2021
Ó Gba Ọmọdékùnrin kan láti Gba Abúlé kan là
Oṣù Kẹrin 2021


“Ó Gba Ọmọdékùnrin kan láti Gba Abúlé kan là,” Fún Òkún àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù kẹrin 2021, 10–11.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù kẹrin 2021.

Ó gba Ọmọdékùnrin kan láti Gba Abúlé Kan Là

Tom Fanene jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá péré, ṣùgbọ́n nígbàtí àrùn apanirun kan kọlu abúlé rẹ ní Samoan, a pe é lati wa ṣe àwọn ohun nlá.

Erékùṣù Samoan pẹ̀lú ọmọdékùnrin tó nran ará abúlé tó nṣàìsàn lọ́wọ́.

Àpèjúwe láti ọwọ́ James Madsen; àwọn fọ́tò láti inú àwọn àwòrán Getty

Bí àkòrí àwọn ọ̀dọ́ odún yi ti sọ, ẹ “nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nla lélẹ̀” (Ẹkọ ati Àwọn Májẹ̀mú 64:33). Jákèjádò ìtàn ìjọ, àwọn ọ̀dọ́ nígbàgbogbo ti kó ipa pàtàkì ni àwọn àkokò tó nira ní gbìgbé ìjọba Ọlọ́run ga. Níhin ni àpẹrẹ kan.

Àjàkálẹ̀ àrùn Erékùṣù

Ó lé ní ọgọ́rùn ọdún sẹ́hin, ni Erékùṣù Samoan ti Òkun Pàsífíkì, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a pe ní Tom Fanene jẹ́ ìrànlọ́wọ́ pàtàkì ní ipò ìyè-àti-ikú fún àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Tom gbé ní abúlé kan tí a pe ní Sauniatu, tí a ti dá sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní agbègbè náà bíi ibìkan fún wọn lati máa parapọ̀ kí wọn ó sì jẹ́ ìletò kan. Gẹ́gẹ́bí ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọlọ́run ni àwọn àkokò àti àwọn ibi míràn, wọ́n ní ìrírí àwọn ìdánwo àti àwọn iṣẹ́ ìyanu bí wọ́n ti ṣiṣẹ́ láti parapọ̀ gbé ìjọba Ọlọ́run ga. Ìdánwo kan wa ni 1918, nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn ọ̀fìnkìn dé abúlé náà.

Ní kété tí àìsàn náà dé, ó jẹ́ ìparun, ó sì tànkálẹ̀ kíákíá. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo wọn nínú bíi irínwó àwọn ará abúlé náà ni kò lè dìde lórí ibùsùn nítorí rẹ̀. Díẹ̀ nínú wọn nìkan ni ara wọn yá to láti rìn kiri: ọkùnrin àgbàlagbà kan àti Tom ọmọ ọdún méjìlá.

Ìgbàgbọ́ àti Iṣẹ́ Àṣekára.

Ẹbí Tom ti lo ìgbàgbọ́ ní ojú àìsàn ṣaájú wọ́n sì ti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi àbájáde. Arákùnrin àbúrò Tom Ailama ṣàìsan ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹhìn. Bàbá wọn, Elisala, lá àlá nínú èyí tí a fun ní àwọn ìtọ́ni ní pàtó lórí ohun tí yíò ṣe láti tọ́jú Ailama: wá igi wili-wili, ṣí eèpo rẹ̀ díẹ̀, kí o si gún omi rẹ̀ síta. Elisala ṣe èyí ó si mú omi rẹ̀ wá fún Ailama, ẹni tí ó mu ún tí o si sàn láìpẹ́. Nítorínáà Tom ti ríi bí gbígbé ìgbésẹ̀ nínú igbagbọ ṣe lè ranni lọ́wọ́ borí àìsàn.

Lakoko àjàkálẹ̀ àrùn ọ̀fìnkìn 1918, Tom lo ìgbàgbọ́ bí o ti ṣiṣẹ́ kárakára láti tọ́jú àwọn ènìyàn abúlé náà. “Gbogbo òwúrọ̀ mo lọ láti ilé de ilé láti bọ́ àti láti nu ara àwọn ènìyàn náà àti lati wá ẹni tí ó ti kú jáde,” ni ó sọ.

Ó pọn àwọn ike omi láti orísun kan o sì gbe omi lọ sí gbogbo ilé. Ó gun àwọn igi àgbọn, ó mú àwọn àgbọn, ó pa wọ́n, ó sì ṣí wọn láti gba omi láti mu wá fún àwọn aláìsàn. Bákannáà ó pa gbogbo àwọn adìyẹ inú abúlé náà láti se ọbẹ̀ fún ẹbí kọ̀ọ̀kan.

Ṣíṣe Ìyàtọ̀ kan

Lákòkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí, bí ìdámẹ́rin gbogbo àwọn ènìyàn ní Samoa ni ó kú ikú ọ̀fìnkìn. Díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn abúlé Tom kú pẹ̀lú. Tom ṣe ìrànlọ́wọ́ lati gbẹ́ ilẹ̀ àti láti sin àwọn tí ó ju ogún lọ, nínú èyítí Baba tirẹ gan, Eliasala, wà.

Ṣùgbọ́n ọpẹ́ fún iṣẹ́ àṣekara àti àbojútó olùfẹ́ni Tom, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú abúlé rẹ yè. Ó ṣe ìyàtọ̀ nla sí àwọn ènìyàn wọnnì àti sí gbígbé ìjọba Olúwa ga ni Samoa. Ó “nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá kan lélẹ̀.”

Àti pé ní ọ̀nà tìrẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ náà.

A lè má ké pè ọ láti ṣe irú àwọn ohun tí Tom ṣe, ṣùgbọ́n, ní tòótọ́, ẹ nlo ìgbàgbọ́ ní oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà tí yio ṣe ìyàtọ̀ nla kan sí yín, sí àwọn míràn, àti si iṣẹ́ ti gbígbé ìjọba Ọlọ́run ga.

Ẹ nfi àpẹrẹ lélẹ̀ fún ẹbi yín, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn míràn nípa fífi ìwà rere, sùúrù, inúrere àti ìfẹ́ hàn. Ẹ nsin àwọn ẹlòmíràn. Ẹ nkópa nínú ìkẹ́kọ ìwé-mímọ́ àti àdúrà. Ẹ̀ npín àwọn òtítọ́ ti ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadà bọ̀sípò.

Lákòkò ọdún tí o kọjá yi, ọ̀pọ̀ nínú yín ti nṣe àwọn ohun wọ̀nyí nígbà tí ẹ nfarada àjàkálẹ̀ àrùn. Bóyá o ko tíì pọn omi àti àwọn àgbọn, àti kí o tọ́jú irínwó ènìyàn pada sí ìlera, ṣùgbọ́n o ti mú ìtùnú, ìrètí, ayọ̀, àti àlááfíà wá fún àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà míràn.

Ọjọ́ orí yín kò ṣe pàtàkì tó ìgbàgbọ́ àti ìmúratán yín láti ṣiṣẹ́ àti láti sin àwọn míràn. Àwọn àpẹrẹ láti ìgbà àtijọ́, bíi ti Tom Fanene, lè ràn yín lọ́wọ́ láti rí pé a nílò yín ní fífi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nla ti Ọlọ́run náà lélẹ̀.