“Jésù Krístì Gbàwálà kúrò nínú Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú,” Làìhónà, Oṣù Kẹrin 2021
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà Oṣù Kẹ́rin (Igbe) 2021
Jésù Krístì Gbàwálà kúrò nínú Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú
Nítorí ètùtù Rẹ, gbogbo wa ní àyè láti rí àlááfíà àti ayọ̀ ayérayé.
A n tọ́ka sí Jésù Krístì bi Olùgbàlà wa. Ìyẹn jẹ́ nítorí pé Ó san ìdíyelé fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ó sì borí agbára ikú. Ó gbàwálà là! Ìrúbọ Rẹ̀ fún wa, tí a pè ni Ètùtù, ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí o ṣẹlẹ̀ rí. Nítorí Rẹ, ikú kìí ṣe òpin. Nítorí Rẹ, a lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jì wá, di mímọ́ lẹ́ẹ̀kansi, kí a sì dàgbà dáradára si lójojúmọ́.
Jésù Krístì Ni Àkọ́bí
Kí a tó wá sí ayé, a gbé pẹ̀lú àwọn òbí wa ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí Àkọ́bí, Jésù Krístì rànwá lọ́wọ́ láti da ayé ẹlẹ́wa yi sílẹ̀. A yàn Án lati jẹ́ Olùgbàlà Ó sì gbà láti jẹ́ bíbí sí ilẹ̀ ayé kí O lè gbé àpẹrẹ pípé kalẹ̀, kọ́ ìhìnrere Rẹ, kí Ó sì parí Ètùtù fún wa.
Jésù Krístì San fún Ẹ̀ṣẹ̀ Wa
Nígbà tí Jésù mọ̀ pé Òun yio kú láìpẹ́, O lọ sí ọgbà kan tí a pè ni Gethsemane lati gbàdúrà. Ní àkokò àdúrà, ó bẹ̀rẹ̀ síí san ìdíyelé fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó mọ̀ọ́mọ̀ jìyà ki a ma bàa jìyà—tí a ba ronúpìwàdà. Bí a ṣe n yí kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a si ntẹ̀lé Olùgbàlà dípò rẹ̀, a le ri ìdáríjì àti ìwòsàn. Nítorí ìrìrì tí ó ni Gethsemane, Jésù lóye ohun gan tí ó dàbí láti jẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wa. Ó ní ìmọ̀lára gbogbo ìbànújẹ̀, àìsàn àti ìrora wa. Èyí ni apá ìkínní Ètùtù.
Jésù Krístì Borí Ikú
Lẹ́hìn àdúrà Rẹ ní Gethsemane, wọ́n fi Jésù hàn, wọ́n mú Un, wọ́n sì ṣe ìdájọ́ ikú fun nípasẹ̀ àgbélebu. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó jẹ́ alágbára gbogbo, Jésù gba ara Rẹ̀ láàyè láti ku lórí àgbélebu. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ fí tìfẹ́tìfẹ́ gbé ara Rẹ̀ sí ibojì. Wọn kò mọ̀ pé bíótilẹ̀jẹ́pé ara Rẹ ti kú, ẹ̀mí Rẹ ṣì wà láàyè ni ayé ẹ̀mí. Ọjọ́ mẹta lẹ́hìnnáà, Jésù wá si ààyè lẹ́ẹ̀kansi ó sì bẹ̀ wọ́n wò, Ò fi hàn pé Òún lè ṣẹ́gun ikú. Èyí ló parí Ètùtù. Nítorí Jésù jíìnde, ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa yìó yè lẹ́ẹ̀kan si lẹ́hìn tí a bá kú.
Ìtumọ̀ Kérésìmesì àti Ọdún-àjíìnde
Púpọ̀ jùlọ ní ayé n ṣe ayẹyẹ àwọn ìsinmi méjì tí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti rántí Ètùtù Jésù Krístì. Lakoko Kérésìmesì, a ránti pẹ̀lú ọpẹ́ pé Jésù fẹ́ láti gbà iṣẹ́ wíwá sáyé bíótilẹ̀jẹ́pé ìyẹn pẹ̀lú ìjìyà àti ikú fún wa. Ọdún-àjíìnde ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun Olùgbàlà lórí ikú àti ẹ̀ṣẹ̀, èyítí o fún wa ní ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la ayérayé ti ayọ̀.
Kínni Àwọn Ìwé Mímọ́ Sọ nipa Ètùtù Olùgbàlà?
Nítorí Jésù mọ̀ wá ní pípé, Ó lè “tì wá lẹ́hìn,” tàbí rànwá, lọ́wọ́ (wo Álmà 7:11–12).
Olùgbàlà lóye ìkorò àti ìbànújẹ́ wa (wo Isaiah 53:2–5).
Ọlọ́run rán Jésù láti gbàwálà nítorí Ọlọ́run fẹ́ràn ẹnikọ̀ọ̀kọn wa (wo Jòhánù 3:16–17).
Jésù gbàdúrà fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, pẹ̀lú wa, láti ní ààbò kúrò lọ́wọ́ ibi àti láti jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run (wo Jòhánù 17).
Olùgbàlà wa pè wá láti tẹle Òun kí á si padà sí iwájú Rẹ (wo Ẹkọ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:16–19, 23–24; 132:23).
© 2020 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọrọ Oṣoòṣù Lìàhónà, Oṣù kẹrin 2021. Yoruba. 17467 000