2018
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn Ọmọ Rẹ̀
March 2018


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́ta 2018

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn Ọmọ Rẹ̀

Àwọn ìwé mímọ́ sọ fún wa pé ohun àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run ṣe lẹ́hìn tí ó dá ọkùnrin àti obìnrin ni sísọ̀rọ̀ sí wọn.1 Oùn ní ìwífúnni pàtàkì àti àwọn àṣẹ iyebíye láti fún wọn. Èrò Rẹ̀ kíí ṣe láti ni wọ́n lára tàbí yọ wọ́n lẹ́nu ṣùgbọ́n láti tọ́ wọn sọ́nà sí ìdùnnú àti ògò ayérayé.

Àti pé èyi ṣẹṣẹ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀. Láti ọjọ́ náà di òní yìí, Ọlọ́run ti tẹ̀síwájú láti máa bá àwọn ọmọ Rẹ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ti wà ní ipamọ́, ní ìṣura, àti ní ṣíṣe àṣàrò rẹ láti ọwọ́ àwọn ọmọẹ̀hìn ní gbogbo ìran. Wọ́n jẹ́ fífi ọ̀wọ̀ fún nípasẹ̀ àwọn tí wọn nwá láti mọ ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí sí òtítọ́ pé “Olúwa Ọlọ́run kò ní ṣe ohunkóhun, ṣùgbọ́n òun yíò fi àṣírí rẹ̀ hàn àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.”2

Èyí ti jẹ́ àwòṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ àkoko, àwòṣe náà si ntẹ̀síwájú ní òní. Kìí ṣe ìtàn Bíbélì dídára kan lásán; ó jẹ́ àgbékalẹ̀ ọ̀nà tí Ọlọ́run fi nbá àwọn ọmọ Rẹ̀ sọ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì. Ó gbe àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan dìde láti àárín wa, Ó pè wọ́n láti jẹ́ wòlíì, Ó si fún wọn ní àwọn ọ̀rọ̀ láti sọ, èyí tí a pè wá láti, “gbà, bíì pé láti ẹnu ara [Rẹ̀].”3 Ó ti kéde pé, “Bóyá nípa ohun ara mi tàbí nípa ohun àwọn ìránṣẹ́ mi, ó jẹ́ ọ̀kannáà.”4

Èyí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò, ológo, ìgbani-níyànjú, áti onírètí jùlọ —Ọlọ́run kò dákẹ́! Ó fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀. Òun kò fi wá sílẹ̀ láti ráre nínú òkùnkùn.

Ní ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dọọdún, ní Oṣù kẹ́rin àti Oṣù kẹwàá, a ní ànfàní láti gbọ́ ohun Olúwa nípasẹ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ nínú àwọn ìpàdé àpapọ́ gbogbogbò oníyanu .

Mo fún yín ní ẹ̀rí araẹni mi pé tipẹ́tipẹ́ ṣíwájú kí olùsọ̀rọ̀ kan nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tó rin ìrìn gígùn náà lọ sí ibi pẹpẹ, ọkùnrin tàbí obìnrin náà ti ṣe ọ̀pọ̀ akitiyan, àdúrà, àti àṣàrò ní ìdáhùn sí ìfunniniṣẹṣe láti sọ̀rọ̀. Gbogbo ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ dúró fún àìlónkà wákàtí ti ìmúrasílẹ̀ àti ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá láti ní òye ohun tí Olúwa nfẹ́ kí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀ gbọ́.

Kíni ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ tí àwa gẹ́gẹ́bí bí olùfetísílẹ̀ bá fi ìmúrasílẹ̀ àwọn olùsọ̀rọ̀ sí ìbámu pẹ̀lú ti ara wa? Báwo ni ìkàsí wa sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ṣe lè yàtọ̀ tí a bá rí ìpàdé àpapọ̀ gẹ́gẹ́bí ànfàní kan láti gba àwọn ọ̀rọ̀ láti ẹnu Olúwa Fúnrarẹ̀? Nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti orin ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, a lè rétí láti gba àwọn ìdáhùn araẹni sí èyíkéyìí ìbéèrè tàbí àwọn wàhálà tí a lè máa dojúkọ.

Tí ẹ bá fi ìgbà kan rónú rí bóyá Bàbá Ọ̀run yíò bá a yín sọ̀rọ̀ nítòótọ́, èmi yíò rán yín létí nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn síbẹ̀síbẹ̀ tí ó jinlẹ̀ tí àwọn alakọbẹrẹ nkọ lórin: “[ Ìwọ jẹ́] ọmọ Ọlọ́run, òun sì ti rán “[ọ] wá síbí.” Èrò Rẹ̀ ni láti ràn yín lọ́wọ́ “lati gbé pẹ̀lú rẹ̀ níjọ́ kan.”

Tí ẹ̀yin bá dé ọ̀dọ̀ Bàbá Ọ̀run gẹ́gẹ́bí ọmọ Rẹ̀, ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn tóótọ́, “darí mi, tọ́ mi sọ́nà, rìn lẹgbẹ me, rán mí lọ́wọ́ láti ri ọ̀nà náà. Kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo gbọ́dọ̀ ṣe.” Òun yíò sọ̀rọ̀ fún yín nípa Ẹ̀mí Mímọ́, ó wá kù síi yín lọ́wọ́ “láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” Mo ṣe ìlérí pé tí ẹ bá ṣeé, “àwọn ọrọ̀ ìbùkún wà ní ìṣura.”5

Ìtọ́sọ́nà Olúwa ni a nílò gidi loni bi ó ti wà títíláé nínú ìwé-ìtàn ayé. Bí a ṣe nmúrasílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, njẹ́ kí a lè fi tọkàntọkàn wá Ẹ̀mí òtítọ́ tó bẹ́ẹ̀ nígbàtí Olúwa bá sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, kí a lè ní òye, ní ìgbéga, kí a sì jùmọ̀ yọ̀ papọ̀.6

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé “nípa ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí ìlẹ̀kùn ọ̀run àpáàdì kò ní borí [wa]; bẹ́ẹ̀ni, Olúwa Ọlọ́run yíò sì tú agbára òkùnkùn kúrò níwájú [wa], yío sì mú àwọn ọ̀run mi tìtì fún rere [wa], àti ògo orúkọ rẹ̀.”7

Tẹ̀