2018
Gbàdúrà fún arábìnrin kọ̀ọ̀kan nípa Orúkọ
March 2018


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́ta 2017

Gbàdúrà fún arábìnrin kọ̀ọ̀kan nípa Orúkọ

Ìfẹ́ wa fún àti ìmísí wa nípa àwọn wọnnì tí à nbẹ̀wò kọ́ yíò pọ̀ si nígbàtí a bá fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà fún arábìnrin kọ̀ọ̀kan nípàtàkì pẹ̀lú orúkọ.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

Àwòrán
Èdidì Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́

Àwọn ìwé mímọ́ ṣe àbápín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú orúkọ. Ní àárín èyí tí ó ga jùlọ ni bàbá ti Álmà Kékeré. Ángẹ́lì kan sọ̀rọ̀ sí Álmà Kékeré, ó sọ fun pé bàbá rẹ̀ “ti gbàdúrà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ nípa rẹ …; nítorínáà, fún èrò yí ni mo fi wá láti mú agbára àṣẹ Ọlọ́run dá ọ lójú, pé kí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ̀ lè gbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn” (Mosiah 27:14).

Gbígbàdúrà fún ẹlòmíràn nṣí ọkàn wa sílẹ̀ láti gba àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ní ìfẹ́ láti fún wa. “Èrèdí àdúrà kìí ṣe láti yí ìfẹ́ Ọlọ́run padà, ṣùgbọ́n láti gba àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run nfẹ́ láti fún wa àti àwọn ẹlòmíràn tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n pé a gbọ́dọ̀ bèèrè fún ní èrò láti gbàá.”1

Arábìnrin kan sọ pé ní ìgbà ìṣòro kan nínú ayé òun, ìpè ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ kan tàbí àtẹ̀ránṣẹ́ jẹ́jẹ́ nwá léraléra láti ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́ ìbẹniwò rẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ burúkú pàtakì jùlọ.” Ó dàbíi pé wọ́n mọ ìgbàtí ó bá nílò gbígbé kan. Ó mọ̀ pé wọ́n ngbàdúrà fún òun, ní ìgba ìbẹ̀wò àti ní àyè ara wọn.

“Ẹ ronú nípa agbára àpapọ̀ tí gbogbo arábìnrin bá nní àdúrà àràárọ̀ àti alẹ́, síbẹ̀síbẹ̀ si, tí wọ́n gbàdúrà láìsimi bí Olúwa ṣe pàṣẹ.” Ni Julie B. Beck, Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ sọ.2 Gbígbàdúrà fún àwọn wọnnì tí à nbẹ̀wò nfún wa lókun gẹ́gẹ́bí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́bí àwọn obìnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn.

Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Àarẹ Kínní, sọ pé: “Gbàdúrà fún ọ̀nà láti mọ ọkàn wọn. … Ẹ máa ní láti mọ ohun tí Ọlọ́run yíò fẹ́ kí ẹ ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ àti láti ṣe gbogbo rẹ̀, ní sísúnmọ́ bí ẹ ti lè ṣe tó, ní níní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún wọn.”3

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Ìtọ́sọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Àánú.”

  2. Julie B. Beck, “Ohun tí àwọn arábìnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn nṣe dáradára jùlọ: Dúró Láìyẹsẹ̀ àti pẹ̀lú Agbára,” Liahona, Nov. 2007, 110.

  3. Henry B. Eyring, “Oyè-àlùfáà àti Àdúrà Araẹni,” Liahona, May 2015, 85.

Tẹ̀