2018
Mímúrasílẹ̀ láti Gbọ́ Ohun Ọlọ́run
March 2018


Ọ̀dọ́

Mímúrasílẹ̀ láti Gbọ́ Ohun Ọlọ́run

Ààrẹ Uchtdorf ṣe àlàyé bí ohun àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run ṣe lẹ́hìn dídá ọkùnrin àti obìnrin ṣe jẹ́ sísọ̀rọ̀ fún wọn tí Ó sì fún wọn ní ìwífúnni iyebíye àti àṣẹ. A ngba ìbùkún kannáà ní Oṣù Kẹrin àti Oṣù Kẹwá ní ìgbà ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, nígbàtí àwọn Olórí Ìjọ bá wa sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì fún wa ní ìmọ̀ràn tí Olúwa nfẹ́ kí a gbọ́.

Njẹ́ ẹ ti gbọ́ ohun Ọlọ́run rí nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò? Njẹ́ ẹ ti ní ìmọ̀lara bíi pé kókó ọ̀rọ̀ kan fún yín ní ìdáhùn tí ẹ ti nwákiri? Nínú ìwé ìròyìn kan, ẹ lè kọ ìrírí náà sílẹ̀ àti bi ó ti ṣe ìrànwọ́ fún yín. Lẹ́hìnnáà múrasílẹ̀ láti gbọ́ ohun Olúwa ní ìpàdé àpapọ̀ tí ó nbọ̀ nípa kíkọ́ àwọn ìbèèrè tí ẹ ní sílẹ̀ kí ẹ si ṣe àṣàrò wọn nínú àṣàrò ìwé mímọ́. Gbàdúrà sí Bàbá Ọrun, bèèrè láti gba àwọn ìbèerè àti òye nínú ìpàdè àpapọ̀ gbogbogbò. Bí ẹ ṣe nfi etí sílẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ dojúkọ àwọn ìṣílétí ẹnìkọ̀ọ̀kan Kíni ẹ ti kọ́? Báwo ni ẹ ṣe ní ìmọ̀lára ìmísí láti yípadà sí? Ẹ kọ àwọn ìṣílétí wọnnì sílẹ̀ nítorí èyí ni pé Ẹ̀mí nbáa yín sọ̀rọ̀.

Ẹ máa rántí nìgbàgbogbo pé Bàbá Ọ̀run ní ìfẹ́ yín Òun yíò sì tọ́ọ yín sí ọ́nà tòótọ́. Bí ẹ ṣe ntiraka láti gbọ́ ohun Rẹ̀ nipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, ẹ̀yin yío gba ìbùkún àti ìgbéga.

Tẹ̀