, inúrere, àti òtítọ́. Ní òdì kejì, wọ́n rí orogún wọn bí “ẹni búburú” —aláìmọ̀kan, aláìlóòtọ́, òpùrọ́, àní ẹni ibi.
Ní ọdún tí a bí mi, ayé kún fún ogun tó burú jáì tí ó fa ìrora ìbànújẹ́ àti ìkorò tó munilómi fún ayé. Ogun yí bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ àkójọ àwọn ènìyàn láti orílẹ̀ èdè mi—àwọn ènìyàn tí wọ́n fi àwọn àkójọ kan hàn bí ibi tí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú sí ìkórira sí wọn.
Wọ́n pa àwọn wọnnì tí wọn kò fẹ́ràn lẹ́nu mọ́. Wọ́n fi wọ́n ṣẹ̀sín wọ́n sì ṣe wọ́n játijàti. Wọ́n rí wọn bí ayédèrú—àní ní ìdínkù sí ẹlẹ́ran ara. Nígbà tí ẹ bá ti rẹ àwọn àkójọ ènìyàn kan sílẹ̀, ó lè dàbí pe ẹ ndá àwọn ọ̀rọ̀ láre àti ìṣe ìjà-agbára lóri wọn.
Mo súnrakì láti ronú nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ogun sẹ́ntúrì sẹ́hìn ní Germany.
Nígbàtí ẹnìkan bá takò tàbí ṣe àìfaramọ́ wá, ó lè tanni láti ṣèbí pé ohunkan gbọ́dọ̀ ṣe wọ́n. Àti pé láti bẹ̀ ni ìṣísẹ̀ kékeré láti lẹ èrò tó burújáì sí ọ̀rọ̀ wọn àti ìṣe.
Bẹ́ẹ̀ni, a gbọ́dọ̀ dúró fún ohun tótọ́ ní ìgbàgbogbo, àwọn ìgbà kan sì wà nígbàtí a gbọ́dọ̀ gbé ohùn wa sókè fún ìdásílẹ̀ náà. Bákannáà, nígbàtí a bá ṣeé pẹ̀lú ìbínú tàbí ìkoríra nínú ọkàn wa—nígbàtí a bá ké mọ́ àwọn ẹlòmíràn láti pa wọ́n lára, mu wọn ṣẹ̀sín, tàbí pa wọ́n lẹnu mọ́—àwọn àye wà pé a ko ṣeé nínú òdodo.
Kíni Olùgbàlà kọ́ni?
Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe õre fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò tí wọn nṣe inúnibíni sí yín;
““Kí ẹ̀yin ó lè jẹ́ ọmọ Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run.”4
Èyí ni ọ̀nà Olùgbàlà. Òun ni ìṣísẹ̀ àkọ́kọ́ ní jíjá ìdèná tí ó ndá ìbínú púpọ̀ sílẹ̀, ìkóríra, yíyàsọ́tọ̀, àti ìjà ipá sílẹ̀ ní ayé.
“Bẹ́ẹ̀ni,” ẹ lè sọ pé, “Èmi yíò ní ìfẹ́ láti fẹ́ràn àwọn ọ̀tá mi—bí wọ́n bá lè ní ìfẹ́ láti ṣe bákannáà.”
Ṣùgbọ́n èyí ko bọ́ si, ṣé ó bọ́ si? À ni ojúṣe ipò ọmọẹ̀hìn fún ara wa, àti pé ó ní ohun díẹ̀—tí ó bá wà rárá—láti ṣe pẹ̀lú ọ̀nà tí àwọn míràn fi nṣe sí wa. À nní ìrètí gbangba pé wọn yíò ní òye àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ní àbábọ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ wa fún wọn dá wà láìsí ìmọ̀ara tí wọ́n ní wa.
Bóyá ìtiraka wa láti fẹ́ràn àwọn ọ̀tá wa yíò rọ̀ wọ́n lọ́kàn kí ó sì fún wọn lágbára láti ṣe rere. Bóyá kò ní bọ́ si. Ṣùgbọ́n èyí kò yí ìfarasìn wa láti tẹ̀lé Jésù Krístì padà.
Nítorínáà, gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì, àwa o fẹ́ràn àwọn ọ̀tá wa.
Àwa ó borí ìbínú tàbí ìkóríra.
A ó kún ọkàn wa pẹ̀lú ìfẹ́ fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
Àwa o nawọ́ jáde láti bùkún àwọn ẹlòmíràn kí a sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn—àní àwọn wọnnì tí wọ́n lè “fi àrankàn bá [wa] lò, tí wọ́n nṣe inúnibini sí [wa].”5
Ojúlówó Ọmọẹ̀hìn Náà
Arábìnrin kẹ́ta dúró bí ojúlówó ọmọẹ̀hìn ti Jésù Krístì. Ó ṣe ohun kan tí ó lè le koko láti ṣe—ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àní ní ojú ìṣẹ̀sín àti ìṣòro. Ní ọ̀nà kan ó dúróti ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti ìrètí, ní àìka ẹ̀gàn àti àbùkù ní àyíká rẹ̀ sí. O gbé ìgbé ayé aláyọ̀, kìí ṣe nítorí pé àwọn ipò rẹ̀ jẹ́ aláyọ̀ ṣùgbọ́n òun jẹ́ aláyọ̀.
Kò sí ẹnìkan lára wa tí ó la ìrìnàjò ayé kọjá láìsí àtakò. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipá tí ó ngbìyànjú láti fà wá kúrò, báwo ni a ṣe ntẹramọ́ fífi ìràn wa lé orí ìlérí ìdùnnú ológo sí àwọn olódodo?
Mo gbàgbọ́ pé ìdáhùn náà ni a lè rí nínú àlá kan tí wòlíì kan lá ní, ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́hìn. Orúkọ wòlíì náà ni Léhì, àti pé àlá rẹ̀ ni a kọ sílẹ̀ sínú Ìwé Mọ́rmọ́nì.
Nínú àlá rẹ̀, Léhì rí pápá tó gbòòrò, nínú rẹ̀ ni igi alárà kan, tó dára kọjá ìjúwe. Bákannáà ó rí àkojọ́ púpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n nwà ọ̀nà lọ sí ìdí igi náà. Wọ́n fẹ́ tọ́ èso igi ológo náà wò. Wọ́n ní ìmọ̀lára wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé yíò fún wọn ní ìdùnnú nlá àti ìbágbé àláfíà.
Ọ̀nà tóóró wà tí ó darí lọ sí ibi igi náà, àti pé ní ìfẹgbẹ́kẹ̀gbẹ́ ni ọ̀pá irin tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró ní ipá ọ̀nà. Ṣùgbọ́n bákannáà òkùnkùn tó ṣú biribiri kan tì ó nbo ìran méjèèjì ipá ọ̀nà àti igi náà. Àti pé àní bóyá ewu púpọ̀ ni ìró nlá ẹ̀rín àti ìṣẹ̀sín tí ó nwá láti inú ilé nlá àti ilé aláyè nítòsí. Ní ìgbọ́nrìrì, àní ìtàbùkù fi òye yé àwọn ènìyàn kan tí wọn dé ìdí igi tí wọ́n sì ti tán èso alárà náà wò láti ní ìmọ̀lára ìtìjú wọ́n sì ṣáko lọ.6
Bóyá wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti ṣe iyèméjì pé igi náà dára bí wọ́n ṣe ti rò tẹ́lẹ̀. Boyá wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti bèèrè òdodo ìrírí ohun tí wọ́n ti rí.
Tàbi wọ́n rò pé bí wọ́n bá yípadà kúrò ní ìdí igi náà, ìgbé ayé yíò rọrùn. Tàbí wọn kò ní fi wọ́n ṣẹ̀sín tàbí rẹrin si mọ́.
Ati pé nítòótọ́, àwọn ènìyàn tí wọ́n ntàbùkù sí wọn bí àwọn ènìyàn tí inú wọn dùn tí wọ́n nní ìgbà ìgbádùn. Nítorínáà, bóyá tí wọ́n bá pa igi náà ti, wọn yíò kí wọn káàbọ̀ sínú agbo àwọn ènìyàn nlá àti ilé aláyè àti gbígba oríyìn fún ìdájọ́, òye, àti dídán.
Dúró ní Ipá Ọ̀nà náà!
Ẹ̀yin arábìnrin ọ̀wọ́n, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, tí ó bá ṣòro fún yín láti di ọ̀pá irin mú daindain kí ẹ sì rìn ní ìdúróṣinṣin síwájú ìgbàlà; tí ẹ̀rín àti ẹ̀sín àwọn ẹlòmíràn ẹnití ó dàbí o ní ìgbẹ́kẹ̀lé gidi nmú yin yẹsẹ̀; tí ẹ bá dàmú nípa àìdáhùn àwọn ìbèèrè tàbí ẹ̀kọ́ tí ko yée yín síbẹ̀síbẹ̀; tí ẹ ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ nítorí àwọn ìjákulẹ̀, mo rọ̀ yín láti rántí àlá Léhì.
Dúró ní Ipá Ọ̀nà náà!
Maṣe fi ọ̀pá irin náà—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ láéláé!
Àti pé nígbàtí ẹnìkan bá gbìyànjú láti mu u yín tijú fún ṣíṣe àbápín ìfẹ́ Ọlọ́run, pa wọ́n ti.
Maṣe gbàgbé láéláé pé, ẹ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run; ọrọ̀ ìbùkún wà ní ìsura; tí ẹ bá kọ́ láti ṣe ifẹ́ Rẹ̀, ẹ ó gbé pẹ̀lú Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan si!7
Àwọn ìlérí ìyìn àti ìtẹ́wọ́gbà nípa ayé kò ní ìgbẹ́kẹlé, kíí ṣe òtítọ́, àti pé kìí tẹ́nilọ́rùn. Àwọn ìlérí Ọlọ́run dájú, o jẹ́ òtítọ́, àti aláyọ̀---báyìí àti títíláé.
Mo pè yín láti gbèrò ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ látinú ìrò gíga kan. Kò sí ohun tí a fúnni nínú ilé nlá àti aláyè tí a lè fi wé èso ìhìnrere ti Jésù Krístì alààyè.
Nítòótọ́, “ojú kò tíì rí, tàbí eti gbọ́, tàbí wọnú ọkàn ọmọ ènìyàn, àwọn ohun èyí tí Ọlọ́run ti pesè sílẹ̀ fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ.”8
Mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ fùnra mi pé ipá ọ̀nà ipò ọmọẹ̀hìn nínú ìhìnrere Jésù Krístì ni ọ̀nà sí ayọ̀. Òun ni ọ̀nà sí ààbò àti àláfíà. Ohun ni ọ̀nà sí òtítọ́. Òun ni ọ̀nà sí òtítọ́.
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé nípa ẹ̀bùn àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ lè kọ́ èyí fúnra yín.
Ní ìgbà kannáà, tí ipá ọ̀nà bá ṣòro fún yín, mo ní ìrètí pé ẹ ó rí ààbò àti okun nínú ètò ìyanu Ijọ—Alakọbẹrẹ, àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Wọ́n dà bí àmì-ọ̀nà ní ipá ọ̀nà, níbití ẹ ti lè tún ìgbẹ́kẹ̀lé yín ṣe àti ìgbàgbọ́ fún ìrìnàjò tó wà níwájú. Wọn jẹ́ ilé ààbò, níbití ẹ ti le ní ìmọ̀lára wíwà pẹ̀lú àti gbígba ìgbìyànjú láti ọ̀dọ̀ àwọn arábìnrin àti àwọn ọmọẹ̀hìn ẹgbẹ́ yín.
Àwọn ohun tí ẹ kọ́ ní Alakọbẹrẹ múra yín sílẹ̀ fún àfikún òtítọ́ tí ẹ kọ́ bí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin. Ipá ọ̀nà ipò ọmọẹ̀hìn tí ẹ rìn ní yàrá ìkàwé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin darí sí ìjọsìn àti ipò arábìnrin ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Pẹ̀lú iṣísẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, a fún un yín ní àfikún àwọn ànfàní láti júwe ìfẹ́ yín fún àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ àwọn ìṣe àánú, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, àti iṣẹ́ ìsìn.
Yíyan Ipá ọ̀nà ipò ọmọẹ̀hìn yí yíò yọrí sí ìdùnnú àìlesọ àti ìmúṣẹ ìwà ẹ̀dá yìn.
Kò lè rọrùn. Yíò gba gbogbo ohun tí a lè ṣe—gbogbo òye yín, ọnà, ìgbàgbọ́, ìṣòdodo, okun, ìpinnu, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan ẹ̀yin ó wẹ̀hìn wò lóri ìtiraka yín, àti pé àà, bí ẹ ó ṣe dúpẹ́ pé ẹ dúró gbọingbọin, tí ẹ gbàgbọ́, tí ẹ kò sì yà kúrò ní ipá ọ̀nà.
Tẹ̀síwájú
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kan lè wà nípa ìgbé ayé tí ó kọjá agbára wa. Ṣùgbọ́n ní òpin, ẹ̀ ó ní okun láti yan méjèèjì ibùdó yín àti ọ̀pọ̀ ìrírí yín ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà. Kìí ṣe púpọ̀ nípa agbára yín, ṣùgbọ́n àwọn àṣàyàn tí ó nmú ìyàtọ̀ wá ninú ayé.9
Ẹ kò lè fi àyè gba ipò yín láti bà yín nínú jẹ́.
Ẹ kò lè fi àyè gba wọ́n láti mú yín bínú.
Ẹ lè yọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọbìnrin Ọlọ́run. Ẹ lè rí ayọ̀ àti ìdùnnú nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti nínú ìfẹ́ Jésù Krístì.
Inú yín lè dùn.
Mo rọ̀ yín láti jẹ́ kí ọkàn yín kún fún ìmoore fún ọ̀pọ̀ àìlóye inúrere Ọlọ́run. Ẹ̀yin olólùfẹ́ arábìnrin mi, ẹ lè ṣe èyí! Mo gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́-ọkàn mi pé ẹ ó mú kí àṣàyàn yín tẹ̀síwájú síbi igi ìyè. Mo gbàdúrà pé ẹ o yàn láti gbé ohùn yín sókè kí ẹ sì gbé ìgbé ayé ológo ni ìrẹ́pọ̀ ìró ohùn orin ìyìn, yíyọ ayọ̀ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àti nínú ìyanu tí Ìjọ Rẹ̀ àti ìhìnrere ti Jésù Krístì lè mú wá sí ayé.
Orin ọmọlẹ́hìn tòótọ́ lè dàbí òdì tàbí tí ó láruwo díẹ̀ sí àwọn kan. Láti ìbẹ̀rẹ̀ àsìkò ni èyí ti rí bẹ́ẹ̀.
Ṣùgbọ́n sí Bàbá wa Ọ̀run, àti sí àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìfẹ́ tí wọ́n sì nbu ọ̀wọ̀ fun Un, ó jẹ́ ojúlówó orin tó ládùn jùlọ—ọlá àti orin ìràpadà ìfẹ́ mímọ́ àti iṣẹ́ ìsìn sì Ọlọ́run àti ọmọlàkejì.10
Mo fi ìbùkún mi sílẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́bí Àpọ́stélì Oluwa kan pé ẹ̀yin ó rí okun àti ìgboyà láti fi tayọ̀tayọ̀ làkàkà bí ọmọbìnrin Ọlọ́run nígbàtí ẹ bá nfi ìdùnnú rin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní ipá ọ̀nà ológo ti ipo ọmọlẹ̀hìn. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín
© 2017 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/17. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/17. Àyípadà èdè Visiting Teaching Message, November 2017. Yoruba. 97929 779