2021
Ìtàn Ọdún Àjínde
Oṣù Kẹrin 2021


“Ìtàn Ọdún Àjínde,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹrin 2021

Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹ́rin gbe) 2021

Ìtàn Ọdún Àjínde

Àwòrán
Jésù nfọ ẹsẹ̀ àwọn Àpóstélì

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Jésù nifẹ àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ. Ó fọ ẹsẹ̀ wọn. Lẹ́hìnnáà Ó fún wọn ní oúnjẹ Olúwa. Ó wí fún wọn kí wọ́n rántí Òun. Ó wí fún wọn kí wọ́n fẹ́ràn ara wọn.

Àwòrán
Jésù Ngbàdúrà ní Gẹ́thsémánì

Lẹ́hìnnaa, Jésù lọ sí ọgbà kan. Ó gbàdúrà fún gbogbo wa. Ó ní ìmọ̀lara ìrora àwọn àísàn wa. Ó ní ìmọ̀lara ìrora àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

Àwòrán
Ara Jésù ní títẹ́ sí ibojì

Àwọn ènìyàn tí wọ́n nbínú gbé Jésù lọ. Wọ́n pa Á lára. Ó kú lórí igi àgbélébu fún wa. Àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ gbé ara Rẹ̀ sí ibojì kan.

Àwòrán
Ángẹ́lì nkéde Àjíìnde Jésù fún àwọn obìnrin

Ọjọ́ mẹta lẹ́hìnnaa, àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ padà wa. Ibojì náà ṣófo! Àwọn angẹ́lì sọ fún wọn pé, “Ó ti jíìnde.” Jésù wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi! Nítorí Jésù, gbogbo wa yìó yè lẹ́ẹ̀kan si lẹ́hìn tí a bá kú.

Àwòrán
Àwọn ọmọdé ni ìjọ

Jésù nifẹ mi. Mo lè jẹ́ kí Ọdún Àjíìde jẹ́ pàtàkì nipa rírántí Rẹ̀.

Kíkun Ojú-ewé

Ọdún Àjínde jẹ́ nípa Jésù

Àwòrán
Jésù Krístì

Tẹ̀